‘’Àṣìgbọ́ wà lórí wí pé akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ pé ọdún méjìdínlógún kó tó lè ṣe ìdánwò WAEC àti NECO’’

Examinatikon

Oríṣun àwòrán, @Radio Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita abẹle fun eto ẹkọ, Yussuf Sununu, ti sọ pe ijọba apapọ ko fi gbedeke ọjọ ori le awọn ọmọ to ba fẹ ṣe idanwo WAEC ati NECO.

Sununu lo sọ ọrọ naa nibi apero eto ẹkọ kan to waye niluu Abuja lọjọ Ẹti.

O fi kun ọrọ rẹ pe wọn tun le faye gba awọn akẹkọọ to jafafa to ba fẹ wọ ile ẹkọ giga ti ijọba apapọ.

Ṣaaju ni minister eto ẹkọ, Ọjọgbọn Tahir Mamman ti kọkọ sọ pe ọmọ ti ko ba tii pe ọdun mejidinlogun ko ni lanfani lati ṣe idanwo WAEC ati NECO mọ.

O ni ijọba apapọ ti paṣẹ fun WAEC ati NECO lati maṣe gba awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko tii to mejidinlogun lati ṣe idanwo naa mọ.

Ọrọ minisita naa bi ọpọ ọmọ Naijiria ninu, ti pupọ ninu wọn si n sọ pe ijọba ko fẹ ki awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko tii to mejidinlogun kawe ṣugbọn o le gba wọn laaye lati lọ sile ọkọ.

Amọ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Ẹti, Sununu sọ pe ṣe ni awọn ọmọ Naijiria ṣi minisita eto ẹkọ naa gbọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbedeke ọjọ ori awọn ti yoo wọ fasiti ni minisita ọhun n sọrọ nipa rẹ, eyii ti yoo bẹrẹ lọdun to n bọ.

Sununu ni “ko si ẹnikẹni ninu wa to mẹnuba gbedeke ọjọ ori ṣiṣe idanwo WAEC ati NECO.

“Awọn eeyan kan mọọmọ n sọ pe ohun ti a sọ niyẹn, ohun ti a sọrọ le lori ni gbedeke ọjọ ori awọn akẹkọọ to ba fẹ wọ fasiti.”

Wayi o, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko tẹwọ gba aba ijọba naa pe ọmọ ti ọjọ ori rẹ ko ba tii to mejidinlogun ko ni le wọ fasiti ni Naijiria.