Ìjọba Taliban fòfin de kí obìnrin máa sọ̀rọ̀ tàbí ṣí ojú rẹ̀ níta gbangba lórílẹ́èdè Afghanistan

Aworan obinrin to fi nnkan bo ori ati oju rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Ali Hussaini
    • Role, BBC News Persian
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn Taliban ni Afganistanti gbe ofin tuntun jade ni ọsẹ to kọja eyi ti yoo tako awọn obinrin lati le sọrọ ni ita tabi si oju wọn ni ita gbangba.

Ajọ agbaye (UN) ti kọyin si fun ofin tuntun yii, ti wọn sekilọ pe o lewu fun ọjọ ọla orilẹede Afganistan

Ofin naa ti jẹ ifọwọsi nipasẹ Alakoso giga julọ ti Taliban, Haibatullah Akhundzada.

Ileeṣẹ ijọba to n risi igbọran ni ofin yii kọyọ ẹnikẹni silẹ rara.

Eto ofin tuntun yii jẹ ki “Mohtasabeen” (ọlọpaa Taliban) le da si igbesi aye awọn araalu, bẹrẹ lati ibi nnkan ti wọn n wọ sọrun. bi wọn se n jade sita, nnkan ti wọn n jẹ ati nnkan ti wọn n mu.

Labẹ ofin titun, awọn ohun obinrin ko ni ni anfani si ọpọ nnkan bi. “Nigba kugba ti obinrin agbalagba ba fi ile rẹ silẹ, o jẹ dandan lati fi ohun, oju ati ara rẹ pamọ.”

Awọn agbofinro ti n mu ofin yii duro ni ibamu pẹlu Ofin Sharia ati pe o ti ọpọ eeyan ti dero atimọlẹ nitori pe wọn ko tẹle ofin yii.

Awọn ofin yii ni Taliban ni o wa ni ibamu pẹlu ofin Sharia.

Ki ofin sọ nipa obinrin?

Aworan

Ofin naa ṣalaye ni kunkun bi obinrin ṣe gbọdọ bo ara wọn patapata, pẹlu oju wọn, “lati ma le fa ọkunrin mọra”.

O sọ pe:

  • Obinrin gbọdọ bo ara rẹ patapata
  • Obinrin gbọdọ bo oju rẹ
  • Ohun obinrin ni ṣapejuwe gẹgẹ bii “awrah”, ti wọn ko gbọdọ gbọ nita gbangba.
  • Ọrọ lalubawa yii ni o tumọ si apa ara obinrin tabi ọkunrin ti wọn ko gbọdọ ṣafihan rẹ ni ita gbangba.
  • Wọn ko gbọdọ gbọ pe ki obinrin ma kọrin, tabi ka iwe soke , paapa lati inu ile wọn.
  • Aṣọ obinrin ni ko gbọdọ fun wọn ju, tirin ju tabi ko kere.
  • Obinrin gbọdọ bo ara wọn ati oju wọn niwaju awọn ọkunrin ti ki se mọlẹbi wọn.
  • Bakan naa ni wọn fi ofin de ọkunrin lati ma wo ara obinrin ati oju wọn, ti ofin yii naa si dena agbalagba obinrin ko ma wo ọkunrin.

Ofin tuntun fun ọkunrin

Aworan

Ofin tuntun yii na gba awọn ofin kalẹ fun awọn ọkunrin.

Ti ọkunrin ba wa ni ita, o gbọdọ bo ara rẹ titi de orukun.

Ọkunrin ko gbọdọ fi irun rẹ se oge ni ilana to tako ofin.

Awọn Taliban ti fi ofin de awọn gẹrigẹri ni ọpọlọpọ agbegbe .

N jẹ ṣe ofin yii ti bẹrẹ?

Ijọba Taliban ti paṣẹ pe ki ofin, ti wọn ko si ni yi ohun wọn pada sugbọn awọn ofin ko ti bẹrẹ lati ma fidi mulẹ ni awọn agbegbe kan mi olu ilu Kabul

Ọkan awọn to jabọ fun BBC lati ẹka ileeṣẹ ijọba pe ijọba ti n ṣiṣẹ lati ri pe ofin naa fẹsẹ mulẹ.

Gẹgẹbi orisun naa, ni kete ti ilana yii ba ti pari, bi ofin yoo se ma ṣiṣẹ yoo han si ọpọ eeyan.

Ẹwẹ, pupọ ninu awọn ofin yii ni wọn ti fẹsẹ mulẹ ni apa ibi kan lorilẹede naa.

Ileeṣẹ ijọba sọ pe eeyan ẹgbẹrun mẹtala lo ko sọwọ awọn agbofinro nitori wọn kọ lati téle ofin Sharia.