Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 3 Owewe, 2024
Keeeere o! Konile o gbọ ko sọ fun t’oko?
Pe ki ni o?
Pe ajọ NNPC ti kede afikun iye owo lita epo bẹntiro ni Naijiria
Hmmmmmm
N897 naira ni NNPC yoo maa ta epo bayii, dipo 568 naira to n taa tẹlẹ
Lori ọrọ epo yii naa ṣi ni o
Ileeṣẹ Dangote Refineries ni oun ti ṣetan lati bẹrẹ si n ta epo bẹntiro f’araalu, lati oni lọ
Aliko Dangote sọ nibi ipade akọroyin kan pe epo oun dara pupọ, yoo si fopin si ọwọngogo epo to wa laarin ilu
Ile ẹjọ majistreeti kan nipinlẹ Kwara ti bẹrẹ igbẹjọ awọn afurari to lọwọ ninu iku ẹni ọdun mọkanlelgun kan, Mojisola Awesu
Tọ jẹ akẹkọọ ti wọn ba oku rẹ lori akitan niluu Ilorin
Ṣe ni Mojisola tẹle ọkunrin kan lọ ile itura, lẹyin ti ọkunrin naa ṣeleri ẹgbẹrun mẹẹdogun naira fun to ba le dibọn bii ọrẹbinrin rẹ
Lẹyinorẹyin, oku Bidsola ni wọn gbe lọ ba awọn obi rẹ
Ti ẹ ba fẹ mọ bo ṣe n lọ