Sẹnetọ Rafiu Adebayọ jáde láyé lẹ́ni ọdún 57

Oríṣun àwòrán, Sẹnetọ Rafiu Adebayọ/Others
Ọkan lara awọn agba oloṣelu nipinlẹ Kwara, Sẹnetọ Rafiu Ibrahim Adebayọ ti jade laye.
Aarọ oni, Ọjọru la gbọ pe Sẹnetọ Adebayọ dagbere faye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta (57).
Ọkunrin naa ni wọn lo ku lẹyin aisan rampẹ to kọlu, ti wọn si lo ti gba itọju, ṣugbọn ti ẹlẹmin tun pada gba a.
Aarin ọdun 2015 si 2019 ni oloogbe naa fi ṣoju ẹkun Guusu ipinlẹ Kwara nile igbimọ aṣofin agba orileede yii labe asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
Taa ni Sẹnetọ Adebayọ?
Inu idile Adebayọ Ibrahim to wa niluu Ojoku, ijọba ibilẹ Ọyun, ipinlẹ Kwara ni wọn bi oloogbe yii si lọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun 1966.
Ọdun 1958 ni Sẹnetọ Adebayọ bẹrẹ ile-ẹkọ alakobẹrẹ ati girama niluu abinibi rẹ.
Ile ẹkọ giga gbogoniṣe tipinlẹ Kwara ni Sẹnetọ Adebayọ kọkọ lọ lọdun 1987, ko to tẹsiwaju lati kẹkọọ gboye nipa imọ ijinlẹ ninu eto inawo, iyẹn ni fasiti Ado Ekiti, lọdun 2000.
Siwaju sii ni Sẹnetọ Adebayọ tun kẹkọọ siwaju sii nile ẹkọ Okoowo ti a mọ si Business School nipinlẹ Eko.
Lara awọn oye to tun gba lẹnu ẹkọ rẹ ni PhD lọdun 2009 ati FCIB.
Ọdun 2008 ni oloogbe yii darapọ mọ oṣelu lorileede Naijiria, to si gbe apoti gẹgẹ bi aṣofin nipinlẹ Kwara lọdun 2009.
Sẹnetọ Adebayọ jawe olubori ninu eto idibo ọdun 2011, nibi to ti ṣoju ẹkun idibo Ọffa, Oyun ati Ifẹlodun nile igbimọ aṣofin kekere niluu Abuja.
Lẹyin eyi lo tun tẹsiwaju lati gbe apoti gẹgẹ bi aṣofin agba lọdun 2015, to si ṣoju ẹkun Guusu Kwara labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Akikanju ọkunrin to fi ara ṣiṣẹ ilu ni Adebayọ - Gomina AbdulRazaq
Ẹwẹ, nigba to n kẹdun iku oloogbe naa, Gomina AbduRahman AbdulRasaq ti ipinlẹ naa ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi akikanju to fi ọkan si ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ibanikẹdun ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita lo ti ni asiko ti ipinlẹ naa nilo awọn ọgbọn ati imọ rẹ lo jade laye.
Bẹẹ lo gbadura pe bi Ọlọrun ṣe n tẹ oloogbe si afẹfẹ rere naa ni ki Ọlọrun tu awọn mọlẹbi rẹ ninu.















