Afurasí ọ̀dọ́ ajínigbé gbé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin fásitì, ó gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ òbí kó tó pa á, tó sì sin-ín sọ́gbà ilé wọn - Ọlọ́pàá

Christiana Idowu ati Ayomide Adeleye

Oríṣun àwòrán, Lagos Police

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe oun ti fi ṣikun ofin mu Ayomide Adeleye lori ẹsun pe oun lo ṣekupa Christiana Idowu, to si sin oku rẹ.

Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Ayomide nigba ti Christiana jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni awọn ọmọ ogun lo fa afurasi naa le ọlọpaa lọwọ fun iwadii ni kikun.

Hundeyin ni “Ọ̀wọ́ ileesẹ ologun (9 Brigade) lo fa Ayomide Adeleye, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun le ileesẹ ọlọpaa lọwọ lọjọ karun un, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 yii.

Iwadii si ti n lọ lọwọ.”

Ọlọpaa gbe igbesẹ naa lori ẹsun ijinigbe ati iṣekupani Christiana, to jẹ akẹkọọ fasiti ẹkọṣe agbẹ, to wa niluu Abeokuta, FUNAAB, ti wọn fi kan Ayomide naa.

Iroyin ni afurasi ọhun kọkọ ji oloogbe naa gbe, o gba owo itusilẹ lọwọ awọn obi rẹ, ko to gbẹmi rẹ.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ

Inu oṣu Kẹjọ ni iroyin gbode pe wọn n wa Christiana, ti gbogbo igbiyanju lati ṣawari rẹ si ja si pabo.

Agbegbe UNILAG ni ọmọdebinrin naa n lọ lati Itaoluwa, to si gba agbegbe Yaba ko to di awati.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara,ni o bẹrẹ si ni lojutu.

Awọn ọmọ ẹgbẹ akẹkọkọ nile ẹkọ rẹ, SUG, sọ ninu atẹjade kan pe, awọn to ji ọmọ naa gbe ko gbe ipe awọn mọ, wọn si ke si awọn akẹgbẹ rẹ lati wọle adura.

Omidan kan to pe ara rẹ ni ibatan Christiana, lo kede lori ayejuajara pe oun gbọ pe o ti jade laye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Agbofinro lo nọmba ti awọn mọlẹbi Christiana san owo itusilẹ si lati tọpinpin ajinigbe naa, akara ba tu sepo

Awọn mọlẹbi oloogbe naa sọ fun BBC pe afurasi to ji ọmọ wọn gbe kan si awọn lati gba owo itusilẹ ti iye rẹ jẹ miliọnu mẹta naira, amọ wọn dunadura si N350,000.

A gbọ pe wọn san owo naa si apo afurasi amọ o kọ lati maa gbe ipe wọn lẹyin to gba owo ọhun tan.

Lẹyin naa ni awọn agbofinro lo nọmba ti awọn mọlẹbi Christiana san owo ọhun si lati tọpinpin rẹ.

Pẹlu nọmba BVN rẹ, wọn tọpinpin afurasi ọhun de ile awọn obi rẹ to wa lagbegbe Ikorodu, niluu Eko.

Nigba ti ọwọ ofin tẹ ẹ tan, wọn ba foonu rẹ lọwọ rẹ, wọn si ri ẹri pe oun gan lo gba owo itusilẹ Christiana.

Ọlọpaa ni afurasi naa ti jẹwọ pe lootọ ni oun ṣekupa Christiana, ti oun tun sin oku rẹ sinu ọgba ile wọn.

Ẹwẹ, iwadii fi han pe ọrẹ ni afurasi naa ati oloogbe, ile ijọsin kan naa ni wọn n lọ bẹẹ ni wọn n tẹle ara wọn lori ayelujara.