Àwọn kókó mẹ́rin tó wà nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí Harris ṣe pẹ̀lú NBS

Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Kamala Harris ni òun àti ikọ̀ òun ti gbáradì láti kojú alátakò rẹ̀, Donald Trump tí ó bá fi lè kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà láì ṣe wí pé wọ́n ti ka ìbò tán.

Lásìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí Harris ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn NBC News ló sọ̀rọ̀ yìí.

Ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni wọ́n ṣe àfihàn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ọ̀hún tó wáyé láàárín Kamala Harris àti Hallie Jackson ní US Naval Observatory.

Harris, tó ń díje sípò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat sọ̀rọ̀ nípa ìtàkurọ̀sọ tó wáyé láàárín Trump àti Ààrẹ Joe Biden, kó tó ní òun kò díje mọ́.

Lára àwọn kókó tí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà dálé nìyí:

Ìtàkurọ̀sọ Joe Biden àti Donald Trump

Nígbà tí Jackson bèèrè lọ́wọ́ Harris pé ṣé ó ṣe òótọ́ pẹ̀lú Joe Biden pẹ̀lú bí ó ṣe jàn án ní òǹtẹ̀ láti wá ipò Ààrẹ fún sáà kejì, Harris ní ìtàkurọ̀sọ náà kìí ṣe ohun tó dára rárá àti pé kìí ṣe ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí pé kí ìtàkurọ̀sọ má lọ bí èèyàn ṣe fẹ́.

Jackson tẹ̀síwájú láti bèèrè pé ṣé ìdí tí wọ́n fi yan Harris ni pé ìtàkurọ̀sọ náà kò lọ bó ṣe yẹ, Harris fún lésì pé ó máa nílò láti bèèrè lọ́wọ́ Biden fúnra rẹ̀ ìdí tí kò ṣe díje mọ́.

Harris ní òun ń dupò Ààrẹ Amẹ́ríkà pẹ̀lú èròńgbà láti mú àwọn àyípadà ọ̀tun pàápàá lẹ́ka yíyan àwọn adarí sípò.

Bákan náà ló ń fọwọ́ sọ̀yà nípa àwọn nǹkan tí Biden ti gbéṣe lásìkò rẹ̀.

Èrò Harris tí Trump bá kéde ara rẹ̀ bí i ẹni tó jáwé olúborí

Jackson tún bèèrè lọ́wọ́ Harris pé kí ni ó máa ṣe tí olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Republican bá kéde ara rẹ̀ bíi Ààrẹ láì ṣe wí pé ìbò kíkà tí parí.

Harris ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ni àwọn máa yanjú ìgbésẹ̀ náà bí ó bá ṣe ń wá àti pé àwọn máa gba àwọn onímọ̀ àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ní ọdún 2020, ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí ìbò wáyé ní Trump kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí àwọn ìlú dìbò fún lásìkò tí ìbò kíkà ṣì ń wáyé.

Ó ṣì ń kojú ìgbẹ́jọ́ pé ó fúngun mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìdìbò láti mú àyípadà bá èsì ìbò 2020 àti pé ó parọ́ pé èrú wà nínú ìbò náà.

Harris ní òun máa gbé irú ìgbésẹ̀ tí Joe Biden láti fojú rẹ̀ winá òfin nítorí ó gbìyànjú láti dojú ètò ìdìbò tó lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ rú.

“Èèyàn tó ń pè fún ìkọlù sí United States Capitol ni à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ọ̀rọ̀ ńlá ni èyí.”

Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣé Harris yóò bojú àánú wo Trump?

Lórí ìbéèrè pé ṣé yóò bojú àánú wo Trump, Harris ní bí òun yóò ṣe di Ààrẹ tó ń bọ̀ ni nǹkan tí òun fi ọpọlọ òun rò báyìí.

“Ọjọ́ mẹ́rìnlá tó ń bọ̀ ni àfojúsùn mi.”

Ó ní òun gbàgbọ́ pé tí òun bá di Ààrẹ Amẹ́ríkà ni ìtẹ̀síwájú yóò wà.

Ṣé Amẹ́ríkà ti ṣetán láti yan obìnrin gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ?

Harris ní òun ní ìgbàgbọ́ pé òun tó ṣe pàtàkì jùlọ lásìkò ìbò yìí ni pé àwọn èèyàn ti ṣetán láti ṣí ojú ìwé tuntun, láti pa ìròyìn pé Amẹ́ríkà pín.

Tí wọ́n bá dìbò yàn án, Harris ní yóò jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ Ààrẹ Amẹ́ríkà.

“Lóòótọ́ obìnrin ni mí àmọ́ nǹkan tí àwọn èèyàn fẹ́ mọ̀ ni pé ṣé o ní ìkápá láti ṣe iṣẹ́ yìí àti pé ṣé àwọn ètò wà láti mú ìpolongo rẹ wá sí ìmúṣẹ.”

Ó ní òun kò rí yíyan òun bíi olùdíje gẹ́gẹ́ bí ohun tó ní ṣe pẹ̀lú bóyá òun jẹ́ obìnrin tàbí ọkùnrin, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí àwọn ènìyàn gbọ́ nǹkan tí òun ní fún wọn lásìkò ìpolongo àti kí òun le gbọ́ nǹkan táwọn ará ìlú náà ń fẹ́.

“Mi ò fẹ́ rò ó pé àwọn kan ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà máa dìbò nítorí pé èèyàn kan jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin.”