Michael Koleoṣo, tí Gómìnà Makinde fi orúkọ rẹ̀ sọrí Oke-Ogun Polytechnic, jade laye

Michael Koleoso

Oríṣun àwòrán, Michael Koleoso

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Oloye Michael Adeniyi Koleoṣo ti jade laye ni ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun.

Eekan oloṣelu naa, to jẹ ilumọọka ni Oke-Ogun, Ipinlẹ Ọyọ ati Naijiria l'apapọ, ni Babalaje ilu Ṣaki ki ọlọjọ to de.

Laipẹ yii ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde bu ọla fun Oloogbe naa nipa bibuwọlu abadofin to yi orukọ ile ẹkọ gbogboniṣe 'Oke-Ogun Polytechnic' pada si orukọ Oloye Michael Adeniyi Koleoṣo

Igbesẹ naa waye tori ipa ribiribi to ko si idasilẹ ile ẹkọ giga naa l'ọdun 1981.

Michael Koleoso

Oríṣun àwòrán, Michael Koleoso

Kókó pàtàkì nípa ìgbé ayé Michael Koleoso

Wọn bi Oloye Koleoṣo ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹrin ọdun 1938 sinu mọlẹbi Emi-Abata ilu Ṣaki.

O pari ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ ni 'Baptist Primary School ni Ajegunle', Saki, ki o to lọ si ile ẹkọ girama 'Olivet Baptist High School', Ọyọ, laarin ọdun 1957 si 1961.

Lẹyin ti o kẹkọọ gboye ọdun meji akọkọ nile ẹkọ giga ti a ti n kọ nipa imọtoto, 'School of Hygiene', Eleyele niluu Ibadan, Koleoso tẹsiwaju lati kẹkọọ gboye 'RSII' laarin ọdun 1965 si 1966.

Gẹgẹ bii adari ẹka to n mojuto agbegbe Ṣaki, Koleoṣo bẹrẹ iṣẹ ijọba ni ẹkun Iwọ-oorun.

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun lẹnu iṣẹ ijọba, o bẹrẹ si ni da okoowo.

Michael Koleoso bẹrẹ ipo oselu lati Kanselọ, aṣofin ipinlẹ, akọwe ijọba, ko to di alaga ẹgbẹ oselu rẹ

Okoowo akọkọ to dawọle, 'Esmak Nigeria Limited' ṣi wa titi di oni, gẹgẹ bii ileeṣẹ to n pin nnkan elo, to n kọ ileigbe, ri si igbokegbodo ọkọ ati idasilẹ awọn ibudo igbafẹ.

Alagba Koleoṣo dije du ipo gẹgẹ bii kansẹlọ ni ijọba ibilẹ 'Ifedapo Local Government Area' ni Ọyọ atijọ l'ọdun 1976, o si wọle lai si ẹnikẹni to dije tako o.

L'ọdun 1979, o tun wọle si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, gẹgẹ bii aṣoju ẹkun idibo Ifẹdapọ lati inu ẹgbẹ oṣelu Oloye Ọbafẹmi Awolowọ, 'Unity Party of Nigeria (UPN)'.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ lasiko ijọba Oloogbe Gomina Lam Adesina.

Koleoṣo ni alaga ẹgbẹ oṣelu 'Alliance for Democracy AD)' ti o wa tẹlẹri, ki o to di pe wọn fi ajọṣepọ da ẹgbẹ oṣelu 'All Progressives Congress, APC silẹ.