Nígbà wo ni àwọn àgùnbánirọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń gba ₦77,000 owó oṣù tuntun?

Oríṣun àwòrán, NYSC
Ajọ agunbanirọ Naijiria, NYSC, ti ni oun ko le sọ igba ti awọn agunbanirọ yoo bẹrẹ si n gba ₦77,000 owo oṣu tutun ti ijọba ṣeleri fun wọn.
Ọkan lara awọn alẹnulọrọ ni NYSC amọ ti ko fẹ ki a darukọ oun lo sọ bẹẹ fun BBC ninu ifọrọwerọ kan.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, niwọn igba ti ijọba ti ṣeleri pe oun fi kun owo naa, o daju pe yoo fi kun owo oṣu ọhun amọ oun ko le sọ igba ti yoo bẹrẹ si n san owo naa ni pato.
Ọkunrin ọhun ṣalaye pe kii ṣe NYSC lo n san owo oṣu awọn agunbanirọ, ojuṣẹ ijọba ni, nitori naa ijọba yo bẹrẹ si n san owo ọhun ti akoko ba to.
O ni “NYSC kọ lo n san owo agunbanirọ, ijọba apapọ lo n san an.
“Ti ijọba ba sọ pe oun yoo bẹrẹ si n san owo oṣu tuntun fun awọn agunbanirọ, ijọba yoo ṣiṣe lori rẹ, yoo si bẹrẹ si n san owo ọhun.
“Mi o le sọ ni pato akoko ti ijọba yoo bẹrẹ si n san owo oṣu tuntun naa fun awọn agunbanirọ, mi o ni aṣẹ lati sọrọ lori rẹ rara.
“Ṣugbọn laipẹ laijina, NYSC yoo fi atẹjade sita lorin ọrọ owo oṣu tuntun naa.”
Ọkunrin naa ṣalaye pe lootọ ni ijọba kede afikunowo oṣu agunbanirọ amọ ko yẹ ki araalu lero pe oun ti yoo ya kankan ni.
O ni oniruru eto ni ijọba yoo ṣe ko to bẹrẹ si n san owo naa, nitori naa ki awọn agunbanirọ lọ ni suuru nitori ijọba ko ni yẹ ileri rẹ fun.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 yii ni NYSC kede pe ijọba ti ṣe afikun owo oṣu agunbanirọ lati ₦33,000 si ₦77,000.
Atẹjade naa sọ pe eredi igbesẹ ọhun ko ṣeyin afikun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ti jọba ṣe lẹnu aipẹ yii.
Gẹgẹ bii ohun ti NYSC sọ, ijọba yoo sun owo naa ṣeyin, to n tumọ si pe yoo san ele owo naa fun awọn agunbanirọ lati inu oṣu Keje ọdun 2024.
Iroyin naa mu inu ọpọ agunbanirọ dun pupọ ti wọn si n reti owo gọbọi ni ipari oṣu to kọja.
Amọ iyalẹnu nla lo jẹ fun wọn nigba ti owo oṣu wọn wọle, ₦33,00 ti ijọba n san tẹlẹ ni wọn ri dipo ₦77,000 ti wọn n reti, eyii to mu ki wọn maa woye ohun to ṣokunfa rẹ.














