Ìgbà èwe mi kò dẹrùn, òbí mi kò lówó láti fa iná ọba sílé, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún là ń jẹran adìyẹ -Muyiwa Ademola

Oríṣun àwòrán, aunthenticmuy/instagram
Gbajugbaja osere tiata Muyiwa Ademola, ti n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun irinajo rẹ lati igba ibi titi di akọkọ yii, bo se n se ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
Muyiwa Ademola loju opo ayelujara instagram rẹ lo ti fi idunnu rẹ han bẹẹ, to si ṣalaye bi ibẹrẹ ọjọ aye rẹ se ri ati bo ṣe jẹ ọmọ atapata dide.
Oṣere naa ni Oja'ba nilu Ibadan ni oun dagba si, ti idile oun ko si ni anfani lati fa ina manamana sile titi ti oun fi fẹ pari iwe girama.
O ni ounjẹ owurọ ati alẹ nikan ni agbara awọn obi oun ka, ti awọn si ma n rin lati ọjà ọba lọ sì Labo/Ọranyan, lati pọn omi ẹrọ fun mimu.
N ko ṣe ajọyọ ọjọ ibi ri afigba ti mo pe ọdun marunlelogun.
Muyiwa ni oun ko ṣe ajọyọ ọjọ ibi oun ri afigba ti oun pe ẹni ọdun marunlelogun.
O ni oore ọfẹ ẹran adiẹ ko si fun awọn nigba ti oun wa ni ewe, ayafi ọjọ keresimesi.
Ninu ọrọ idupe rẹ, Muyiwa Ademola wa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun iranlọwọ ati itọju rẹ lori oun lati ọpọ ọdun sẹyin.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post











