N kò fẹ́ fẹ́ ìyàwó, ni mo ṣe sá lọ sójú ogun - Buhari
Ìfẹ́ Ọlórun ni mo fi wà láyé tití di òní, ojú ti rí – Buhari

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni didari orilẹede Naijiria kii ṣe agbara eniyan kankan, edua nikan lo le ṣe.
Aarẹ Buhari sọ eyi ni Daura lasiko to ṣe abẹwo si Emir ilu Daura, Faruk Faruk to gba alejo rẹ.
Buhari ni Ọlọrun lo pa oun mọ titi di ọjọ oni paapaa lasiko ogun abẹle to bẹ silẹ ni ọdun 1967 si ọdun 1970, ti oun si jẹ ọkan lara awọn ọmọ ogun Naijiria nigba naa lọhun.
Ore ofẹ ni mo ri gba lọwọ Ẹlẹda lati tukọ orilẹede Naijiria - Buhari
‘’Fun aarẹ orilẹede Naijiria lati wa lati Daura kii ṣe mimọṣe ẹnikẹni kọ, ore ofẹ larigba.’’
‘’Ọgbọn osu ni mo fi wa ni oju ogun, ti ọpọ si n ṣubu ni ọtun ati osi’’
‘’Ẹlẹda lo komi yọ ninu ewu gbogbo, ọpọlọpọ ogun ni mo ja ti mo ri bori’’
‘’Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eniyan lo wa lorilẹede Naijiria, nitori naa aṣeyọri to lamilaaka ni ki aarẹ wa lati ilu Daura.’’
‘’Nitori mi o fẹ fẹ iyawo ni mo ṣe salọ si oju ogun’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Aarẹ Buhari nigba to n ba Emir Daura sọrọ salaye oun ti oju rẹ ri ni oju ogun Biafra nigba naa lọhun.
Buhari ni iṣẹ akọkọ ti oun kọkọ ṣe lẹyin ti o pariu ileẹkọ ni ṣiṣe akoso ileeṣẹ atojutofo ni ilu Daura.
Amọ Buhari ni oun sakuro nibẹ lati lọ darapọ mọ ikọ ọmọogun Naijiria nitori awọn mọlẹbi to n kan an nipa fun ohun lati lọ ṣe igbeyawo.
‘’Mo sọ fun gomina Aminu Masari idi ti mo fi kuro ni Daura nigba naa lọ darapọ mọ ikọ ọmọogun Naijiria.’’
‘’Igbagbọ mi ni pe Ọlọrun lo kọọ bẹ fun mi lati rin irinajo mi bẹẹ nitori akọsilẹ ti duro fun mi.’’
‘’Mo wa ni oju ogun, ti mo ri ọpọlọpọ ku lẹgbẹ mi ọtun ati osi, amọ Edua damisi di oni.’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Bakan naa ni aarẹ dupẹ lọwọ Emir naa fun aduroti rẹ ni igba gbọgbọ ati awn oye ati ipo ọla to fun awọn mọlẹbi rẹ ati awọn alabaṣiṣẹ rẹ.
Ninu ọrọ tirẹ, Emir Faruk dupẹ lọwọ aarẹ fun awọn iṣẹ akanṣe to ṣi ni ilu Daura, to si fikun un pe ọpọlọpọ ohun meremere ni ilu naa ti jẹ anfaani rẹ nitori ipo aarẹ ti Buhari di mu ni Naijiria.
O fikun un pe aanu ọlọrun daju lori aarẹ naa, nitori ọdun 2014 ni Ọlọrun ko yọ kuro ninu ikọlu awọn agbesunmọmi to si da ẹmi rẹ si titi di asiko yii.












