Mọ̀ nípa àwọn ọ̀gá àgbà tuntun àjọ DSS àti NIA tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò

Aworan Adeola Ajayi

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti yan Mohammed Mohammed gẹgẹ bi ọga agba ajọ NIA to n ri si ọrọ iwadii lori eto abo.

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun yan Adeola Ajayi gẹgẹ bi ọga-agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS.

Oludamọran aarẹ lori eto iroyin ati ilukoro, Ajuri Ngelale, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lonii ọjọ Aje.

Gẹgẹ bi o ti ṣalaye ninu atẹjade naa, Aarẹ Tinubu yan awọn mejeeji sipo lẹyin tawọn to di ipo naa mu tẹlẹ kọwe fipo silẹ.

Taa ni Mohammed Mohammed ti Tinubu yan sipo olori ajọ NIA?

Ajuri ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wi pe Ọgbẹni Mohammed to ti ṣoju Naijiria rii nilẹ okeere jẹ akọṣẹmọṣẹ to ti fakọyọ lati 1995 to ti darapọ mọ ajọ NIA.

‘’Ọgbẹni Mohammed ti ṣiṣẹ loriṣiiriiṣi ẹka ki o to de ipo ọgba agba eyi to fi di adari igbimọ to ṣoju orilẹede Naijiria ni Libya.

Mohammed to kẹkọọ gboye ni fasiti BUK niluu Kano lọdun 1990 ti ṣiṣẹ lorilẹede North Korea, Sudan, Pakistan ati nileeṣẹ aarẹ l’Abuja,’’ Ajuru lo ṣalaye bẹẹ ninu atẹajde to fi sita.

Taa ni Adeola Ajayi ti Tinubu yan sipo olori ajọ DSS?

Nigba ti o n sọ nipa olori ajọ DSS tuntun, Ajuri ni Ọgbẹni Ajayi ti ṣiṣẹ kaakiri nipinlẹ Bauchi, Enugu, Rivers, Kogi ati Bayelsa ki o to di igbakeji olori ajọ DSS ṣaaju iyansipo rẹ gẹgẹ bi ọga agba DSS.

Ajuri ni Aarẹ Tinubu fẹ kawọn mejeeji ṣiṣẹ takun takun lati wa ojutuu si iṣoro eto abo to n koju orilẹede Naijiria lọwọ yii.

O ni aarẹ tun fẹ ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu ọfiisi oludamọran aarẹ lori eto abo, Nuha Ribadu.

Oludamọran aarẹ lori eto iroyin ati ilukoro fikun ọrọ rẹ ninu atẹjade to fi sita pe Tinubu gboṣuba rabandẹ fawọn olori ajọ DSS ati NIA to lọ fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe lasiko wọn.