Wo ọ̀nà márùn ún tí àrùn mpox fi yàtọ̀ sí coronavirus

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Dorcas Wangira
- Role, BBC Africa health correspondent
- Reporting from, Nairobi
- Author, Carolyne Kiambo
- Role, BBC Africa health producer
- Reporting from, Nairobi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ọpọ eeyan lo n beere bo ya ajakalẹ arun covid tun ti bẹ silẹ, nigba ti ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO, kede nkan o fararọ lori arun mpox fun igba keji lọdun 2024 yii.
Dokita Hans Kluge to jẹ adari ajọ WHO ni Yuroopu ṣalaye pe mpox kii ṣe arun covid.
‘’A mọ bi a ti le koju arun mpox, papaa julo a mọ igbesẹ ti a le gbe lati dẹkun itankalẹ arun mpox nilẹ Yuroopu.
Arun mejeeji lo maa n ran nipasẹ kokoro, amọ, awọn apẹẹrẹ wọn yatọ sira, ati pe ọna ọtọtọ ni wọn fi maa n ran,’’ Dokita Kluge ṣalaye.
Ọjọgbọn Rodney Adam ni tiẹ sọ pe iyatọ to wa laarin arun mejeeji ju ifarajọ wọn lọ.
1. Mpox kii ṣe arun tuntun
Ọdun 1958 ni arun mpox ti wa lẹyin tawọn oniṣegun oyinbo kede pe arun naa bẹ silẹ laarin awọn ọbọ to wa ni igbekun lorilẹede Denmark.
Ọdun 1970 ni arun naa kọkọ mu eeyan lorilẹede DR Congo.
Lati igba naa ni ajakalẹ naa ti n bẹ silẹ lapa guusu ati arin gbungbun Afirika.
Ọdun 2022 ni igba akọkọ ti mpox di ajakalẹ arun kari gbogbo aye lẹyin to tan kalẹ de aadọrin orilẹede lagbaaye.
Amọ, kokoro kan ti orukọ rẹ n jẹ SARS-CoV2 lo fa ajakalẹ arun covid-19 to bẹrẹ ni Wuhan lorilẹede China eyi to si ran kaakiri gbogbo agbaye.
Irufẹ kokoro covid yii ko tii mu eeyan ri ṣaaju ọdun 2019.
2. Mpox kii tete ran bi covid-19
Bo tilẹ jẹ pe arun majeeji lo maa n ran nipa ifarakanra, amọm awọn onimọ iṣegun sọ pe covid-19 maa n tete ran ju mpox lọ tori kokoro arun naa maa n wa ninu afẹfẹ.
Nigba tawọn eeyan le ko covid-19 ninu afẹfẹ, ọna ti eeyan fi le ko mpox ni nipa fifi ara kan ẹni to ba ni arun yii tabi nipa ibalopọ.
Eeyan to le ko arun mpox lara aṣọ ẹni to ba mu tabi nipa ibalopọ pẹlu ẹni to ba larun ọhun.
O le ni miliọnu 760 eeyan to ko arun covid-19 kaakiri agbaye laarin ọdun 2019 si 2023.
Ajọ eleto ilera WHO sọ pe awọn to ti ti ko arun mpox ṣẹṣẹ di ẹgbẹrun lọna ọgọrun un ni bayii lati bi ọdun meji ti arun naa ti bẹ silẹ lagbaaye.
Lọdun 2024 yii, ajọ CDC to n ri si ati dẹkun ajakalẹ arun l'Afirika ti ṣe akọsilẹ eeyan 18,910 to ti lugbadi arun mpox nigba ti arun naa si ti gbẹmi eeyan 600.

