Atiku fi ohùn ránṣẹ́ sí CBN lórí gbèndéke Jan 31 tí yóò kó owó àtijọ́ kúrò nílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @atiku
Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti ke si banki apapọ Naijria, CBN, lati ṣe afikun gbedeke ọjọ ti yoo ko owo naira atijọ kuro nilẹ.
Atiku lo parọwa bẹẹ ninu fidio kan to fi lede loju opo Twitter rẹ lọjọ Abamẹta.
Ninu fidio ọhun ni Atiku ti sọ pe ko rọrun fun awọn araalu lati tete lọ paarọ awọn owo atijọ to wa lọwọ wọn si tuntun lasiko pgbedeke erete ti ijọba kede.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ko si ohun to buru ninu ki ijọba tẹ owo tuntun, amọ ọpọ araalu lo ti wa ninu hilahilo bayii latari bi wọn yoo ṣe paarọ owo naa.
O ni “Ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa awọn agbẹ, oniṣẹ ọwọ atawọn eeyan to wa ni igberiko, ti wọn ko ni apo ile ifowopamọ ni yoo ṣoro fun lati ni owo tuntun ni bayii ti wọn ko ni maa gba owo atijọ mọ.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
“Idi ree ti mo ṣe ke pe CBN lati sun gbedeke ti wọn kede ṣaaju nitori awọn ti yoo nira fun lati tete ri owo tuntun.”
Atiku sọ siwaju si pe oun mọ pe kii ṣe pe ijọba fẹ mọọmọ ni awọn araalu lara lo ṣe tẹ owo tuntun naa.
O fi kun pe ki ijọba tubọ maa ṣe ilanilọyẹ fun awọn araalu amọ wọn gbọdọ gbiyanju lati sun gbedeke ti wọn kede siwwaju.
Ẹwẹ, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n tiraka lati lọ paarọ owo atijọ ọwọ wọn si owo tuntun bayii.
Bẹẹ naa ni CBN ti pasẹ fun awọn banki lati ṣilẹkun wọn lọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku ki awọn eeyan le lanfani lati lọ paarọ owo ọwọ wọn.
Wayi o, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n kọ wo atijọ naa bayii.
Bẹẹ si ni awọn ile ifowopamọ kun fọfọ fun awọn to n fẹ lati paarọ owo ọwọ wọn.












