Mọ̀ si nípa àìsàn PCOS tó ń ṣe aburú ńlá fún àgọ́ ara áwọn obìnrin

Àkọlé fídíò, PCOS: Dókítà sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń fa àìsàn PCOS àti ìpalára tó ń ṣe fáwọn obìnrin
Mọ̀ si nípa àìsàn PCOS tó ń ṣe aburú ńlá fún àgọ́ ara áwọn obìnrin

Isẹda awọn obinrin se ẹlẹgẹ pupọ, oniruuru ayipada si lo maa n de ba agọ ara wọn ni akoko kan si omiran.

Oniruuru nnkan si lo n fa ayipada to maa n de ba agọ ara awọn obinrin naa paapaa bo se kan nnkan osu wọn.

Aimọye awọn isoro to n bawọn obinrin yii finra ni ọpọ wọn ko mọ ohun to se okunfa rẹ.

Idi ree ti BBC Yoruba fi se iwadi si awọn ayipada kan to se koko si agọ ara obinrin ati ohun to n faa.

Aworan ile ọmọ lara obinrin ati Stephanie Aderiokun

N jẹ o mọ ohun to n mu ki nnkan osu obinrin se segesege, ki awọn obinrin miran ma ri ọmọ bi, ki wọn sanra abaadi tabi hu irun ni aya?

Ni ọpọ igba ni nnkan osu awọn obinrin mii maa n se segesege, ti ko si ye wọn ohun to n se okunfa isẹlẹ naa.

Bakan naa, ọpọ obinrin ni ko le salaye idi ti ko fi ri oyun ni lasiko to yẹ bi o tilẹ jẹ pe o n sun mọ ọkunrin ni oore koore.

Nigba miran, awọn obinrin yii yoo maa sanra baadi tabi asanju lai le sọ ohun to n sokunfa ara asanju yii.

Tun wẹ, ọpọ obinrin miran lo n hu irungbọn bii awọn ọkunrin, ti wọn si tun n hu irun aya, ti ohun to se okunfa irun naa ko si ye wọn.

BBC Yoruba ti se iwadi imọ ijinlẹ lọdọ awọn onisegun lati mọ ohun to n fa awọn ayipada baadi yii lara awọn obinrin.

Ki ni aisan PCOS wa fun to n mu ayipada ba agọ ara obinrin?

Iwadi BBC Yoruba fihan pe aisan kan wa ti wọn n pe ni PCOS eyi to maa n mu ayipada ba agọ ara awọn obinrin.

Bakan naa ni aisan yii maa n mu ki nnkan obinrin maa se segesege, ti o si seese ko maa tun ri ọmọ bi.

Idi ni pe aisan PCOS yii maa n ba ile ẹyin obinrin ja, aisan yii si lo n lewaju ninu awọn ohun to n se oikunfa airi ọmọ bi fawọn obinrin lagbaye.

Iwadii fihan pe ida mẹjọ si mẹtala obinrin to ti to ọmọ bi ni aisan yii n ba ja.

Ida aadọrin obinrin kaakiri agbaye ni wọn ko si mọ pe awọn ni aisan yii.

BBC Yoruba wa tọ onimọ isegun kan lọ lati tọpinpin nipa aisan nla ọhun, PCOS.

Aworan ile ọmọ lara obinrin

Dokita Henrietta Aniobi, tii se onimọ nipa itọju awọn obinrin to ba BBC Yoruba sọrọ nipa aisan yii ati salaye ipa to n ni lara awọn obinrin.

Dokita Henrietta Aniobi salaye pe awọn obinrin to ba ni arun PCOS ni nnkan osu wọn ko ni maa wa deede.

“Awọn obinrin yii yoo maa ni irun lara bii ọkunrin, irun ori wọn le pa ni aarin ori, wọn kii le ni oyun, ti wọn yoo si sanara abaadi.

Sugbọn eyi ko tumọ si pe ẹni ti ko sanra ko le ni aisan PCOS.

Ilumọọka Obinrin kan, to ni arun PCOS, salaye nipa arun naa...

Abilekọ kan, Stephanie Aderiokun ba BBC Yoruba sọrọ lori bi aisan PCOS se ba ohun faa, ti oun ko si tete ri ọmọ bi lẹyin igbeyawo.

“Mo sarae-sare, mo ri baba wa to n se agbo lati jẹ oyun wa amọ n ko gbọ pa, n ko gbọ po.”

Mo le ma se nnkan osu fun osu marun tabi ọdun kan, to ba si wa, nnkan osu mi naa ko ni da bọrọ.

Ilumọọka ni mi, arun naa n se mi titi di akoko yii amọ nigba ti oyun ko de lakoko ti mo n reti rẹ, mo lọ se amulo ilana igbalode lati ri ọmọ bi ti a mọ si IVF

Mo si loyun, emi naa ree, mo si ti bimọ.”

Stephanie Aderiokun

Ki lo n fa aisan PCOS yii ni agọ ara obinrin ati ipalara to n se?

Ninu alaye rẹ, Dokita Aniobi salaye awọn nnkan to n fa aisan PCOS ninu agọ ara obinrin.

“Arun PCOS yii le jẹ ajogunba fun obinrin, ti aisan naa si lee ran lati ara iya si ọmọbinrin.

Igba mii awọn nnkan ti a maa n jẹ tun le fa arun naa amọ kii se ẹbi ẹni to ni aisan yii, bi wọn se bii niyẹn.

Bi ẹni to ni arun PCOS ko ba si lọ sile iwosan, o le loyun lootọ amọ iru wọn ni wọn kii tete loyun afi ti akoko ba lọ.