Gbajúmọ̀ eléré ìdárayá tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ dáná sun, jáde láyé

Rebecca Cheptegei

Oríṣun àwòrán, Alamy

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Rebecca Cheptegei, tii se gbajugbaja elere idaraya tó ń soju ilẹ Uganda ninu idije ere idaraya Olympics ti jade laye.

Awọn alasẹ ilẹ Uganda ni Rebecca ku lẹyin ọjọ diẹ ti ọrẹkunrin rẹ tẹlẹ, dana sun-un.

Awọn dokita to n se itọju ọmọbinrin elere idaraya naa, tii se ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ni wọn sọ pe o jona kọja ala lalẹ ọjọ Aiku to kọja, ti isẹlẹ naa waye.

Awọn alasẹ ẹkun North-West lorilẹede Kenya ti Rebecca n gbe salaye pe se ni ọkunrin naa kọ lu u nigba to ti ile ijọsin de.

Ere olobiripo ti wọn n pe ni Marathon lede Gẹẹsi ni Rebecca Cheptegei ma n sa, koda o kopa ninu idije Paris Olympics to ṣẹsẹ pari.

Ile rẹ to wa ni Iwọ oorun Kenya, nibi to ti ma n ṣe igbaradi, ni ọkunrin naa ti kọlu u.

Iroyin sọ pe awọn aladugbo Arabinrin Ms Cheptegei lo doola rẹ lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ Aiku to kọja nile rẹ to wa niluu Endebess.

Ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo, Moi Teaching and Referral Hospital to wa ni Eldoret, ni awọn mejeeji ti n gba itọju.

Oludari agba kan nileewosan naa sọ pe awọn fun obinrin naa ni oogun orun ni, nitori bi o ṣe jona to.

Rebecca Cheptegei

Oríṣun àwòrán, Uganda Athletics Federation/X Rebecca Cheptegei won the World Mountain and Trail

Bawo ni ọrọ ṣe ṣẹlẹ gan-an?

Olori ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe naa, Jeremiah Ole Kasiom, sọ fun awọn akọroyin pe, ṣọọṣi lo ti n bọ, pẹlu awọn ọmọ rẹ mejeeji, nigba ti ọkunrin naa kọlu.

O ni, ẹni ti wọn fi ẹsun kan ọhun naa jona pupọ.

"Ariwo ija ololufẹ meji ọhun ni awọn ara adugbo gbọ, nita ile wọn. Lasiko rogbodiyan naa, ọrẹkinrin ọhun ni àwọn eeyan ri to n da epo bẹtiro le obinrin naa lori, ko to dana sun-un.

Ilu kan lẹyin odi ni Uganda, ni Arabinrin Cheptegei ti wa.

Awọn to mọ ọ sọ pe o ra ilẹ kan ni agbegbe Trans Nzoia, to si kọ ile kan sibẹ ko le ba a sunmọ ọpọlọpọ ibudo igbaradi to wa ni Kenya.

Akọsilẹ ti alaṣẹ kan niluu naa kọ sọ pe awọn mejeeji ti n ja tipẹ lori ọrọ ilẹ naa.

Awọn ọlọpaa sọ pe iwadii n lọ lọwọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, baba Arabinrin Cheptegei, Ọgbẹni Joseph Cheptegei, sọ pe idajọ ni oun fẹ fun ọmọ oun.

Ipo kẹrinlelogoji ni Arabinrin Cheptegei ṣe ninu idije olobiripo, ni Paris Olympics.

Bakan naa lo gba ami ẹyẹ goolu ni idije World Mountain and Trail Running Championships to waye ni Chiang Mai, Thailand, lọdun 2022.

Ikọlu si awọn elere idaraya ko ṣẹsẹ maa waye ni Kenya.

Ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2022, wọn ba oku elere idaraya obinrin, Damaris Mutua, ti wọn fun ni ọrun pa ninu ile kan niluu Iten, pẹlu irọri to bo o loju.

Iṣẹlẹ naa waye lẹyin oṣu die ti wọn ba oku elere sisa, Agnes Tirop, ti wọn gun pa niluu naa bakan naa.

Awọn ọkunrin ti wọn n fẹ ni wọn fi ẹsun kan ninu iṣẹlẹ mejeeji.

Ọkọ Arabinrin Tilop ṣi n koju ẹsun ipaniyan botilẹ jẹ pe o ni, oun ko jẹbi.

Wọn ṣi n wa ọrẹkinrin Arabinrin Mutua ni ti rẹ.

Awọn ọkunrin naa ma n kagbako. Ninu oṣu Kejìla, ọdun to kọja, awọn kan gun elere idaraya, ọmọ orile-ede Uganda, Benjamin Kiplagat pa ni Eldoret.