Agbẹjọ́rò di èrò ilé ẹjọ́ l'Akure fún ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìwé ìpín ogún olóògbé

ere ile ẹjọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Amofin jan, Olusegun Agunloye, ti n woju wina ofin nile ẹjọ Majisireti kan niluu Akure, Ipinlẹ Ondo, fun ẹsun pe o yi iwe.

Wọn fi ẹsun kan agbẹjọro naa pe o fi ayederu iwe ipin ogun, ti wọn n pe ni ‘Will’ ni ede Gẹẹsi, eyi to jẹ ti oloogbe Benjamin Ejelonu, ranṣẹ si ile ẹjọ niluu Akure.

Ọlọpaa to gbe Agunloye lọ siwaju ile ẹjọ, Nelson Akintimehin, sọ fun ile ẹjọ pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta ọhun ṣẹ ẹṣẹ naa ni ọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, dun 2023, ni ẹka ile ẹjọ Giga niluu Akure, to n mojuto awọn awuyewuye to ba jẹyọ lori ọrọ iwe ipinogun.

Ọlọpaa ṣalaye pe agbẹjọro naa pẹlu ifọwọsowọpọ pẹlu aburo oloogbe, Arabinrin Aminat Bakare, ti oun naa n jẹjọ lọwọ nile ẹjọ kan naa, lati ṣe ayederu iwe ogun ti oloogbe kọ silẹ ṣaaju iku rẹ, ti wọn si gbe e lọ sile ẹjọ gẹgẹ bi ojulowo.

Wọn ni igbesẹ wọn naa jẹ ọna lati lu ẹnikan to n jẹ Oluwamodupe Ejelonu, ni jibiti.

Iwa ti awọn mejeeji yii hu ni ọlọpaa sọ pe o tako ofin iwa ọdaran ọdun 2006 ni ipinlẹ Ondo.

Amọ, olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.

Nigba to n sọrọ, agbẹjọro fun olujẹjọ, Kehinde Osadugbe, rọ ile ẹjọ lati gba beeli onibaara rẹ, paapaa fun bo ṣe jẹ pe agbẹjọro ni oun naa.

Ati pe lẹnu iṣẹ rẹ gẹgẹ bi agbẹjọro lo ti ṣẹ ẹsẹ naa.

Ṣugbọn ọlọpaa tako o pe olujẹjọ naa le salọ ti wọn ba gba beeli rẹ, nitori pe o ti fi igba kan sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ nitori wọn fi silẹ gẹgẹ bi agbẹjọro.

Adajọ to gbọ ẹjọ naa, Kolawole Aro, pada gba beeli olujẹjọ, pẹlu miliọnu meji Naira, ati oniduro meji ti yoo san iru owo bẹẹ.

O wa a sun igbẹjọ si oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024.