Ìbẹ̀rù bojo báwọn aláboyún ní Afghanistan níbi tí obìnrin mẹ́rin ti ń pín bẹ́ẹ̀dì kan lò

Awọn obinrin mẹrin lori bẹẹdi to wa fun enikan ṣoṣo.
Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin mẹrin lori bẹẹdi to wa fun enikan ṣoṣo.
    • Author, Syed Anwar and Swaminathan Natarajan
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ninu ibẹrubojo ni awọn alaboyun wa lorilẹede Afghanistan lẹyin ti ọpọ ile iwosan igbẹbi n kogba wọle lorilẹede naa.

Ọpọ alaboyun ni ko lanfani lati ri dokita fun igba mẹrin to jẹ alakalẹ fawọn oloyun lasiko ti wọn wa ninu oyun.

Alaboyun kan, Farkhunda, to ti loyun fun oṣu mẹfa bayii sọ pe ẹru n boun wi pe o ṣee ṣe ki ọkan nínu oun tabi ọmọ to wa ninu oun ku latari aisi anfaani si eto ilera to peye fawọn alaboyun.

Ile agbẹbi kan ti ajọ eleto ilera lagbaaye WHO n ṣagbatẹru rẹ ni o ti n gbero lati bímọ si.

Amọ, ile igbẹbi naa ti kogba wọle bayii.

"Iṣẹ abẹ ni mo fi bi ọmọ mi akọkọ, mi o mọ ohun to maa ṣẹlẹ pẹlu eyi to wa ninu mi.

Ọrọ naa n kọ mi lominu," Farkhunda lo sọ bẹẹ.

Awọn ọmọ ikoko meji ti ko gbo ti wọn gbe sinu igo.

Oríṣun àwòrán, Dr Najmussama Shefajo

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ikoko meji ti ko gbo ti wọn gbe sinu igo.

Ile agbẹbi ti ko dara to

Badakhshan jẹ bi ti ọpọ ri gẹgẹ bi ibikan to buru julọ lati bímọ si.

Ajọ WHO sọ fun BBC wi pe oun ni lati gbe ile agbẹbi to lẹkun naa pa tori ọwọn owo.

Oṣiṣẹ ile agbẹbi naa sọ fun BBC pe o maa n to bii iṣẹ abẹ mẹẹdogun lati gbe ọmọ jade ti ile agbẹbi naa maa n ṣe ki o to di titi pa.

Bakan naa ni oṣiṣẹ ọhun tun sọ pe oriṣiiriṣii nnkan mii ni wọn n ṣe nipa itọju awọn eeyan níbẹ.

Ile agbẹbi mii to tun wa lẹkun Badakhshan ni ajọ onitọrẹ aanu Aga Khan n ṣagbatẹru rẹ.

Ọwọ awọn dokita mẹrin at'awọn akọṣẹmọṣẹ meji to wa nibẹ ti di bayii pẹlu bi awọn eeyan to nilo itọju ṣe n pọ si.

Ile iwosan to tun sun mọ to irin wakati marun-un ki eeyan to de ibẹ.

Iku to buru jai

Akọsilẹ ajọ UNICEF fidi rẹ múlẹ pe ọmọ ikoko 620 ni 100,000 ti wọn bi lọdun 2020 ni Afghanistan.

Orilẹede Afghanistan wa ninu awọn orilẹ-ede to lewu julọ lati gbe fáwọn ọmọ ikoko.

Lọdun 2023, ọmọ ikoko mẹtadinlogoji lo ku ninu ẹgbẹrun ọmọ ti wọn bi.

Dokita kan to fi Jalalabad ṣe ibugbe sọ pe ko si irinṣẹ l'awọn ile iwosan ijọba lati ṣe itọju awọ ọmọ inu igo.

Aisi awọn agbẹbi

Akọsilẹ UNICEF sọ pe ida kan ninu ida mẹta lo n bimọ nibi ti kii ṣe ile agbẹbi.

Eyi tumọ si ọpọ awọn obinrin lo n bimọ sile tabi t'awọn eeyan ti mọ nipa gbigbẹbi n gbẹni fun wọn.

Agbẹbi kan to wa ni igberiko lẹkun Kandahar sọ pe "ọpọ eeyan lo n bimọ sile eyi to si lewu gan an.

Awọn eeyan abule ti gbe obinrin kan wa ri to bimọ ni bii ago meji oru amọ ti ibi ọmọ ko jade.

Ẹbi rẹ ni lati duro ko ilẹ fi mọ ti wọn ti gbe e lọ sile iwosan.

A tọju obinrin yii, o si pada gbadun.

Ka ni pe o pẹ ju bayẹn lọ ki wọn to gbe e wa ni, obinrin naa ko ba ku.

