Russia tún ṣe ìkọlù sí Ukraine, èèyàn márùn-ún dèrò ọ̀run

Aworna agbegbe iṣẹlẹ kan ree

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ko tii daju pe ogun to wa laarin orileede Ukraine ati Russia yoo dopin laipẹ, pẹlu bi awọn mejeeji ṣe n leri ogun sira wọn, ti wọn si n ṣe ikọlu ni gbogbo igba.

Ohun ti a gbọ ni pe laarọ kutu ọjọ Aje ni ikọlu eroja ogun bii drone ati awọn ado oloro ti a mọ si missile ṣọṣẹ mọjumọ, to si gba ẹmi eeyan marun-un.

Eeyan mẹta la gbọ pe wọn ku loju ẹsẹ, ti awọn meji yooku naa si dakẹ lẹyin bii ọpọ wakati.

Orilẹ-ede Russia ni iroyin fi to wa leti pe o ju ado oloro si aarin gbungbun ilẹ Ukraine lojiji, to si ko ibẹrubojo ba awọn araalu.

Oriṣiriṣi ilu to wa lawọn ẹkun mẹẹdogun lorileede Ukraine ni ibugbamu ti waye, gẹgẹ bi Olootu ijọba Ukraine ṣe ṣalaye.

Awọn alakoso ilu naa ti kọkọ sọ pe eeyan mẹta lo dero ọrun lori ikọlu ọhun, ko to di pe wọn tun pada fidi rẹ mulẹ pe wọn ti di marun-un.

Gbogbo agbegbe orileede Ukraine ni wọn ti wa labẹ ikọlu bayii, ti wọn si ti waninu ifoya lati mọ ibi ti ogun tun ti fẹẹ gba yọ.

Awọn alakoso ilẹ Ukraine ti fẹsun kan awọn Russia pe ẹrọ amunawa ati omi wọn ni wọn dojukọ lati ba jẹ.

Iṣẹlẹ ikọlu yii lo mu ki awọn alaṣẹ orileede Poland to mule ti Ukraine sọ pe awọn naa ti tan gbogbo awọn ẹrọ igbalode to le dena ado oloro ọhun silẹ, pẹlu bi wọn ṣe sunmọ itosi wọn.

Ileeṣẹ ologun oju ofurufu ilẹ naa jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn ado oloro Russia to n fo kaakiri Ukraine ko tii dopin.

Ninu ọrọ tuntun to n lọ lori ikanni Telegram, wọn ni ọpọlọpọ 'drone' ti wọn fi n ṣe ikọlu yii lo n morile olu-ilu wọn tii ṣe Kyiv.

Awọn ẹṣọ ologun oju ofurufu naa jẹ ko di mimọ pe awọn agbegbe ti wọn doju awọn ‘drones’ naa kọ ni Vinnytsia, Poltava ati Mykolaiv lorileede Ukraine.

Ukraine ti n jẹ gaba lawọn ẹkun Kursk ni Russia

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Laarọ yii, awọn ariwo ado oloro ti ‘missile’ ati ‘drone’ yii lo wa lẹyin bii ọsẹ mẹta ikọlu ti Ukraine ṣe si ilẹ Russia.

Lọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ ni Ukraine ṣe ikọlu nla si aarin gbungbun Kursk, to si ti n jẹ gaba lori ilẹ Russia to le ni ẹgbẹrun kan kilomita (1000sq km), iyẹn maili to din diẹ nirnwo (386 sq miles).

Agbelewọn awọn ikọ ogun to to ẹgbẹrun mẹwaa ni wọn ṣọṣẹ kaakiri ẹnubode ti ko fi bẹẹ si ohun idaabo bo fun, eyi ti wọn fi gba ilẹ rẹpẹtẹ laarin ọjọ perete ju eyi ti Russia ti bori ni Ukraine lọ lọdun yii.

Ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Russia ni wọn ti ko kuro, pẹlu bi ija ọhun ṣe peleke sii lai dawọ duro.

Aarẹ ilẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ti sọ pe erongba ikọlu Kursk ni lati mu awọn ikọ ogun Russia nigbekun – eyi ti yoo jẹ ki wọn pe fun paṣipaarọ ẹlẹwọn ti awọn ọmọ Ukraine marundinlọgọfa (115) fun iye awọn Russia lọjọ Abamẹta.

Bakan naa lo tun sọ pe idena ado oloro ti Russia n ju si ẹnubode ẹkun Sumy nilẹ Ukraine, ati pẹlu awọn afojusun miran ti oun ko ni le sọ sita.

Ẹkun mẹẹdogun ati awọn ohun amuṣọrọ ina mọnamọna ni wọn dojukọ, Olootu ijọ Ukraine sọ bẹẹ

Laipẹ yii ni Olootu ilẹ Ukraine, Denys Shmyhal ṣalaye pe ẹkun mẹẹdogun lorileede naa ni Russia ṣe ikọlu si, nipa lilo awọn eroja ogun bii ‘drone’, ‘missile’ ati Kinzhal hypersonic missiles.

Ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara ti Telegram, o fi kun ọrọ rẹ pe ohun ti wọn n dojukọ gangan ni eto idagbasoke ti ina mọnamọna wọn, nigba to n sọrọ nipa iye ẹkun ti wọn ṣe ikọlu si.

Shmyhal sọ pe o ti wa pọn dandan fawọn ileeṣẹ mọnamọna ilẹ Ukraine lati wa ọna abayọ pajawiri ti wọn yoo lo lati fi dẹna ikọlu si ohun amuṣagbara ina (gird) wọn.

Olootu yii kadi ọrọ rẹ nilẹ wi pe awọn nilo aṣẹ lati lo eroja ogun ti yoo lo ọjọ pipẹ lori ilẹ Russia, pẹlu afikun pe Ukraine nilo lati ṣe ikọlu si awọn agbegbe ti ado oloro ti n wa.

Russia ni ko sohun to n jẹ didawọ ogun duro

Awọn alaṣẹ ijọba Russia, ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo idunadura ati ajọsọ ti wọn n gbero rẹ tẹlẹ lati dawọ ogun naa duro ko nii waye mọ, nitori pe ija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

Agbenusọ Kremlin, Dmitry Peskov sọ fawọn akọroyin pe “akọle idunadura pẹlu Ukraine ti sọ agbara rẹ nu, ko si wulọ mọ.”

O tun sọ pe igbesẹ Russia jẹ idahun si awọn ikọlu ti Ukraine ṣe si ẹkun Kursk wọn.