Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 5 Owewe, 2024

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 5 Owewe, 2024
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 5 Owewe, 2024

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Naijiria NANS

Ti kede pe irọ ni iroyin to n lọ nigboro pe awọn fẹ ṣe iwọde latari afikun owo epo bẹntiro

NANS lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti adari rẹ, Akinteye Afeez Babatunde, buwọlu

Babatunde ni ko si ohun to jọ iwọde niwaju awọn lasiko yii

Eemọ wọlu, ọkọ fọ oju iyawo rẹ lorumọju

Ilu Umuahia, nipinlẹ Anambra ni iṣẹlẹ naa ti waye

Amarachi Lawrence ni oju orun loun wa ki ọkọ oun to ki oun mọlẹ lai si ija laarin wọn tẹlẹ

O ṣalaye pe nnkan bii aago kan oru ni ọkunrin naa bẹrẹ si n lu oun, to si n fi ọwọ tẹ oju oun memeji

Obirin naa ti wa nile iwosan bayii, nibi to ti n gba itọju

Ni Uganda

Gbajugbaja elere idaraya kan, Rebecca Cheptegei, ti jde laye lẹyin ti ọrẹkunrin rẹ dana sun-un

A gbọ pe ile ijọsin ni obinrin naa ti n bọ ki iṣẹlẹ ọhun to waye

Iroyin ni ọrọ ilẹ lo da ija silẹ laarin awọn ololufẹ mejeji