"Èmi àti ọkọ mi dìjọ jẹun alẹ́, ta ayò papọ̀ àmọ́ ó kọlù mi lójú oorun, mo sì pàdánù ojú méjéèjì"

Arábìnrin kan, Amarachi Lawrence ti tẹnu bọ ọ̀rọ̀ lórí bí ọkọ rẹ̀ ṣe ṣe ìkọlù si lórù láti ojú orun, tó si pàdánù ojú rẹ̀ méjéèjì.
Ní ìlú Umuahia, ìpínlẹ̀ Anambra ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí ti wáyé lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ ọdún 2024.
Amarachi, ẹni tó ṣì wà nílé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọ́jú lórí ojú rẹ̀ méjéèjì sọ fún BBC pé ṣàdédé ni ọkọ òun ki òun mọ́lẹ̀ lóru láì ṣe wí pé òun ṣe nǹkankan fun.
Ó ní kò sí ìjà láàárín òun àti ọkọ òun kí àwọn tó lọ sùn nítorí lẹ́yìn tí àwọn jẹun alẹ́ tán, àwọn tún jọ ta ayò “Whot” kí àwọn tó wọlé sùn.
Ó ṣàlàyé pé nǹkan bíi aago kan òru ni ọkọ òun jí òun kalẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lu òun, ó ní bó ṣe ń lu òun ló ń fi ọwọ́ tẹ òun ní ojú méjéèjì mọlẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ méjéèjì.

“Ọkọ mi jí mi lóru, ó bẹ̀rẹ̀ sí lù mí, ó ń bú mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí pariwo, ìyàwó bàbá onílé wa jáde sí wa àmọ́ ọkọ mi gún -un lọ́bẹ”
Amarachi Lawrence tẹ̀sìwájú pé “Lẹ́yìn ti a jẹun alẹ́ tán, a ta ayò whot.
“Ọkọ mi jí mi lóru mo sì sọ fún pé kó jẹ́ kí n sùn ṣùgbọ́n ó kọ̀ tó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ fẹ ojú mi láti là á.
“O bẹ̀rẹ̀ sí ní lù mí, tó sì ń bú mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo, títí tí ìyàwó bàbá onílé wa fi jáde sí wa.”
Amarachi sọ pé bí ọkọ òun ṣe ṣílẹ̀kùn ló gún ìyàwọ bàbá onílé àwọn, tó fẹ́ wá làjà láàárín àwọn méjéèjì ni ọbẹ.
O fikun pe láti ìgbà náà ni òun kò mọ nǹkankan tó ń ṣẹlẹ̀ mọ́ àfi ìgbà tí òun jí nílé ìwòsàn.
Amarachi fi kun pé ìgbéyàwọ àwọn kò ì tíì pé ọdún kan àti pé àwọn kò ì tíì bí ọmọ kankan.
Ó wá rọ ìjọba láti ran òun lọ́wọ́ àti àwọn obìnrin tó bá ń la ìṣòro bí i ti òun kọjá nílé ọkọ.
Ọkọ Amarachi, Lawrence Uzor ló jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Umuhu Ezechi nígbà tí Amarachi jẹ́ ọmọ ìlú Umuahia ní ìpínlẹ̀ Abia.
"Lawrence gún mi ni ọbẹ nígbà tí mo fẹ́ gba ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀"

Oríṣun àwòrán, Other
Ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Priscilla Otti ṣàbẹ̀wò sí Amarachi nílé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọ́jú
Ẹni tó ni ilé táwọn tọkọtaya náà ń gbé, Lovejane Nwaiwu sọ pé nǹkan bíi aago mẹ́wàá alẹ́ ni òun ń gbọ́ tí Lawrence ń pariwo “odogwu, odogwu”.
Ó ní nígbà tó yá ni òun kò gbọ́ nǹkankan mọ́ títí di aago méjìlá òru tí òun fi sùn.
Ó ṣàlàyé pé aago kan ni òun túnbẹ̀rẹ̀ sí ni gbọ́ ariwo ti ìyàwó ń pariwo pé ìyà òun, wọ́n ti pa òun o.
Ó sọ pé òun ṣí ilẹ̀kùn tí òun sì rí ọkùnrin náà tó mú ọ̀bẹ dání pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀.
“Mo sáré kan ilẹ̀kùn yàrá àwọn ará ilé tó kù àmọ́ kò sí ẹni tó dámi lóhùn nínú wọn.
“Nígbà tí mo lọ kan ilẹ̀kùn wọn, ọkọ jáde sí mi, tó sì fẹ́ fi ọ̀bẹ gún mi lórí ni mo sáré sá kúrò níbẹ̀ lọ sí yàrá wa padà.”
Lovejane Nwaiwu ní èyí ló mú òun lọ pé ọmọ òun lórí fóònù, tó sì pé àwọn ọlọ́pàá láti wá mú ọkùnrin náà.
Ó sọ pé Lawrence ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá níbi tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò.
Ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Priscilla Otti ṣàbẹ̀wò sí Amarachi nílé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọ́jú, tó sì bẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn tó wà ní àwọn ń ṣiṣẹ́ láti ri pé Amarachi le fojú rẹ̀ ríran padà.















