Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 3 Ọ́wàrà, 2024
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 3 Ọ́wàrà, 2024
Ajọ NYSC ti sọ pe oun ko mọ igba ti awọn agunbanirọ yoo bẹrẹ si n gba ₦77,000 owo oṣu tuntun
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan
Ṣaaju ni NYSC ti kọkọ kede pe ijọba ti ṣafikun owo oṣu agunbanirọ lati ₦33,000 ti wọn n gba tẹlẹ si ₦77,000
Amọ nigba ti owo oṣu wọn yoo wọle, 33,000 ni wọn ri dipo 77,000 ti wọn reti, ni wọn ba fariga
¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬
Bi a ṣe n wa ohun ti a o jẹ kiri, ki eledu ma jẹ ki a pade ohun ti yoo jẹ wa
Amin ẹ pọ, amọ ki lo ri?
Ọkuurin kan ti yinbọ pa obinrin meji to si fi oku wọn fun ẹlẹdẹ lati jẹ ni South Africa
Ikunlẹ abiyamọ o!
A gbọ pe ṣe ni awọn obinrin naa wa ounjẹ lọ sinu oko afurasi ọhun lagbegbe Limpopo, ko to ṣina ibọn fun wọn
Hmmmmmm
Fun ẹkunrẹrẹ iroyin naa....