‘Mo mọ̀ pé ọkọ mi yóò padà wálé ní ọjọ́ kan'

Oríṣun àwòrán, Abubakar Idris (Dadiyata)
Ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ni ayajọ ọjọ awọn to deedee poora pẹlu ipa – awọn ti wọn jigbe, paapaa awọn to jẹ oṣiṣẹ ijọba, ti wọn ko si ri wọn tabi gburo wọn mọ.
Iru iṣẹlẹ yii lo maa n saba wọpọ lawọn agbegbe ti ipenija ba ti de ba eto aabo, to si tun le jẹ anfaani fun awọn oloṣelu lati pa awọn alatako lẹnu mọ.
“O ṣi n jẹ ibanujẹ fun mi bi mo ba ranti iṣẹlẹ bi wọn ṣe gbe ọkọ mi lọ. Ọmọ mi ṣi maa n beere lọwọ mi pe igba wo ni baba oun maa pada de sile, mo si maa n sọ fun un pe ko ṣi ni suuru nitori pe niṣe lo rin irin ajo, ko si ni pẹ ẹ de,” Khadija Ahmed lo sọ eyi.
Obinrin naa bu sẹkun nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe fi ipa gbe ọkọ rẹ, Abubakar Idris, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Dadiyata lọ lọdun marun-un sẹyin.
Olukọ ile-ẹkọ fasiti Dutsinma to wani ẹkun Ariwa Naijiria ni Dadiyata, to si jẹ ọkan gboogi lara awọn to n bu ẹnu atẹ lu awọn gomina ati aarẹ Naijiria nigba naa lori ayelujara.
Khadija sọ pe ọkọ oun ti ọjọ ori rẹ ti le lọgbọn ọdun daadaa ṣẹṣẹ de lati ilu kan to wa nitosi ni lọjọ naa, ko to di pe awọn agbebọn yii wọle lalẹ patapata, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun 2019, ti wọn si gbe e lọ.
“Emi pẹlu ọmọ mi la jọ n duro de e lati de pada sile. Nigba to si de lalẹ ọjọ naa, mo yọju loju ferese, mo si ṣakiyesi wi pe o ṣi jokoo sinu mọtọ rẹ to n ba ẹnikan sọrọ lori foonu.
“Lojiji ni awọn ọkunrin kan de, ti wọn si bẹrẹ sii ba a sọrọ. Aya mi bẹrẹ sii ja, mo wa sare lọ pe awọn alabagbe wa. Nigba ti a maa fi pada debẹ ka si pe awọn ọlọpaa, wọn ti poora pẹlu ọkọ mi.”

Oríṣun àwòrán, Abubakar Idris (Dadiyata)
Ọdun marun-un lẹyin rẹ, ko tii si aridaju kan nipa Dadiyata tabi mọto rẹ, ati pe ko sẹni to pe mọlẹbi lori aago lati beere fun owo. Wọn ko mọ boya o ti ku, tabi pe o ṣi wa laaye.
Khadija gbiyanju lati tu ọmọ rẹ agba ninu, ẹni to ti pe ọdun mẹwaa bayii, wi pe ko ma ṣe gbọ ohun ti awọn eeyan n sọ pe baba rẹ ko nii pada de, nitori oun nigbagbọ pe baba rẹ ṣi wa laye.
Iwa ipa
Alakoso ajọ ajafẹtọ agbaye (Amnesty International) lorileede Naijiria, Isa Sanusi sọ pe pipoora eeyan maa n ni ohun kan lati ṣe – lati pa wọn lẹnu mọ, ati lati fi ibẹru sọkan awọn eeyan.
“Fifi ipa gbe awọn eeyan lọ ni wọn saba maa n lo lati fi da ẹru silẹ laarin ilu.
“Imọlara aisi eto aabo to maa n da silẹ kii si lọdọ awọn mọlẹbi awọn to poora nikan, bi ko ṣe fun agbegbe ati ilu ti iru iṣẹlẹ bẹẹ ba ti waye.”
O ni irufẹ awọn iṣẹlẹ bayii maa n wọpọ lawọn ibi ti rukerudo ba ti wa. Ati pe o jẹ awọn ohun gboogi lawọn orileede bii Syria, Sri Lanka, Sudan, Pakistan ati Libya, to fi mọ Naijiria.
Ajọ ti wọn pe ni International Committee of the Red Cross kii tọju akọsilẹ awọn ti wọn fi ipa gbe lọ, ṣugbọn wọn maa n sọ iye awọn eeyan to ti “dawati”, eyi to fi mọ awọn to ti poora.
Wọn ni awọn to ti le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan eeyan lo ti dawati lorileede Mexico ati Colombia, ati paapaa ẹgbẹẹgbẹrun ni Iraq.

