Ó wù mí láti bímọ oyè fún Ooni, ẹ̀yin alálẹ̀, ẹ fún mi ní ìbejì - Ashley Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Queen Ashley Afolashade Ogunwusi/Instagram
Yoruba ni ẹnu ẹni la fi n pe Temidire, ohun ta ba si fi ẹnu wa sọ si ara wa, o di dandan ko ri bẹẹ.
Eyi lo mu ki Olori Ashley Afolashade Ogunwusi, tii se ọkan lara awọn iyawo Ooni ti ilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, se n bẹ awọn alalẹ lọwẹ pe ki wọn fun oun ni ibeji ti yoo jẹ ọmọ oye.
O ni nitori pe o wu oun lati bi ibeji ni aafin Ọba Adeyeye Ogunwusi.
Olori Ogunwusi rawọ ẹbẹ yii ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan, eyi to tẹ BBC Yoruba lọwọ.
Ninu fidio naa ni Olori Ashley ti n ba ipejọpọ awọn agbaagba kan lọkunrin ati lobinrin sọrọ, to si n se adura kikankikan.
Olori naa, to wọ asọ ibilẹ to jẹ funfun pẹlu ọja saki si ejika rẹ, lo joko sori aga kan ni gbagede igbalejo Ooni, to wa ninu aafin Ile Ife.
Bi Olori Ashley si se n se adura naa, lawọn abẹsẹ, alejo ati iransẹ ninu aafin naa n se asẹ Edumare.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Olori Ashley Ka ọmọ marun fun Ooni Ogunwusi lasiko to n se adura
Ninu fidio ọhun, lasiko to n gbadura naa, ni orogun rẹ, Ronke Ademiluyi ti joko sẹgbẹ , to si n gbadura fun ọkọ wọn.
Olori Ashyley ni Ooni Ogunwusi, tii se Arole Oodua ni baba Adeola, Baba Adewamiwa, baba Fadesola, baba Tadenikawo ati baba Adeife.
"Mo dupẹ lọwọ baba, ti mo ba ni ki n maa ki wọn lọ, a ni kuro nibi yii nitori wọn to bẹẹ, wọn si ju bẹẹ lọ.
Mo wa gbadura pe mimi kankan ko ni mi i mọ lode aye, yoo gbo, yoo tọ, ti yoo si fi erigi jobi.
Gbogbo olori ni yoo dijọ maa ko ọmọ lubọ laafin, a finu soyun, a fi ẹyin gbe ọmọ pọn."
“Mo n sọrọ ara mi ni o, ma a bi ibeji ni aafin Ọba, maa bi ọmọ oye"
Lasiko adura naa si ni Olori Ashley ti sisọ loju rẹ pe o wu oun pe ki oun bimọ oye ninu aafin Adimula.
"Ọmọ oye, ma a bi, maa finu soyun, maa fẹyin gbọmọ pọn.
“Mo n sọrọ ara mi ni o, ma a bi ibeji ni aafin Ọba, maa bi ọmọ oye.
Ati emi atawọn to ku mi naa, a dijọ ko ọmọ lubọ lati finu se oyun lasẹ Olodumare."
Bakan naa lo wa gbadura pe ki gbogbo awọn Olori ba Ooni gbo, ki wọn ba wọn pẹ, ki asẹ si pẹ lẹnu ọkọ awọn.
O ni wọn ko ni gbọ iku aya atabi ọmọ lori itẹ, ti aafin yoo si toro kalẹ.
Olori naa wa tun dupẹ lọwọ ọkọ pupọ fun isẹ ribiribi to n ṣe fun awọn ati ilẹ Yoruba lapapọ.

Oríṣun àwòrán, Queen Asyley Afolashade Ogunwusi/Instagram
Ta ni Ashley Ogunwusi?
Ọmọ bibi ilu Ile Ife ni Ashley Afolashade Ogunwusi naa gẹgẹ bii Ooni, to si mọ ile daadaa ati itan aṣa ilu Ife.
Ọmọ ọba ni Olori Ogunwusi yii nitori idile ọba kan nile ife ni wn ti bii.
Ashley ni iyawo kẹrin ti Oba Adeyeye Ogunwusi fẹ. Ọdun to kọja ni Ọba kede Ashely gẹgẹ bi iyawo kẹrin.
Akọṣẹmọṣẹ ninu imọ iṣiro owo ni Olori Ashley.
O si kẹkọ gboye imọ ijinlẹ keji ninu imọ ẹkọ Iṣiro owo ati eto isuna ni fasiti Greenwich, to si tun ni okoowo to n ṣe ni ilẹ UK.
O ni ileeṣẹ ti ara rẹ to jẹ adari fun. Bakan naa lo ni ajọ kan ti kii se tijọba, to fi n tọju awọn ọmọde ti ko rọwọ họri ati opó.
















