Àwọn agbébọn yawọ abúlé, jí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ gbe ní Katsina

Oríṣun àwòrán, DIKKO RADDA/FACEBOOK
Nnkan ko fi ara rọ niluu Na-Alma to wa nijọba ibilẹ Malumfashi, ipinlẹ Katsina nigba ti wọn sọ pe awọn agbebọn yawọ ibẹ, ti wọn si ji awọn eeyan gbe.
Yatọ si pe wọn ji awọn eeyan gbe, a tun gbọ pe awọn ajinigbe ọhun dana sun ọpọlọpọ ile.
Iṣẹlẹ yii ti sọ ọpọ awọn to n gbe lagbegbe naa di alainile lori ati ẹru awọn ajinigbe.
Pupọ awọn to n gbe lawọn agbegbe ti awọn agbebọn ti ṣọṣẹ yii ni wọn ti ko ẹru wọn kuro niluu lati wa ibomiran ti wọn yoo fi ara pamọ si.
Ogunlọgọ ni awọn ti wọn jigbe, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ti pupọ wọn si jẹ obinrin, alaboyun ati awọn ọmọ kekeeke.
Ọkunrin kan ti ori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe yii sọ pe inu iporuru ọkan lawọn wa, nitori pe awọn bii mẹjọ ni wọn ti ko ẹru kuro niluu lati wa ibomiran.
Ọkunrin naa sọ pe ṣaaju asiko ikọlu yii ni awọn ti fi to awọn oṣiṣẹ eleto aabo leti wi pe awọn ri olobo kan gba wi pe awọn agbebọn fẹ wa ṣe ikọlu si wọn.
“A ti sọ fun awọn oṣiṣẹ eleto aabo ni nnkan bi agogo mẹjọ aabọ alẹ wi pe awọn agbebọn n bọ, ṣugbọn wọn ko yọju si wa.
“Lojiji ni awọn ajinigbe ọhun yawọ ilu, ti wọn si da ibọn bolẹ, ti wọn dana sun awọn ile wa. Gbogbo ohun to wa nibi ni wọn dana sun tan.
“Igba ti awọn agbebọn naa ṣọṣẹ tan, ti wọn si ji awọn eeyan gbe salọ ni awọn oṣiṣẹ eleto aabo naa too yọju lati wo ohun to ṣẹlẹ.”
Ọkunrin naa to kọ lati darukọ ara rẹ tẹsiwaju pe “Ọlọrun nikan lo mọ iye ẹmi to ti ba iṣẹlẹ yii lọ, nitori pe niṣe ni wọn n ti ojule de ojule lati dana sun ile nla-nla, ti wọn si tun n pa awọn to ni ile.
Siwaju sii lo ni wọn tun gbe Alaaji kan salọ lẹyin ti wọn ti ge ẹsẹ ati apa rẹ lọjọ diẹ sẹyin. Wọn tun ji awọn obinrin, to fi mọ awọn alaboyun gbe.”
Awọn ara agbegbe naa sọ pe awọn n koju ikọlu lasiko yii ju ti tẹlẹ, ti wọn si lo n pa wọn lẹkun ni gbogbo igba.
Kọmiṣanna fọrọ eto aabo nipinlẹ Katsina, Ọmọwe Nasiru Mu’azu nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe awọn to wa ṣe ikọlu naa wa gbẹsan ni.
O ni iku ọkunrin kan ti wọn fura si pe o wa lara awọn ikọ agbebọn ti wọn lọ kọlu ijọba ibilẹ Malumfashi lo ṣee ṣe ko fa, ti wọn fi pada wa ṣọṣẹ wọn.