Oríṣun àwòrán, Reuters
3. Abẹrẹ ti wa nilẹ fun arun mpox
Nigba ti covid-19 bẹrẹ, awọn oṣiṣẹ eleto ilera bẹrẹ si ni wa abẹrẹ fun itọju rẹ, amọ, abẹrẹ ti wa nilẹ fun itọju mpox.
Mpox dabi arun igbonna eyi ti o parun pẹlu abẹrẹ lọdun 1980.
Abẹrẹ to ran arun igbonna lọ soko iparun naa lo n ṣiṣẹ fun arun mpox papaa julọ irufẹ ajakalẹ arun mpox ti ọdun 2022.
Bavararian Nordic ti pin miliọnu mẹẹdogun abẹrẹ MVA-BN fun itọju mpox eyi to tun jẹ abẹrẹ igbonna kaakiri orilẹede mẹrindinlọgọrin kaakiri agbaye nigba ti arun naa bẹ silẹ lọdun 2022.
4. Kokoro mpox maa n yipada diẹ diẹ ju coronavirus lọ
Awọn kokoro arun maa yipada lati igba de igba, amọ, awọn kan maa n tete yipada ju awọn mii lọ.
Idi ni pe kokoro DNA lo maa n ṣokunfa arun mpox nigba ti RNA maa n fa covid-19.
Irufẹ meji ni kokoro to n fa mpox eyi ti orukọ wọn jẹ ''clade 1 ati clade 2.
Amọ, kokoro SARS-coV2 to n fa coronavirus ni irufẹ to le logun.
Irufẹ clade 1 lawọn oṣiṣẹ eleto ilera sọ pe o ṣokunfa ajakalẹ arun mpox to wa nita bayii.
Ọjọgbọn Trudie Lang to jẹ onimọ nipa iwadii eto ilera ni fasiti Oxford sọ pe nipasẹ ibalopọ ni irufẹ clade 1 mpox to n ja lọwọ fi ran julọ.
Ọjọgbọn Lang ni awọn eeyan si tun n ko arun naa nipa ifarakinra bii iya si ọmọ ninu ile.

Oríṣun àwòrán, AFP
5. O ṣee ṣe ki ofin konle n gbele wa tabi kawọn ijọba orilẹede gbe ibode tipa lori mpox
Ọpọ eeyan lo n bẹru wi pe bi mpox ṣe ran le jẹ ki ofin konle o gbele wa bi ti asiko covid-19.
Bo tilẹ jẹ pe arun mpox ti ran de orilẹede Afirika mẹrindinlogun, ajọ CDC to n gbogun ti ajakalẹ arun l'Afirika ti sọ pe oun ko ni gba awọn alaṣẹ orilẹede Afirika ni imọran pe ki wọn gbe ibode wọn tipa lori arun mpox.
Ọgagba ajọ CDC, Dokita Jean Kaseya, ṣalaye pe ''CDC ko ni gba awọn ijọba orilẹede Afirika ni imọran pe ki wọn ṣe ofin ti yoo ṣakoba fun lilọ bibọ awọn eeyan, pẹlu ibi ti arun naa de duro bayii.
Lilọ bibọ awọn eeyan yoo tẹsiwaju nigba ti a o tẹsiwaju lati koju arun mpox ni Afirika.''

Oríṣun àwòrán, EPA
Dokita Mike Ryan to jẹ ọgagba ajọ WHO sọ pe ''kokoro mpox ko nira lati tọju ti a ba le ṣe ohun to yẹ ki a ṣe lakoko gẹgẹ bi a ti ṣe nigba ajakalẹ arun covid.''
Awọn to ba lugbadi mpox maa n ri iwosan gba laarin ọsẹ meji si mẹrin.
Amọ, awọn mii ninu wọn maa n ni arun mii to lagbara, iru awọn eeyan bayii lo maa n pẹ nile iwosan.
Ọna ti eeyan le gba lati ma ko arun mpox ni nipasẹ tita kete si eeyan tabi ẹranko to ba ni arun ọhun.
Bakan naa, fifọ ọwọ, lilo sanitaisa lẹyin ti eeyan ba fọwọ egbo ṣe pataki.


















