Èèwọ̀ 25 tó wà ní ààfin Ewi Ado Ekiti àti ewu tó wà fún ẹni tó bá lu àwọn èèwọ̀ náà
Ni ilẹ Yoruba, oniruuru eewọ lo wa ti awọn eeyan n tẹle, a si lee se sọ pe eewọ tumọ si ohun ti ẹnikẹni ko gbọdọ se.
Bakan naa, ọpọ eewọ yii lo ni awọn ijiya tabi ewu to tẹle ti ẹnikẹni ba lu awọn eewọ yii.
Ni aafin Ewi, tii se oriade tilu Ado Ekiti, oniruuru awọn eewọ lo wa eyi to to mẹẹdọgbọn niye.
Bakan naa ni ọpọ ijiya tabi ewu rọ mọ awọn eewọ yii eyi to yẹ ki awọn araalu tabi alejo to ba fẹ se abẹwo si aafin naa mọ.
Ọna lati mọ awọn eewọ naa lo gbe BBC Yoruba lọ si aafin Ewi tilu Ado Ekiti, bakan naa la tun fẹ mọ ọpọ ewu to rọ mọ awọn eewọ naa.
Tun wẹ, BBC Yoruba fẹ mọ pataki aafin to ni eewọ bii mẹẹdọgbọn yii ninu itan ilẹ Yoruba ati idi ti aafin naa se yatọ si tawọn akẹẹgbẹ rẹ yoku.

“Aafin Ewi jẹ aafin pataki nilẹ Yoruba tori Ọọni tuntun lati Ile Ife, gbọdọ wa si aafin Ado lati tẹ ẹjẹ wọle, bura ni ojubọ meji si mẹta”
BBC Yoruba, nigba ta de aafin Ewi ti Ado Ekiti, ba Ẹlẹgbira ilu Ado Ekiti, Oloye Adekumola Kayode sọrọ, ẹni to salaye nipa pataki aafin Ewi ato awọn eewọ to wa nibẹ.
Oloye Adekumola ni aafin Ewi jẹ aafin kan pataki nilẹ Yoruba, to jẹ pe ti wọn ba fi Ọọni tuntun jẹ nilu Ile Ife, o si maa wa si ilu Ado Ekiti lati rubọ ni ojubọ mẹta si marun, ti yoo si tun se ibura nibẹ.
“Ọọni tuntun gbọdọ wa silu Ado, ti yoo si ya si ojubọ bii marun nibi ti wọn yoo ti bura fun, ti wọn yoo si tun se adura fun nibẹ, ko to pada si Ile Ife.
Ni igba iwasẹ titi di akoko yii, ti Ọọni ba ti fẹ wle si aafin Ado, ẹjẹ ẹlá lo maa tẹ wọle, eyi ti wọn maa ba si ẹnu ọna abawọle.
Igba yẹn ni Ọọni yoo ni oun fi ẹsẹ Oodua tẹ aafin Ado wọle, ko to di pe o le wọle sinu aafin naa.
Lai tẹ ẹjẹ naa wọle, Ọọni ko le wọle sinu aafin Ewi ti Ado Ekiti laelae.”

Eewọ mẹẹdọgbọn to wa ni aafin Ewi ti onile ati alejo gbọdọ tẹle
Nigba to n salaye ni ẹkunrẹrẹ fun BBC Yoruba, Oloye Adekumọla sọ awọn eewọ to wa ni aafin Ewi ti Ado Ekiti, eyi to yẹ ki ẹni to ba jẹ alejo nilu naa gbọdọ kiyesi daadaa.
- Eewọ ni lati gbe ọmọ tuntun ti wọn ko tii ge iru akọkọ fun wọ inu aafin bi bẹẹ kọ, ọmọ naa yoo ku to ba dele
- Eewọ ni lati bimọ sinu aafin
- Eewọ ni lati ku sinu aafin tabi gbe oku wọ inu aafin tabi gbe oku jade nibẹ
- Ẹnikẹni ko gbọdọ sunkun ninu aafin boya lati sunkun wọle tabi sunkun jade
- Wọn kii kawọ mọ aya ninu aafin yii
- Wọn kii gbe ẹsẹ le ori ara wọn nibi lasiko ijoko tabi gbe ẹsẹ lori orukun ninu aafin
- Wọn kii poṣe ninu aafin Ewi
- Wọn kii sepe ninu aafin Ado
- Wọn kii fi nnkan tẹlẹ sori aga, ki wọn to joko
- Wọn kii wọn asọ dudu wọ inu aafin Ado.

"Ẹni to ba gbe nnkan kọrun ni igboro, Alogbo aafin yoo mu wa si aafin, oju wọn yoo ri nnkan ti ko tẹ ki wọn jẹ tabi se"
Awọn eewọ yoku to tun wa ni aafin Ewi tilu Ado Ekiti ni iwọnyi.
- Eewọ ni lati gbọwọ lẹ́rán tabi fi ọwọ ti agbọn ninu aafin
- Eewọ ni lati ru ẹnikan le ejika laarin igboro ado tabi wọnu aafin
- Ẹnikẹni ko gbọdọ sare wọ inu aafin tabi sare jade kuro lati aafin pẹlu ẹsẹ, kẹkẹ tabi alupupu
- Eewọ ni lati tu itọ ninu aafin
- Eewọ ni lati run orin wọ inu aafin
- Eewọ ni lati sufe ninu aafin
- Eewọ ni lati mu siga tabi ikoko ninu aafin
- Eewọ ni lati ki Kabiyesi Ewi lai kọkọ ki Ologun Adele
- Ẹni to ba gbe nnkan kọrun ni igboro, Alogbo aafin yoo mu wa si aafin, oju wọn yoo ri nnkan ti ko tẹ ki wọn jẹ tabi se.

Nipari, awọn eewọ yoku ree to wa ni aafin Ewi ti Ado Ekiti.
- Ewi nikan ni ẹnikan soso to maa n gbe ru eeyan tabi sọ eeyan kalẹ ni igboro Ado
- Wọn kii tẹ ọ̀pa wọ aafin Ado, eewọ orisa, ẹni to ba tẹ ọpa wọnu aafin Ado yoo so ẹran kan mọlẹ. Ewi nikan ni ẹnikansoso to maa n tẹ ọpa wọnu aafin
- Wọn kii mu isu tuntun wọ inu aafin, o seewọ, tori pe nnkan aburu maa sẹlẹ lẹyin rẹ
- Wọn kii gun ẹsin wọ ilu Ado Ekiti nitori pe o ni idi. Ti wọn ba gun ẹsin wọ aafin Ado Ekiti, o ni nnkan to maa sẹlẹ si ẹniyẹn
- Ile adura wa nibi, ibẹ ni gbogob oloye to ba fẹ jẹ yoo wọ nigba mẹta fun adura. Ko si ẹni ti wọn ba bura fun nibẹ, to ba ti tẹle ibura, isẹ rẹ ti bẹrẹ si ni dara niyẹn
- Bakan naa, ti ẹni to ba se aburu, ba bura nile adura naa, oju ẹsẹ ni isẹlẹ kan yoo ti sẹlẹ si. Wọn kii fi ibura ile adura naa sere, gbogbo ibura ti eeyan ba bu nibẹ, ẹni to bura gbọdọ tẹle ibura naa.






