Ìjoͅba dóòlà èͅmí obìnrin 66 tí wọn jí gbé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awon eso alaabo lorileede Burkina Faso ti doola emi awon obinrin merindinlaadorin woͅn jigbe loͅ lorileͅede naa.
Ileesͅeͅ iroyin lorileͅede naa kede pe agbegbe ariwa orileͅede Burkina faso ti woͅn ti ji awoͅn obinrin naa gbe.
Awoͅn eͅsͅoͅ alaabo ni woͅn ri awoͅn obinrin ati oͅmoͅ naa ninu oͅkoͅ akero ni iwoͅn kilomita igba si ibi ti woͅn ti ji woͅn gbe.
Iru ijinigbe oͅloͅgoͅoͅroͅ yii ko sͅeͅleͅ lorileeͅde naa lati igba ti awoͅn ajinigbe ti n sͅoͅsͅeͅ ni agbegbe naa.
Amoͅ ko I tii han si eͅnikeͅni boya woͅn ri awoͅn ajinigbe naa mu abi beͅeͅ koͅ.
Oͅjoͅ Kejila ati Ikeͅtala, Osu Kini, oͅdun 2023 ni woͅn ji awoͅn oͅmoͅ ati awoͅn obinrin naa gbe ni Arbinda.
Ori teͅlifisoͅn ni woͅn ti fi aworan awoͅn oͅmoͅde ati obinrin han nibi ti woͅn ti n woͅ oͅkoͅ igbooro ni papakoͅ ofurufu nibi ti eͅsͅoͅ alaabo ti n ba woͅn soͅroͅ.
Ijoͅba Burkina Faso ni awoͅn ti woͅn doola eͅmi woͅn naa wani olu ilu naa nibi ti woͅn ti n fi oͅroͅ wa woͅn leͅnu woͅ
Oͅjoͅ Kejila ati Ikeͅtala, Osu Kini ni woͅn ji awoͅn oͅmoͅ ati awoͅn obinrin naa gbe ni agbegbe Arbinda.
Awoͅn agbesunmoͅmi woͅnyii di oju titi, ti woͅn ko si gba ki awoͅn jade tabi woͅle si agbegbe naa, nitori naa iya ati isͅeͅ n han awoͅn eniyan ni eemoͅ ni agbegbe naa.
O ti le ni oͅdun meͅwaa ti awoͅn agbesunmoͅmi ti n sͅoͅsͅeͅ ni orileͅede naa, ti awoͅn eniyan to le ni milioͅnu meji si ti di alainile lori.
Odun to koͅja ni awoͅn Ologun gba ijoͅba, ti woͅn si sͅeleri lati fopin si igbesunmoͅmi ni orileͅede oͅhun.
Amoͅ awoͅn Ologun miran tun fi ipa gba ijoͅba ni Osu keͅsan an, oͅdun to koͅja, amoͅ ko I tii si oͅna abayoͅ.















