Ọba Ghandi Afolabi yan Ìmáàmù Àgbà tuntun fún Ààfin Soun Ogbomoso

Aworan Imaamu aafin Soun

Oríṣun àwòrán, Soun palace

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumogege 111, Soun ilẹ Ogbomoso ti yan Habib Ahmed Adekunle Ayilara gẹgẹ bi Imaamu tuntun fun aafin Soun Ogbomoso.

Ọba Olaoye sọrọ yii ninu atẹjade kan ti o fi sita ni ọjọ Ẹti.

Sheikh Habib Ayilara yii ni ẹbi Ayilara fọwọ si tẹlẹ wi pe ki o jẹ Imaamu Agba ilu Ogbomoso.

Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi naa ṣalaye pe aafin nilo Imaamu ti ko ni maa dari irun laafin nikan.

Ọpọ musulumi lo wa ni aafin Soun nibi ti wọn ti we lawani fun Imaamu Ayilara ọhun to fi mọ Parakoyi Ogbomoso, Alhaji Sirajudeen Aleem, Sẹnẹtọ Fatai Buhari ti Alhaji Yekinni Woleola ṣoju rẹ atawọn olori ẹsin mii l’Ogbomoso.

Parakoyi ilu Ogbomoso ko ṣai fidi rẹ pe aafin Soun ni Imaamu yii wa fun, o ni Imaamu Agba ilu Ogbomoso, Sheikh Teliat Yunus Olusina Ayilara ṣi wa ni ipo rẹ.

O ni ẹjọ to wa lori ipo rẹ si wa nile ẹjọ lọwọ yii.

Ọba Ghandi ati Imaamu tuntun fun aafin Soun

Oríṣun àwòrán, Soun palace

Aworan Ọba Ghandi ati Imaamu tuntun

Oríṣun àwòrán, Soun palace

Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi naa ṣalaye pe aafin nilo Imaamu ti ko ni maa dari irun laafin nikan.

Ọba Ghandi ni aafin Soun nilo Imaamu ti yoo maa ṣoju oun ninu gbogbo eto tawọn musulumi ba n ṣe yala niluu Ogbomoso tabi nibi miran.

‘’Mo gbagbọ ibagbepọ oniruusu ẹsin lo le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilu Ogbomoso.

Mi o si ni kaarẹ nipa gbigbaruku ti iṣọkan ilu Ogbomoso fun anfani gbogbo araalu,'' Ọba Olaoye lo sọ bẹẹ.