Wo kókó àdéhùn márùn-ún tí Tinubu tọwọ́bọ pẹ̀lú China, túmọ̀ sí fún ọ

Ààrẹ Tinubu àti ààrẹ China, Xi Jinping

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN PRESIDENCY

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti tọwọ́bọ àdéhùn márùń-ún pẹ̀lú ààrẹ orílẹ̀ èdè China, Xi Jinping láti mú ìgbò]orò bá ètò ọrọ̀ ajé orílè èdè méjéèjì.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2024 ni Tinubu àdéhùn náà lásìkò tó ń kópa ní àpérò orílẹ̀ èdè China àti Áfíríkà tọdún 2024.

Nígbà tí Tinubu ń gbéra lọ fún àpérò náà lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, agbẹnusọ Tinubu, Ajuri Ngelale sọ pé Tinubu yóò ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Xi Jinping àtàwọn èèkàn nídìí okoòwò ní China.

Bákan náà ni yóò tún kópa níbi àpérò ètò ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè China àti àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà, èyí tó máa wáyé láàárín ọjọ́ Kẹrin sí ọjọ́ Kẹfà, oṣù Keje.

Àpérò China àtàwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà jẹ́ àpérò láti mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà àti China, tó sì máa ń wáyé ní ọdún mẹ́ta mẹ́ta.

Kí ló wà nínú àdéhùn tí wọ́n tọwọ́bọ náà?

Àjọṣepọ̀ láàárín Nàìjíríà àti China lórí àmúṣẹ àti àgbéga ètò Belt and Road Initiative

Ìfẹnukò lórí àjọṣepọ̀ lórí ìṣàmúlò àwọn ohun àmúṣagbára

Àdéhùn lórí ṣíṣe àgbéga fún ètò ìgbágbára wọni lábẹ́ ètò Global Development Initiative

Àdéhùn lórí ìṣàmúlò ìròyìn àti àjọṣepọ̀

Àjọṣepọ̀ láàárín iléeṣẹ́ ìròyìn China àti iléeṣẹ́ ìròyìn Nigerian Television Authority (NTA)

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Nàìjíríà àti China fẹnukò lórí okoòwò, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ètò ọrọ̀ ajé

Ààrẹ Tinubu sọ pé Nàìjíríà àti China nílò láti máa pọkún àjọṣepọ̀ tọ wà láàárín àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì kí ìgbòòrò le bá okoòwò àti ètò ọrọ̀ ajé wọn.

Tinubu ni òun tí ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti mú àtúntò bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà bí China náà ṣe ṣe tí wọ́n fi dé ibi tí wọ́n wà lónìí.

“A ti ṣàwárí ìnílò láti mú àtúntò bá ètò ọrọ̀ ajé wa, a sì ti ń gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn orí tó fi mọ́ gbogbo àwọn ẹ̀ka tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè wa,” Tinubu sọ.

“Àwọn tó bá fẹ́ dókoòwò ní àǹfàní láti ṣe bẹ́ẹ̀ láì sí ìdíwọ́ kankan fún wọn.”

Ààrẹ China, Xi Jinping ní ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Nàìjíríà àti China ti lé ní àádọ́ta ọdún àti pé òun ní ìgbàgbọ́ pé àjọṣe pọ̀ náà yóò mú ìgbà ọ̀tun bá àjọṣepọ̀ China àti ilẹ̀ Áfíríkà yòókù.

Àdéhùn tó ti wà láàárín Nàìjíríà àti China tẹ́lẹ̀

Ní ọdún 2018, ààrẹ àná, Muhammadu Buhari tọwọ́bọ àdéhùn pẹ̀lú ìjọba China láti pèsè ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́ kan tí ìjọba rẹ̀ gùnlé nígbà náà.

Buhari yá owó mílíọ̀nù 328 dọ́là ($328m) lọ́wọ́ China lásìkò tó kópa níbi àpérò àjọṣepọ̀ China àti Áfíríkà tó wáyé ní Beijing lọ́dún náà lọ́hùn-ún.

Ṣáájú ni China, lọ́dun 2013 yá Nàìjíríà ní $1.1bn láti fi pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nílò lásìkò ìṣèjọba ààrẹ Goodluck Jonathan.

Owó náà ni wọ́n ló wà fún ìpèsè ọ̀nà, pápákọ̀ òfurufú àti ọkọ̀ ojú irin ti ìgbàlódé.

Lásìkò náà ni China ń ran ilẹ̀ Áfíríkà lọ́wọ́ lórí àwọn amáyédẹrùn bí òhun náà ṣe ń gbáralé epo rọ̀bì tó wà nílẹ̀ Áfíríkà.