Ààbò 2023 dára ju ti 2015 ta dìbò kẹ́yìn lọ, mìmì kan kò ní mi ìbò tó ń bọ̀ - Buratai

Tukur Buratai

Oríṣun àwòrán, KabiruAbdulahi/facebook

Ọga agba awọn ọmọ ogun ile Naijiria nigbakan ri, Lieutenant General Tukur Yusuf Burutai, ti fi ọkan awọn ọmọ orilẹ-ede yii balẹ nipa eto idibo Naijiria ti yoo bẹrẹ losu keji ọdun yii.

Buratai, to jẹ ọkan lara ​​awọn igbimọ ipolongo Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu tẹgbẹ APC fẹwẹ gbaya bẹẹ lakoko to n ṣabẹwo si ileeṣẹ ́ BBC.

O ni ọpọlọpọ awọn to n halẹ pe eto idibo ọdun yii ko ni seese, kan n fẹnu sọ lasan ni.

Buratai ni, "Ni temi, enu lasan ni won fi n hale , nitori awọn ọmọ ologun Naijiria, awọn ọlọpaa ati awọn agbofinro miiran ti pinnu lati koju ẹnikẹni ti yoo da wahala silẹ lasiko idibo."

"Ikọ ologun atawọn ẹsọ alaabo ti ṣe ọpọ iṣẹ lati pese aabo lakoko idibo"

O ni ọpọlọpọ lo n bẹru boya eto idibo ọdun yii yoo waye, ati pe awọn iṣoro kọọkan le wa lakoko idibo ti n bọ.

Burutai ni awọn ikọ ologun ati awọn ẹso alaabo ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ lati ri wi pe aabo wa lakoko eto idibo naa.

O ni eto aabo nigba idibo ọdun 2019 ko dabi ti isinsinyi nitori idaniloju aabo ti wa ni Orilẹ-ede yii bayi.

Ọgagun tẹleri naa sọ pe "ijọba apapọ gbọdọ jade lati fi ọkan awọn ara ilu bale ki wọn si fi ẹri idaniloju han pe awọn igbese to yẹ ni wọn yoo ṣe lati rii pe aabo wa lakoko idibo,".