Wo bí o ṣe lè ṣe àtúnṣe káàdì ìdánimọ̀ NIN lórí fóònù rẹ láì lọ sí ọ́fíìsì àjọ NIMC

Oríṣun àwòrán, TECHECONIMY
Awọn ọmọ orilẹede Naijiria ko nilo lati lọ si ọfiisi ajọ NIMC to n ri si ọrọ kaadi idanimọ NIN mọ fun isọdọtun tabi atunse ti wọn ba fẹ ṣe lori Kaadi idanimọ wọn.
Ajọ NIMC ti kede pe oun ti ṣe ifilọlẹ ilana táwọn eeyan le maa tẹle lori foonu wọn lati ṣe ohun kohun ti wọn ba fẹ ṣe lori kaadi idanimọ wọn.
Ajọ NIMC kede loju opo X rẹ pe awọn araalu ko nilo lati lọ si ọfiisi awọn mọ fun ohun kohun ti wọn ba fẹ ṣe lori kaadi idanimọ wọn
Ajọ naa sọ pe ilana tuntun toun gbe kalẹ yii rọrun, ati pe yoo fáwọn eeyan lanfaani lati ṣe atunṣe lori kaadi idanimọ wọn nibi kibi ti wọn ba wa.
Ajọ NIMC ni ilana tuntun yii yoo fopin bi awọn eeyan ṣe maa n to siwaju ọfiisi awọn ni gbogbo igba ti wọn ba ti fẹ ṣe atunṣe kan tabi omiran lori kaadi idanimọ wọn.
Ajọ NIMC ni o le ni ọgọrun kan miliọnu ọmọ Naijiria to ti forukọ silẹ pẹlu awọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wo awọn nkan ti o le satunṣe rẹ fun ra rẹ lori kaadi idanimọ NIN rẹ
Awọn nkan ti o le satunṣe rẹ fun ra rẹ lori kaadi idanimọ rẹ gẹgẹ bi ajọ NIMC ṣe sọ ni orukọ ati ọjọ ibi rẹ ati adirẹsi ile rẹ.
Wo bi o ṣe le paarọ orukọ rẹ
Ki o too le paarọ orukọ rẹ, o ni lati pese iwe ẹri igbeyawo, tabi iwe ẹri ti o gba nile ẹjọ tabi kaadi idanimọ ijọba ti o ba ni.
Ọjọ ibi rẹ
Ki o to le ṣe atunṣe lori ọjọ ibi rẹ, o gbọdọ ni iwe ẹri nipa ojọ ibi ti o gba lati ọwọ ajọ NPC to n ri si eto ikaniyan, eleyii wa fawọn ti wọn ti bi ṣaaju ọdun 1992.
Fun awọn ti wọn bi i lẹyin ọdun 1992, wọn ni lati mu iwe ẹri ọjọ ibi wọn ti wọn gba lati ọwọ ajọ NPC wa.
Adirẹsi ile rẹ
Awọn ohun ti o nilo ni iwe ti o fi n sanwo ina mọnamọna, adehun rẹ ati onile ti o n gbe ati iwe ijẹri lati ọdọ olori awujọ to n gbe.
Nọmba foonu rẹ
O nilo ẹri lati ọdọ awọn ọlọpaa.
Awọn nkan ti o ko le ṣe atunṣe rẹ fun ra rẹ lori kaadi idanimọ NIN rẹ
Ipinlẹ abinibi rẹ.
Bo ya o ti ṣe igbeyawo tabi apọn si ni ọ.
Orukọ baba rẹ ti o n jẹ tẹlẹ.
Atunṣe lori fọto rẹ.
Wo bi o ṣe le ṣe isọdọtun lori aapu NIMC
Ajọ NIMC ti gb'awọn ọmọ Naijiria ti wọn fẹ ṣe isọdọtun data nipa ara wọn ni imọran lati bẹrẹ nipa ṣiṣẹ ayẹwo kaadi NIN wọn.
Eyi ni yoo fun wọn lanfaani lati wọ ori ikanni ajọ NIMC.
Lọ si ẹka ti awọn nkan ti o fẹ se atunṣe lori wọn wa.
Ranti lati maaki apoti ijẹri si.
Lẹyin naa ni ki o si fi atunṣe ti o ti ṣe ranṣẹ.















