ASUU tún fún ìjọba Nàìjíríà ní gbèdéke tuntun, àmọ́ kí làwọn ohun tí wọ́n fẹ́ lọ́tẹ̀ yí?

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Osodeke, Bola TinubuWia dis foto come from,Bola Tinubu twitter/ Emmanuel Osodeke/Facebook
Ajọ awọn olukọni ile ẹkọ giga fasiti, ASUU, ti kede pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi ti ijọba apapọ ba kọ lati dawọn lohun lori ohun tawọn n beere lẹyin ti gbedeke ọjọ mẹrinla t'awọn ṣẹṣẹ fun ijọba ba ti pe.
Ti ẹ o ba gbagbe, ni ogunjọ oṣu Kẹjọ to kọja ni ajọ ASUU fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ mọkanlelogun lati ṣe nnkan lori ohun ti wọn n beere fun.
Ṣugbọn wọn ni ijọba ko gbe igbesẹ kankan lori ọrọ naa ti ọjọ mọkanlelogun naa fi pe.
Nigba ti o n sọrọ nibi ipade ajọ naa to waye niluu Uyo, ipinlẹ Akwa Ibom, ọkan lara awọn adari ajọ ASUU, Ọjọgbọn Happiness Uduk, ṣalaye pe ko si àṣeyọrí kankan ti ajọ naa le tọka si lasiko gbedeke ọjọ mọkanlelogun tawon fun ijọba.
"Awọn ipade kan waye pẹlu awọn aṣoju ijọba ṣugbọn ko si eyi to so eso rere ninu wọn"
Ọjọgbọn Uduk ni lootọọ l'awọn ipade kan waye pẹlu awọn aṣoju ijọba ṣugbọn ko si eyi to so eso rere ninu wọn.
Ajọ ASUU ni lẹyin ti gbedeke ọjọ mẹrinla t'awọn ṣẹṣẹ fun ijọba ba tan ti ijọba ko ba ṣe nkankan, gbogbo ọmọ ẹgbẹ ajọ naa ni yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi lẹsẹ kẹsẹ.
Ajọ ASUU wa rọ awọn alẹnulọrọ lati ba ijọba sọrọ pe ki dawọn lohun lori ohun tawọn n beere fun.
ASUU sọ ninu atẹjade to fi sita lẹyin ipade rẹ wi pe "a kede afikun ọjọ mẹrinla gẹgẹ bi gbedeke fun ijọba lati dahun si ibeere wa lẹyìn ti gbedeke ọjọ mọkanlelogun ti a kọkọ fun ijọba ti tan ti ijọba ko si ṣe nkankan.
Ti ijọba ba kọ lati dawa lohun lẹyin gbedeke ọjọ mẹrinla yii, a ko fẹ ki ẹnikẹni bu wa ti a ba da iṣẹ silẹ.
A fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ijọba ni ko sootọ, ti ko si laanu rara."
Ajọ ASUU wa kepe awọn to wa ni ijọba lati wa nkan ṣe lori ọrọ naa ko maa ba di ohun tawọn n da'ṣẹ silẹ le lori.
ASUU ni ijọba lo lẹbi t'awọn ba fi le gunle iyanṣẹlodi leyin gbedeke ọjọ mẹrinla t'awọn ṣẹṣẹ fun ijọba.
Ohun ti ajọ ASUU n beere fun lọwọ ijọba ree
Lara ohun ti ajọ ASUU n beere fun idunadura lori adehun ọdun 2009 laarin ajọ ASUU ati ijọba apapọ.
Sisan owo oṣu ọmọ ẹgbẹ ASUU ti ijọba gbẹsẹ le nigba ti wọn gunle iyanṣẹlodi lọdun 2022.
Sisan owo oṣu awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU to gbaye lọ ṣiṣẹ olùkọ ni fasiti mii.
Sisan awọn owo ti ijọba yọ ninu owo oṣu awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU eyi to wa ninu eto isuna ọdun 2023.
Sisan awọn ajẹmọnu awọn olukọni ati titẹle ilana UTAS fun sisan owo oṣu awọn olukọni dipọ lilo Ilana IPPIS.
Ṣiṣe amojuto dida ile ẹkọ giga fasiti silẹ kaakiri lati pese owo fun iṣakoso awọn ile ẹkọ naa.
Titẹle awọn imọran igbimọ to ṣabẹwo s'awọn ile ẹkọ fasiti.
Ipese owo fun itaji awọn fasiti ijọba eyi to wa ninu eto iṣuna ọdun 2023.












