Ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn olọ́jọ́ mẹ́ta tako ìwakùsà lọ́nà àìtọ́ bẹ̀rẹ̀ ní Ghana

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní orílẹ̀ èdè Ghana ló ti yawọ ojú pópó fún ìwọ́ded ìfẹ̀hónúhàn tako bí wọ́n ṣe ń wakùsà lọ́nà àìtọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
Bákan náà ni àwọn olùwọ́de náà tún bèèrè pé kí ìjọba tú àwọn ọ̀dọ́ mẹ́tàléláàdọ́ta tó wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá àti ọgbà ẹ̀wọ̀n fẹ́sùn wí pé wọ́n kópa nínú ìwọ́de ìwàkùsà lọ́nà àìtọ́ tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kẹsàn-án.
Àwọn ọ̀dọ́ náà ní ìwàkùsà lọ́nà àìtọ́ ti ṣàkóbá fún àwọn omi àti igbó lórílẹ̀ èdè náà.
Ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà tí àwọn ikọ̀ kan tí wọ́n pe ara wọn ní ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìjọba àwaarawa “Democracy hub” ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ló yẹ kó wáyé fún ọjọ́ mẹ́ta.
Àmọ́ àwọn ọlọ́pàá fòfin gbé èèyàn mẹ́tàléláàdọ́ta ní ọjọ́ kejì tí ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀ fẹ́sùn wí pé wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tí kò bá òfin mu.
Àwọn olùwọ́de náà ní gbogbo nǹkan tí àwọn ń ṣe ló wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òfin.
Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n fi àwọn èèyàn náà sí àhámọ́ ọlọ́pàá àti ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ka ẹ̀sùn pé wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti hu ìwà ọ̀daràn, péjọ lọ́nà àìtọ́, bíbá dúkìá ìlú jẹ́, olè jíjà àti nína àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò.
Àwọn èèyàn náà ní àwọn kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn nílé ẹjọ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n ti ń tako ìjọba àti ọlọ́pàá láti ìgbà náà pé wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀.
Àjọ Amnesty International Ghana bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ọlọ́pàá, tí wọ́n sì ní kí wọ́n tu àwọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ ní kíákíá.

Oríṣun àwòrán, ECONOMIC FIGHTERS LEAGUE/FACEBOOK
Àjọ ajáfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn náà sọ pé àwọn kò faramọ́ àwọn ìwà ipá táwọn ọlọ́pàá ṣàmúlò sáwọn olùwọ́de náà pé ó jẹ́ àbùkù sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.
Ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn míì ló ti dá sọ̀rọ̀ náà tí wọ́n sì képe ìjọba láti tú àwọn olùwọ́de tó ti wà ní àhámọ́ sílẹ̀ láti ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kẹsàn-án.
Àwọn agbẹjọ́rò ń kọminú pé àwọn ọlọ́pàá kò máa fún àwọn èèyàn náà ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì máa gbàwọ́n láyè láti rí ẹbí wọn.
Ikọ̀ Democracy hub fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọn kò jẹ́ kí àwọn olùwọ́de tó wà ní àhámọ́ wọn ní àànfàní sí agbẹjọ́rò wọn.
Bákan náà ni wọ́n ní ọlọ́pàá kò gba méjì tí wọ́n ní ìpèníjà ìlera láti rí dókítà kí wọ́n le rí ìwòsàn tó pèye.
Aṣáájú ìwọ́de #StopGalamsey, Oliver Barker-Vormawor àti èèyàn kan, Fanny Otoo ṣe àárẹ̀, tí wọ́n sì dáwọn dúro sí ilé ìwòsàn.
Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìpè àwọn agbẹjọ́rò wọn pé kí ilé ẹjọ́ jẹ́ kí wọ́n lọ gba ìwòsàn níbòmíràn, ilé ẹja ní kí wọ́n fi wọ́n sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Kí ni ìjọba sọ nípa àwọn olùwọ́de tó wà ní àhámọ́?

