Ìdí tí Soun Ogbomoso fi yan ìmáàmù ààfin tuntun rèé

Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Soun Ogbomoso

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Oloye Orumogege III ti yan Habib Ahmed Adekunle gẹgẹ bii Imaamu tuntun fun aafin Soun ti ilẹ Ogbomoso.

Eto yii lo waye lẹyin ti awọn Musulumi ilu naa pejọ lati ṣe akanse eto adura fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹtalelọgọta Ọba ohun.

Nibi ayẹyẹ naa ni Soun ti kede pe Imaamu aafin tuntun naa ni yoo maa ṣoju aafin oun ninu gbogbo ipade to nii ṣe pẹlu awọn Musulumi ilu Ogbomoso ati aafin.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni wahala kan ti kọkọ waye laarin Ṣọun ati Imaamu agba Sheikh Toliat Ayilara.

Asiko naa ni imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.

Ninu oṣu keje ọdun yii ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ayodele Sonubi pe ipade alafia laarin, kabiyesi ati Sheikh Taliat Ayilara, ẹni ti o jẹ imaamu ilu naa.

Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Soun Ogbomoso

Aawọ to n waye laarin Imaamu agba ati Sọun si wa nile ẹjọ, Imaamu agba ko wa si aafin mọ lati maa lewaju adura fun Soun ni gbogbo ọjọ Jimoh saaju irun janmọ – Aarẹ Ago

Ninu ifọrọwerọ BBC Yoruba pẹlu aṣoju aafin lori igbese yii, oloye agba Samuel Otolorin, to jẹ Aarẹ Ago ti ilẹ Ogbomoso ni Soun ko se aṣiṣe pẹlu yiyan imaamu aafin tuntun.

Aarẹ Ago fun ilu Ogbomoso ni lati igba ti Sheikh Toliat Ayilara ti gbe Ọba Ghandi Afolabi Oloye lọ si ile ẹjọ, ni o ti tẹti ninu awọn ojuṣe rẹ si aafin.

Paapaa julọ, o ni Imaamu agba naa ko wa si aafin mọ lati maa lewaju adura fun Soun ni gbogbo ọjọ Jimoh ṣaaju ki wọn to kirun Jimoh ni mọṣalaṣi apapọ Ogbomoso.

Oloye Aarẹ ago ni “ireti ni pe nigba ti Sheikh Toliat Yusuf ti lọ si ile ẹjọ ati wi pe boya yoo ronu piwada funra ara rẹ yoo mu awọn ẹsun ile ẹjọ kuro.

Lẹyin oṣu mẹfa ni kabiyesi wa wo wi pe o yẹ ki awọn ni imaamu ti yoo maa ṣoju aafin, nitori idi eyi ni wọn fi yan imaamu aafin, ipo naa si yatọ si oye Imamu agba.

“Ara iṣẹ imaamu aafin tuntun yii ni lati wa ṣe adura fun kabiyesi ati aafin lapapọ nitori pe laipẹ yii ni kabiyesi yoo yan aṣoju awọn ẹlẹṣin Kristẹni fun aafin.

“Ṣe ẹ mọ wi pe ẹjọ wa ni ile ẹjọ a ko si gbọdọ tapa si igbese ile ẹjọ, imaamu aafin la yan, ti wọn ba si pe kabiyesi si ode to jẹ mọ ẹṣin Islam imaamu yii ni yoo jẹ aṣoju wọn nibẹ.”

Aṣoju idile ati Soun ni mo jẹ laafin – Habib Ahmed, Imaamu Aafin

Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Soun Ogbomoso

Ninu ọrọ rẹ, imaamu aafin Soun tuntun, Sheikh Habib Ahmed Adekunle Ayilara ṣalaye pe igbesẹ kabiyesi yii yoo mu ki alaafia wa ninu agbo ile Ayilara.

Sheikh Ahmed ni agbọye ti wa laarin oun ati kabiyesi lati mu igbelarugẹ ba ẹṣin Islam.

Sheikh aafin tun ṣalaye wi pe “aṣoju idile ni mo jẹ fun aafin nitori kabiyesi fi ye mi wi pe, gbogbo ibiti wọn ba ti pe awọn si, ni ẹkọọkan ni maa ti ma ṣe aṣoju awọn nibẹ.

O wa ṣeleri lati mu isọkan ba gbogbo ẹsin to wa niluu Ogbomoso.