Oríṣun àwòrán, EPA
Isa Sanusi ni, Amnesty ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Naijiria lori bi wọn ṣe n kuna lati ṣakọsilẹ awọn ti wọn n fipa gbe tabi poora, ati lori bi wọn ko ṣe maa n ṣe iwadii, koda to ba jẹ awọn iṣẹlẹ to gbajumọ bii ti Dadiyata.
Iṣẹ awọn to n ṣe akọsilẹ ti wa a di ti awọn ajọ ti kii ṣe tijọba, ajọ Jire Dole Network of Victims, to ti ṣe akọsilẹ ẹgbẹrun marundinlọgbọn laarin ọdun mọkanla le diẹ sẹyin.
Oludasilẹ ati alakoso ajọ naa, Hamsatu Allamin sọ pe pupọ awọn ti wọn n jigbe yii lo jẹ pe ọwọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo tabi awọn alẹnulọrọ laarin ilu lo ti wa.
Ileeṣẹ ologun ko le sọ iye awọn to ti mu sahamọ, ṣawari, tabi iye awọn to ti ku sahamọ wọn.
Gẹgẹ bi ajọ Amnesty International ṣe sọ, pupọ awọn to ti poora lorileede Naijiria lo waye lawọn agbegbe ti rukerudo ti waye ni ẹkun ariwa ila oorun ati guusu ila oòrùn.
Awọn ẹgbẹ aṣekọlu ti musulumi, Boko Haram ti ji awọn ọdọbinrin ati ọmọdebinrin ti ko din ni ẹgbẹrun meji gbe, nigba ti awọn ileeṣẹ eleto aabo ti fofin mu awọn ọkunrin ati ọmọdekunrin to ti le ni ẹgbẹrun lọna ogun.
Iwadii Amnesty sọ pe awọn ologun maa n san owo fawọn ọtẹlẹmuyẹ wọn lati ṣawari awọn to n ba awọn Boko Haram kẹdun, ki wọn si gbe wọn pamọ si abẹ aabo ologun.
Amnesty sọ pe akọsilẹ fihan pe ẹgbẹrun mẹwaa ni awọn to ti ku sahamọ laarin ọdun marun-un sẹyin.
Ninu oṣu kọkanla, Amnesty pe ẹjọ kan sile-ẹjọ Economic Community of West African States (ECOWAS), nibi ti wọn ti n fẹsun kan Naijiria wi pe wọn ti tapa ẹtọ agbaye wọn nipa gbigba awọn ologun laaye lati fipa jẹ ki ẹgbẹrun awọn eeyan poora lẹkun ariwa-ila-oorun, ati kikuna lati ṣewadii wọn lọna to tọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Idunkooko
Awọn mọlẹbi Dadiyata ko mọ awọn to gbe e lọ, ṣugbọn ti wọn sọ pe gbogbo igba lo maa n gba ipe idunkooko lati ọdọ awọn alẹnulọrọ nidi oṣelu.
“Igba kan wa to jẹ pe o nilo lati farapamọ fun ọjọ mẹta gbako nile ẹgbọn rẹ, nitori to n gba oriṣiriṣi ipe idunkooko lati ọdọ awọan oloṣelu kan, ti wọn si n jẹ ko di mimọ pe wọn maa jii gbe,” ẹgbọn Dadiyata, Usman Idris Usman lo sọ bẹẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn olori ọlọpaa ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ko fesi si awọn lẹta ti mọlẹbi ti kọ fun iranlọwọ, ati pe awọn ijọba naa ti “mọ-ọn-mọ kọ eti ikun si wa.”
Ẹbẹ si awọn gomina naa tun ti bọ sẹyin eti awọn gomina, o sọ bẹẹ.
“A kan fẹ ki wọn sọ fun wa pe o ti ku tabi pe o ṣi wa laye."

Oríṣun àwòrán, Abubakar Idris (Dadiyata)
Awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ti takoo wi pe awọn n fipa gbe awọn eeyan lati poora, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn oṣiṣẹ wọn n ṣiṣẹ wọn lọna to tọ labẹ ofin.
Agbẹnusọ DS, Peter Afunanya, naa kọ lati sọrọ nipa iṣẹlẹ Dadiyata.
Iyawo Dadiyata, Khadija, sọ pe oun ṣi ni ireti fun iroyin ayọ, pẹlu bi ọdun marun-un sẹ ti kọja.
“Nko lero wi pe o le to asiko rẹpẹtẹ bayii, ati pe latigba naa ni ọkan mi ko ti balẹ. Ni isalẹ ọkan mi, mo n lero wi pe eyi kii ṣe opin fun wa, mo mọ pe nipa oore ọfẹ Ọlọrun, ọkọ mi ṣi n pada bọ,” o sọ bẹẹ.
“Mo gbadura pe ki Ọlọrun muu pada bọ layọ, ohun kan ṣoṣo ti mo n fẹ nile aye ree.”















