Ṣé lóòótọ́ ni pé Aunty Ramota kò ní ilé lórí mọ́?

Aworan Aunty Ramota

Oríṣun àwòrán, IG/Aunty Ramota

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fọnran kan to jade loju opo ayelujara Instagram lo ti ṣafihan bi gbajumọ oṣere tiata, Ramota Adetu, ti ọpọ mọ si Aunty Ramota ṣe n tọrọ iranlọwọ lati ọwọ ọmọ Naijiria pe oun ko ni ile lori mọ.

Ninu fọnran to wa ju opo Agiye Amira lori Instagram ni Aunty Ramota ti sọrọ sita, to fẹsun kan ẹni ti oun ṣe alamojuto rẹ pe o lu oun ni jibiti owo.

Bakan naa, Aunty Ramota ni awọn to n ṣe akoso oun ti ji bẹgidina Tiktok oun.

O ni “Bi mo ṣe wa yii, n ko ni ile mọ. Obinrin ti mo n gbe pẹlu, ṣe igbeyawo loṣu to kọja, to si ni ki n kuro ni ile ounnitori ọkọ oun ko fẹ ki n duro.

“Mo ṣisẹ karakara ṣugbọn wọn n ji mi lowo nitori n ko mọ iye owo ti mo n pa wọle.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Ki ni mọlẹbi Aunty Ramota sọ?

Nigba ti BBC Yoruba kan si Ganiyu Kehinde, ẹni ti ọpọ mọ si Ijọba Lande lati ṣalaye ohun to sẹlẹ si Aunty Ramota.

O sọ fun BBC pe ko si nnkan to jọ mọ pe Aunty Ramota ko ni ile lori mọ ṣugbọn o jẹ ko di mimọ pe ootọ ni pe awọn to n ṣe alamojuto rẹ kọ lati fun ni owo.

Ijọba lande sọ fun wa pe “Nigba ti arabinrin to ṣe amojuto Aunty Ramota ṣe igbeyawo, o ni ki wọn wa mu aunty Ramota, ti o si wa ni ọdọ Aunty rẹ bayii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Nnkan to sẹlẹ ni pe awọn to n ṣe alamojuto rẹ n gba owo iṣẹ ti Ramota n ṣe.

“Lootọ ni pe ibi ti Ramota wa tẹlẹ, ẹni yẹn ni ki wọn wa mu Ramota kuro ni ibẹ, to si jẹ pe ọdọ awọn mọlẹbi rẹ lo wa.

“Nigba ti mo gbọ nipa rẹ, inu mi ko dun si, mo mọ bi Ramota ṣe n sisẹ to, mo si mọ iye owo to n pa wọle.

“Pẹlu bi o ṣe n sisẹ nitori o yẹ ki wọn le gba ile oni yara meji fun un Ramota, ko pọju, ti ko ba ti pari ile rẹ.

“Wọn ko fun Ramota lowo rara.

“Ti mo ba bi Ramota pe ṣe o fẹ kuro lọdọ awọn mọlẹbi rẹ, o maa ni rara ṣugbọn a ti n ṣisẹ lori ile rẹ.

“Otitọ ni pe wọn tun yọ opo ayelujara rẹ, Tiktok.”

Sussie Ratty, ẹni to ni a le pe oun ni mọlẹbi Aunty Ramota ni Ramota ko bere owo lọwọ ẹnikẹni ṣugbọn otitọ ni pe wọn lu ni jibiti owo.

O ni alaafia ni Aunty Ramota wa, to n si n gbe pẹlu ayọ pẹlu mọlẹbi rẹ

”Ko si nnkan to jọ mọ pe Aunty Ramota ko ni ile lori. O n gbe pẹlu alaafia ati idunu pẹlu ẹgbọn rẹ,

“Ṣugbọn o ṣe ni laanu pe wọn ṣe owo rẹ mọkumọku.”

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2