Ìwádìí rèé nípa obìnrin tó ní òun yóò fún gbogbo Yoruba ní májèlé àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ si lọ́wọ́lọ́wọ́

Amaka Sonnberger,

Oríṣun àwòrán, Amaka Sonnberger

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ ọlọpaa ilu Toronto, lorilẹede Canada ti tẹ Amaka Sonnberger, obinrin to dunkoko pe oun yoo ṣekupa gbogbo ọmọ Yoruba pẹlu majele.

Ninu apero kan to waye loju poo TikTok ni obirin naa ti sọ pe oun yoo ṣekupa awọn ọmọ ẹya Yoruba ati Benin to ba wa ni sakani oun.

Lẹyin ti ọrọ rẹ naa lu jade lori ayejura ni ọpọ araalu binu, ti wọn si ke si ijọba ko fi ṣikun ofin mu u lẹyin ti wọn ni ọrọ naa ko bojumu, ati pe o le das ija ẹlẹyamẹya silẹ.

Ati mu Amaka Sonnberger, yo foju bale ẹjọ - Ọlọpaa

Ninu atẹjade kan ti ọọfisi ọlọpaa Toronto fi lede, o ni ọjọ Aiku, ọjọ kinni, oṣu Kẹsan an yii ni oun mu Amaka, yoo si foju bale ẹjọ lonii ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Kẹsan an kan naa.

Atẹjade naa ni “a fẹ ki gbogbo araalu mọ pe a ti mu afurasi to sọrọ ikorira lori ayelujara fun iwadii.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ni a gbọ pe o dunkoko naa... lọjọ Aiku, ọjọ kinni, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024, ileeṣẹ ọlọpaa Toronto fi ṣikun ofin mu Amaka Sonnberger, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, ni Toronto.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe ile ẹjọ kan to wa ni “2201 Finch Avenue West” ni wọn yoo ti ṣe ẹjọ afurasi naa laago mẹwaa aarọ.

Ẹsun ti wọn fi kan obinrin naa ni sisọrọ idunkokomọni lori ayejuara si awọn ọmọ Naijiria.

Ki ni ọrọ ti Amaka sọ

Ninu fidio kan to ti fa oju opo X ya bayii ni obinrin kan ti sọrọ tako awọn ọmọ ẹya Yoruba ati ẹya Benin.

Ede Pidgin lo fi sọ ọrọ naa pe oun yo fun awọn ọmọ Yoruba ati Benin ni majele jẹ ki wọn gbogbo wọn le ku.

O fi kun pe oun yoo kọkọ ri daju pe awọn eeyan naa jiya daadaa ki ẹmi to bọ lẹnu wọn.

O ni “ẹ ka ohun mi silẹ daadaa, asiko ti to lati bẹrẹ si n fun awọn ẹya Yoruba ati Benin ni majele jẹ.

“Ẹ fi majele si ounjẹ ati omi wọn, ki gbogbo wọn le maa ku lẹyo kọọkan.”

Ọrọ naa bi ọpọ ọmọ Naijiria ninu, eyii to mu ki wọn ke ṣi ijọba Naijiria ati Canada pe ko fi iya to tọ labẹ ofin jẹ obinrin naa.