Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba Naijiria ti dá owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiró padà?

Fatgbems

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹgbẹ awọn to n pin epo bẹntiro jakejado Naijiria, Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria, IPMAN, ti sọ pe ijọba ko tii bẹrẹ si n san owo iranwọ ori epo pada lẹyin to fopin si lọdun to kọja.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Abubakar Migandi Garima, lọ sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ajọ NNPC lo n ko epo wọ Naijiria lati oke okun, ọwọ ajọ naa ati ajọ mii lawọn ti n ra epo.

O fi kun pe lootọ ni NNPC san awọn owo kan laipẹ yii lati ṣeranwọ epo gẹgẹ bii aṣẹ Aarẹ amọ kii ṣe ‘subsidy.’

O ni “titi di asiko yii, a ko gbọ iroyin kankan lati ọdọ ijọba pe oun ti bẹrẹ si n san owo iranwọ ori epo pada.

Nigba to n sọrọ nipa owo iranwọ kan ti ijọba san lori epo laipẹ yii o ni “nigba ti wọn ṣalaye, wọn ni NNPC lo gbe owo naa kalẹ ko le kaju iye owo epo lẹyin ti wọn gba aṣẹ ijọba tan.

“Ṣugbọn niwọn igba ti Aarẹ ti sọ pe ijọba ko ni san owo iranwọ ori epo bẹntiro mọ, ko si ẹni to le sọ pe owo naa ni ‘subsidy.’

“Ohun ti mo mọ ni pe Aarẹ ti sọ pe ko si owo iranwọ ori epo mọ, ọga agba ajọ NNPC naa tun sọ pe ko si owo iranwọ ori epo mọ, o n tumọ si pe ko si iranwọ ori mọ naa niyẹn.

Garima sọ siwaju si pe epo ti NNPC ba ko wọle lawọn n ra amọ lọpọ igba ọwọ ajọ ‘Depot and Petroleum Products Marketers Association of Nigeria (DAPPMAN)’ lawọn ti maa n ra epo.

O ni iwọmba epo diẹ lawọn n ra lọwọ NNPC.

O sọ siwaju si pe lẹyinorẹyin, ọwọ NNPC ni awọn to jẹ IPMAN, ati DAPPMAN ti n ra epo.

Ọ pari ọrọ rẹ pe o ṣeeṣe ki ọwọngogo epo to wa lode dopin laipẹ latari pe NNPC ti ṣeleri bẹẹ.

Àkọlé fídíò, PCOS: Dókítà sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń fa àìsàn PCOS àti ìpalára tó ń ṣe fáwọn obìnrin

Kókó ìdí tí epo bẹntiró ṣe wọ́n ní lásìkò yìi - NNPC

NNPC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti fi han pe o ṣeeṣe ki ọwọngogo epo to wa lode ni Naijiria ṣi tẹsiwaju.

Eyii ko ṣẹyin bi ajọ NNPC ṣe sọ pe oun n koju iṣoro kiko epo wọle latari gbese $6bn to jẹ awọn to n ko epo fun Naijiria.

Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ajọ naa ti kọkọ sẹ fun ọpọlọpọ ọsẹ pe kii ṣe ẹbi oun ni ọwọngogo epo to gbode.

NNPC ti wa sọ bayii pe oun jẹ awọn to n ko epo fun Naijiria ni owo ti iye rẹ to biliọnu mẹfa dọla.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Olufemi Soneye fi lede, NNPC fidi rẹ mulẹ pe gbese naa lo ṣokunfa bi epo ṣe wọn ati bi ọpọ ọkọ ṣe n to sawọn ile epo kaakiri Naijiria.

Ṣaaju lawọn ileeṣẹ iryin abẹle kan ti kọkọ jabọ ninu oṣu Keje ọdun yii pe NNPC jẹ awọn to n ko epo wọle ni gbese to le ni $6bn, eyii to mu ko ṣoro fun ajọ naa lati kede iye owo ti wọn yoo maa ta epo ni pato.

Ileeṣẹ iroyin Reuters sọ pe ṣe ni NNPC n tiraka lati ko epo wọle nigba ti gbese naa kọkọ le ni $3bn ni ibẹrẹ ọdun yii.

A gbọ pe NNPC ko tii san owo awọn epo kan to ko wọle ninu oṣu Kinni ọdun yii, ti gbese naa si n ga si.

Wayi o, ninu adehun NNPC atawọn ileeṣẹ to n pese epo, aarin oṣu mẹta pere ni NNPC gbọdọ san owo epo naa.

NNPC kọ́kọ́ sẹ́

Bi awọn iroyin gbese naa ṣe n jade ni NNPC fesi pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.

Ninu atẹjade kan ninu oṣu Kẹjọ, o ni “NNPC ko jẹ awọn oniṣowo epo ilẹ okere kankan ni owo ti iye rẹ to $6.8bn.

“Ninu òwò epo, awin ni a maa n ra ọja, nitori naa ko jẹ tuntun pe a le ni awọn owo kan ti a ko tii san lawọn igba mii.”

Lẹyin naa ni ajọ ọhun ni oju ọjọ ti ko ṣe dede ati iṣoro ti awọn ọkọ oju omi to n ko epo n dojukọ lo jẹ ki epo wọn ni Naijiiria.

NNPC yi ohun pada

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Amọ nigba ti yoo di ana ode yii, to jẹ ọjọ Aiku, ọjọ kinni, oṣu Kẹsan an, NNPC jẹwọ pe oun n doju kọ awọn iṣoro kan nipa ti owo.

O ni ootọ ni awọn iroyin ti awọn ileeṣẹ iroyin n kọ nipa gbese toun jẹ awọn to n pese epo bẹntiro fun Naijira.

Amọ o fi kun pe oun ko ni sinmi ninu afojusun oun lati ri pe ọwọngogo epo di ohun atijọ ni Naijiria.

Wayi o, NNPC ko mẹnuba igba ti iṣọro ọwọngogo epo to wa lode lasiko yii yoo dopin.