Oríṣun àwòrán, KOJO AKOTO BOATENG
Ìjọba sọ pé nǹkan tó bójúmu ni àwọn ọlọ́pàá ń ṣe.
Agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè Ghana, Godfred Dame sọ níbi ìpàdé ọlọ́dọọdún àwọn adájọ́ pé kí àwọn ọlọ́pàá ṣe ìwádìí wọn kíákíá kó tó di ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹwàá tí ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ sí.
Dame ní kí àwọn ọlọ́pàá náà ṣe àkójọ àwọn ẹ̀rí wọn kó tó di ọjọ́ náà.
Ó ní àwọn olùpejọ́ ń gbèrò láti gbà kí ilé ẹjọ́ fún àwọn olùwọ́de náà ní ìdáǹdè.
Ó fi kun pé àwọn olùwọ́de náà sọ kọjá àwọn ọ̀rọ̀ tí òfin fàyè gbà wọ́n láti sọ lọ.
“Àwọn èèyàn kan ń gbèrò láti dá inú fu àyà fu sílẹ̀ ṣáájú ètò ìdìbò, wọ́n ń lo ìwọ́de láti fi ṣe ìkọlù sáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àti láti da omi àlááfíà ìlú rú.
Ó ní àwọn èèyàn tí wọ́n láyà láti ṣe ìkọlù sáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò gbọ́dọ̀ fojú winá òfin.
Àwọn èèyàn ti ń lo táàgì #FreeTheCitizens lóri ayélujára láti fúngun ma ọlọ́pàá láti tú àwọn èèyàn náà sílẹ̀.
Ní orí X, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń lo háṣìtáàgì náà, tí wọ́n sì ń sọ fún ìjọba láti fòfin de ìwàkùsà lọ́nà àìtọ́ àti pé kí wọ́n kéde ìlú kò fararọ.
Háṣìtáàgì yìí ló ṣokùnfà ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tuntun tí yóò wáyé ní olú ìlú orílẹ̀ ède Ghana, Accra láàárín ọjọ́ Kẹta sí ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kẹwàá.
Kí ni èròńgbà fún ìwọ́de tuntun ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí?
Bí àwọn olùwọ́de mẹ́tàléláàdọ́ta náà ṣe ṣì wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá, àwọn ọ̀dọ́ ní ọ̀rọ̀ náà ti tógẹ́.
Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn wọn tó bẹ̀rẹ̀ lórí X ní àwọn òpópónà báyìí.
Fún ọjọ́ mẹ́ta tí ìwọ́de ọ̀hún yóò fi wáyé, àwọn olùwọ́de náà yóò ṣe àgbékalẹ̀ ìwé ìfẹ̀hónúhàn wọn síwájú agbẹjọ́rò àgbà Ghana, ilé aṣòfin àti mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ àti ohun àlùmọ́nì.
Wọ́n ní ìwé tí àwọn kọ sí agbẹjọ́rò àgbà ni láti bèèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn tó wà ní àhámọ́.
Tí ilé aṣòfin ni bèèrè pé kí ilé ṣòfin tó máa gbégi dínà ìwàkùsà lọ́nà àìtọ́.
Wọ́n ní èyí tó wà mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ àti ohun àlùmọ́nì ni láti ri pé wọ́n gbé ìgbésẹ̀ tako wíwakùsà léti omi ìlú àti igbó.
Àwọn òlùwọ́de náà ló gbé omi tí kò mọ́ dání láti fi han ìjọba pé àwọn kẹ́míkà bíi mercury, lead, cyanide tó wà nínú omi náà le ṣàkóbá fárá ìlú.
Ghana ni orílẹ̀ èdè tó ń pèsè góòlù jùlọ ní Áfíríkà
Ghana gba ipò àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà tó ń pèsè góòlù mọ́ South Africa lọ́wọ́ lọ́dún 2023.
Ààrẹ Nana Akufo-Addo nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó bá aráàlú sọ nínú oṣù Kejì ọdún 2024 pé àwọn ètò tí ìjọba gbé kalẹ̀ ló jẹ́ kí wọ́n le pèsè góòlù tó tó mílíọ̀nù mẹ́rin ounces.
Ó fi kun pé mímú àdínkù bá owó orí táwọn tó ń wakùsà lábẹ́nú láti ìdá mẹ́ta (3%) di ìdá kan àbọ̀ (1.5%) ló jẹ́ kí iye wúrà tí àwọn ń tà jáde ní orílẹ̀ èdè náà ṣe ti lékún ní ìdá 900% láàárín ọdún méjì tí àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà.
Ajọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àlùmọ́nì ní Ghana ní owó tí àwọn ti pa lẹ́ka títa àwọn ohun àlùmọ́nì sílẹ̀ òkèrè ti lé bílíọ̀nù mẹ́sàn-án dọ́là tí góòlù nìkan sì kó ìdá mẹ́rìnléláàdọ́ta nínú rẹ̀.
Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ omi ní Ghana ní ọ̀pọ̀ àwọn odò tí àwọn ti máa ń pèsè omi fáráàlú ni ìwàkùsà ti ba omi ibẹ̀ jẹ́ àti pé owó ti àwọn ń lò láti mú kí àwọn omi náà ṣe é lò ló ti pọ̀ si.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àtàwọn àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ni wọ́n ti kéde ìyanṣẹ́lódì lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ìwakùsà lọ́nà àìtọ́ lòdì sí òfin Ghana tí èèyàn sì le lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá lórí rẹ̀
Àmọ́ àwọn kan wòye pé ìjọba kò fẹ́ ṣe àmúṣẹ òfin náà nítorí àwọn alágbára tó lọ́wọ́ nínú wíwakùsà lọ́nà àìtọ́.















