Mi ò mọ Bobrisky rí, a ò pàdé rí, kódà a ò sọ̀rọ̀ rí – Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Richard Akinwumi/Bobrisky
Ajafẹtọ ọmọniyan to tun jẹ amofin agba, Femi Falana, SAN, ti sọ pe oun ko ni nnkankan ṣe pẹlu ọkunrin to n mura bii obinrin, Idris ‘Bobrisky’ Okuneye.
Falana lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels.
O ni oun ko mọ Bobrisky ri, wọn ko jọ sọrọ ri bẹẹ ni wọn ko ba ara wọn pade nibikibi ri.
Falana sọ pe “Bobrisky ko ba mi sọrọ ri, mi o ba pade ri, mi o mọ ọ ri lati ibi kankan bo tilẹ jẹ pe wọn ni o ba ọmọ mi Folarin sọrọ.
“Lootọ, ọmọ mi sọ pe o bẹbẹ fun iranlọwọ lati ọwọ awọn eeyan kan, o si pe ọmọ mi ni nnkan bii ọjọ kẹrin, oṣu Karun un, ọdun yii lati sọ pe jọwọ ṣe o le fun ni miliọnu mẹta naira ki wọn le fi mi si agbegbe VIP ninu ẹwọn.
“Ọmọ mi bere lọwọ rẹ pe, ṣe awọn ọga ẹlẹwọn mọ pe o n pe mi bayii? O ni rara – jọ ma pa mi mọ. Mi o ni le ṣe iranlọwọ fun ẹ lati fun awọn ọga ẹlẹwọn ni riba, ki o dẹ ṣọra gidi nitori o ti wa ninu ẹwọn fun ẹsun kan tẹlẹ.”
Falani ni Folarin sọ fun Bobrisky siwajusi pe “jọwọ ti o ba fẹ pe mi lọjọ mii, gba ọdọ awọn ọga ẹlẹwọn tabi ki o kọ lẹta ti ọga ẹlẹwọn yoo fọwọ si, igba ti wọn sọrọ kẹyin niyẹn.
“Ẹnikan wa lọ n fi fọran kan lede to si n ba orukọ mi jẹ pe ọkunrin naa ba mi sọrọ.”
“Eeyan to le ni 280 ni mo ti yọ lọgba ẹwọn”
Falana sọ siwaju si pe ko din ni eeyan 280 ti oun ti ṣeranwọ fun lati yi idajọ ti ile ẹjọ ṣe fun wọn pada, koda pupọ ninu awọn eeyan naa lo gba idajọ iku nilẹ okere.
O ni pẹlu gbogbo iranlọwọ ti oun ṣe fun awọn eeyan 280 naa lati gba ominira oun ko gba owo kankan lọwọ wọn.
Falana ni oun ti bere pe ki VDM tuba ko si tọrọ aforijin lọwọ oun ati ọmọ oun fun ibanilorukọjẹ, bi bẹẹ kọ, yoo foju bale ẹjọ.
Agbẹjọrọ agba naa sọ siwaju si pe oun yoo fi ọrọ VDM ṣe apẹrẹ fun awọn to ba fẹ maa ba orukẹ awọn ẹlomiran jẹ lori ayelujara.















