Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní Niger, Hamma Amadou jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Niger, Hamma Amadou ti jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin.
Iléeṣẹ́ ìròyìn Niger kéde pé Hamma, ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ sbẹnugan ilé aṣòfin, jáde láyé lẹ́yìn tó ń gba ìwòsàn ní ilé ìwòsàn kan ní Yamai lálẹ́ Ọjọ́rú.
Bákan náà ló tún ti fìgbà kan jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Modern FA Lumana.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò ni Hamma Amadou ti dìmú ní orílẹ̀ èdè Niger. Ẹ̀ẹmèjì ló di ipò Olóòtú ìjọba mú láàárín ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejì ọdún 1995 sí ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kìíní ọdún 1996 lábẹ́ ìṣèjọba Mahamane Ousmane.
Ìgbà kejì ni ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1999 sí ọjọ́ Keje, oṣù Kẹfà ọdún 2007 lábẹ́ ìṣèjọba Mamadou Tandja.
Ní ọdún 2011 ni wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí abẹnugan ilé aṣòfin, tó sì wà nípò di ọdún 2013.
Ẹ̀wẹ̀, lọ́dún 2014, Hamma Amadou sá kúrò ní Niger lọ sí France láti má kojú ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn kíkó àwọn ènìyàn lọ ṣọfà tí wọ́n fi kàn án.
Àmọ́ síbẹ̀ ilé ẹjọ́ sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan pẹ̀lú bí kò ṣe sí níbẹ̀.
Ó padà sí Niger lọ́dún 2019 lẹ́yìn tó lo ọdún márùn-ún ní France.
Ta ni Hamma Amadou?

Ní ọdún 1950 ni wọ́n bí Hamma Amadou ní ìlú Youri.
Ó di ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò mú ní orílẹ̀ èdè Niger láàárín ọdún 1972 sí 1988 nígbà tó fi Mínísítà fétò ìròyìn.
Níbi ètò àpérò ọdún 1991, Hamma Amadou dìde láti dá ààbò bo ẹgbẹ́ òṣèlú MNSD-Nasara tó lọ ṣojú èyí tó sọ ọ́ di akọ̀wé ẹgbẹ́ lọ́dún 1991.
Hamma Amadou di Olóòtú ìjọba Niger ní Ẹ̀ẹmèjì láàárín ọdún 1995 sí 2007.
Ní ọdún 2008, àwọn aláṣẹ ti Amadou mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Koutoukale níbi tó ti lo oṣù mẹ́wàá lórí ẹ̀sùn gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
Nígbà tó yá ló fi ẹgbẹ́ òṣèlú MNSD-Nasara sílẹ̀ láti lọ dá ẹgbẹ́ òṣèlú Modern FA Lumana sílẹ̀.
Ẹ̀ẹmẹta ni wọ́n dìbò yàn án sí ilé aṣòfin.
Ní ọdún 2011, ó dupò Ààrẹ Niger tó sì gbé ipò kẹta. Ó ṣe àtìlẹyìn fún Mamahadou Issoufou ní sáà kejì.