Ohun to ba ni lọkan jẹ

 Musrsal obinrin Afghanistan ree ninu hijaabu to bo o loju.

Oríṣun àwòrán, Dr Najmussama Shefajo

Àkọlé àwòrán, Musrsal obinrin Afghanistan ree ninu hijaabu to bo o loju.

Diẹ ninu awọn obinrin lo lagbara lati sanwo ile iwosan.

Musrsal ẹni ọdun marundilogoji jẹ obinrin kan ti oyun ti bajẹ lara rẹ nigba meje ọtọtọ, nigba ti oyun ti bajẹ lara Hamida ẹni ogun ni igba mẹrin.

Musrsal ni "ni gbogbo igba ti ọmọ ba ti ku mọ mi lọwọ, o maa n ṣe mi bi ẹni pe mo ti padanu idaji ọpọlọ mi.

Awọn dokita sọ fun mi pe ounjẹ gidi jẹ wa lara awọn ohun to ṣokunfa bi oyun ṣe n bajẹ lara mi."

Kandahar sọ pe "bi oṣu mẹfa sẹyin ni oyun bajẹ lara mi kẹyin.

Ni orilẹede Pakistan ni awọn ilu meji yoku wa.

Awọn dokita Kandahar sọ pe kokoro lo n da a laamu ninu, wọn si ti sọ abẹrẹ ti yoo gba.

Ọmọ ọdun mẹrindilogun ni Hamida ti lọ sile ọkọ, amọ, gbogbo eeyan lo n tabuku rẹ bayii pe ko tii bimọ.

Hamida ati Mursa to oniruuru ayẹwo eyi ti wọn n reti esi rẹ bayii.

Dokita Najmussama Shefajo lo n tọju Musrsal ati Hamida.

 Hamida ree to n sọrọ lori foonu

Oríṣun àwòrán, Dr Najmussama Shefajo

Àkọlé àwòrán, Hamida ree to n sọrọ lori foonu

Dokita Shejafo lara awọn iṣoro to n koju awọn oloyun ni aisi dokita obinrin at'awọn nọọsi, aisi ile iwosan awọn akọṣẹmọṣẹ ati oogun.

Awọn ti ko kawe naa wa lara awọn iṣoro ohun.

Ọpọ awọn dokita obinrin lo fi ilu silẹ lẹyin t'awọn Taliban gba ijọba lọdun 2021.

Ijọba tuntun kọ lati fawọn obinrin dokita ni iwe ẹri lati le maa fi ṣiṣẹ.

Dokita Shejafo ni awọn ile iwosan ijọba nikan ko to lati tọju awọn eeyan.

O ni oun ti ibi ti awọn obirin mẹrin ti ẹjẹ n da lara wọn ti wa lori bẹẹdi kan ṣoṣo.

Bakan naa ni o sọ pe oun ti ri ibi ti wọn gbe ọmọ ikoko mẹrin sinu inkubetọ kan ṣoṣo.

Ariyanjiyan

Dokita Najmussama Shefajo to n tọju Musrsal ati Hamida.

Oríṣun àwòrán, Dr Najmussama Shefajo

Àkọlé àwòrán, Dokita Najmussama Shefajo to n tọju Musrsal ati Hamida.

Agbẹnusọ ijọba Taliban sọ pe kudiẹ kudiẹ to wa lẹka eto ilera ni ṣe pẹlu aiṣedeedee ijọba to lọ.

Dokita Sharafat Zaman ni ijọba n ṣiṣẹ lori ati pese eto ilera to peye fawọn araalu.

Agbẹnusọ ẹka eto ilera ni Afghanistan, Dokita Sharafat Zaman.

Oríṣun àwòrán, Dr Sharafat Zaman Amar

Àkọlé àwòrán, Agbẹnusọ ẹka eto ilera ni Afghanistan, Dokita Sharafat Zaman.

Ọkan Farkhunda to n gbe ni Badakhshan ko balẹ.

Oṣu kẹwaa to n bọ lo yẹ ki ọjọ rẹ pe lati bímọ, ẹru n ba a.

Ibi to yẹ ki o bimọ si ti kun fọfọ bayii, bẹẹdi ọgbọn pere lo wa nile iwosan naa.

O ni oun o lagbara lati san $355 nile iwosan aladaani bakan naa.

Farkhunda si mọ pe oun ko le pe agbẹbi wi pe ko wa gbebi foun nile tori o lodi sofin ijọba Taliban.

Farkhunda ni awọn obinrin ko ni anfani daadaa s'awọn ile iwosan ni Afghanistan.

Orukọ mii ni a lo fawọn ti a durukọ ninu iroyin yii lati le daabo bo wọn.