Polio: Ṣé àìsàn rọmọlápá-rọmọlẹ́sẹ̀ lè di ohun ìgbàgbé lágbàáyé bí?

Àwòrán ọmọ tí wọ́n ń kán abẹ́rẹ́ àjẹsára sí lẹ́nu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Abẹ́rẹ́ àjẹsára bílíọ̀nù mẹ́wàá ni wọ́n ti fún àwọn ọmọdé káàkiri àgbáyé láàárín ọdún mẹ́wàá
    • Author, Swaminathan Natarajan and Zarghuna Kargar
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ajo ètò ìlera àgbáyé ìyẹn World Health Organization, WHO, ní ìgboyà pé to bá máa fi di ìparí ọdún 2025, àwọn máa ti fi òpin ìtànkálẹ̀ àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún ṣàwárí kòkòrò tó ń ṣokùnfà àìsàn náà lọ́dún yìí.

Ní ọdún 1988 ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò láti fòpin sí Polio nígbà tí àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ tó lágbára gidi mú èèyàn 350,000 ní orílẹ̀ èdè 125.

Ní báyìí, orílẹ̀ èdè méjì: Pakistan àti Afghanistan ni irúfẹ́ polio tó lágbára yìí wà. Ní ọdún 2023, èèyàn mẹ́fà ni àìsàn náà mú ní orílẹ̀ èdè méjèèjì lápapọ̀ àmọ́ lọ́dún yìí, Afghanistan ti ní àkọ́ọ́lẹ̀ èèyàn 22, tí èèyàn 39 sì ní àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ ní Pakistan.

Ṣé àwọn ẹ̀yà polio tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fojú hàn yìí yóò jẹ́ kí àlá WHO láti fòpin sí àìsàn náà wá sí ìmúṣẹ bayìí?

Polio kọlu Jawad ti baba rẹ gbe dani
Àkọlé àwòrán, Baba Jawad, Jaleel Ahmad to gbe Jawad ko mọ iru ipenija ti yoo la kọja lọjọ iwaju

Àwọn ọmọdé tó ń ní àìsàn polio

Ọmọ ọgbọ̀n oṣù láti ìlú Quetta ní orílẹ̀ èdè Pakistan ni Jawad. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ tí àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ ń dà láàmú. Nínú oṣù Kọkànlá ọdún tó kọjá ló bẹ̀rẹ̀ sí ní gbóná, tí àyà sì ń dùn ún.

“Nígbà tí ọmọ mi jí láàárọ̀, a ri pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kan kò ṣiṣẹ́, kò lè fi dúró, “ bàbá Jawad, Jaleel Ahmad ṣèrántí.

Ó ní àwọn dókítà jẹ́ kó yé àwọn pé ẹsẹ̀ rẹ̀ ti rọ.

“Nǹkan tó lágbára ni fún èmi àti ìyàwó mi. A gbe lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà mìíràn àmọ́ wọ́n sọ pé kò sí nǹkan tí àwọn lè ṣe.”

Kò sí oògùn fún polio àmọ́ ó ṣe é dènà pẹ̀lú abẹ́rẹ́ àjẹsára.

“Nígbà tí a bi, a ò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára kankan fun àmọ́ ó gba èyí tí wọ́n máa ń kán sí ẹnu lẹ́yìn tó pé oṣù mẹ́ta.

“Tí ó bá gbìyànjú láti rìn, ẹsẹ̀ rẹ̀ kò dúró dada, ó ti rọ.”

Níní ìgbàgbọ́ nínú àfojúsùn

Oṣiṣẹ eto ilera n fun ọmọ ni abẹrẹ ajẹsara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ko si oogun lati tọju polio amọ abẹrẹ ajẹsara le dena itankalẹ rẹ

Pẹ̀lú bí polio ṣe ń pọ̀ si, àjọ WHO ní àwọn kò bẹ̀rù rárá.

Adarí ẹ̀ka fífi òpin sí polio fún WHO ní ẹkùn ìlà oòrùn Mediterranean, Dókítà Hamid Jafari ní gbogbo ìgbà ni polio máa ń fojú hàn kí àwọn tó dènà rẹ̀ àti pé irúfé bẹ́ẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí.

Fífi òpin sí polio ní Afghanistan àti Pakistan nílò kí wọ́n máa fún àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì kọjá ọdún márùn-ún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára polio ní gbogbo ìgbà.

Jafari ṣàlàyé àwọn tó máa ń fún àwọn ọmọdé náà ní abẹ́rẹ́ àjẹsára ni wọ́n máa ń ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn agbègbè tí wọ́n kò bá ti fún ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.

Àwọn tó máa ń pín abẹ́rẹ́ àjẹsára náà máa ń fi ọ̀kadà lọ láti ìletò kan sí òmíràn láti fún àwọn tó máa ń ṣe ìrìnàjò kiri.

Ó wòye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ọmọdé tó ń ní àìsàn náà ń pọ̀ si, síbẹ̀ irúfẹ́ àìsàn náà tó wà lóde kò ju méjì lọ dípò méjìlá tó wà lọ́dún 2020.

Kí ni àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ àti pé báwo ló ṣe ń tàn?

Awọn ẹlẹhaa ni Afghanistan n fun ọmọ ni abẹrẹ ajẹsara ni Jalalabad lọdun 2023

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀, polio, jẹ́ èyí tí kòkòrò àìfojúrí, poliovirus máa ń fà. Ó máa ń tàn látara ìgbẹ́ ẹni tó bá ni tàbí tí itọ́ ẹni tó bá ni bá kan èèyàn llára.

Àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn kò bá ì tíì pé ọdún márùn-ún ló máa ń yọ lẹ́nu.

Àjọ WHO ní èèyàn kan nínú igba ọmọdé tí àìsàn náà bá mú ni ó ṣeéṣe kí ó má lè rìn mọ́ àti ìdá márùn-ún sí mẹ́wàá nínú wọn ló máa ń ṣekúpa nígbà tí wọ́n kò bá ríbi mí mọ́ dáadáa.

Gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára ti mú kí méjì nínú ẹ̀yà kòkòrò náà tó lágbára púpọ̀ di ohun ìgbàgbé àmọ́ ẹyọ̀kan ṣì ń jà.

WHO ní níwọ̀n ìgbà tí ọmọ kan bá ṣì ní àìsàn náà, gbogbo àwọn ọmọdé tó wà ní agbègbè náà ló wà nínú ewu.

Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ àìsàn ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, CDS ní ọ̀pọ̀ àwọn polio tí wọ́n ń rí lẹ́yìn abẹ́rẹ́ àjẹsára ló wáyé ní ilẹ̀ Áfíríkà.

Láàárín oṣù Kìíní ọdún 2023 sí oṣù Kẹfà ọdún 2024, CDS sọ pé èèyàn 672 ní orílẹ̀ èdè 39 ni àìsàn náà dà láàmú.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára

Gulnaz Shirazi n fi abẹrẹ ajẹsara si ọmọ lẹnu

Oríṣun àwòrán, Gulnaz Shirazi

Àkọlé àwòrán, Gulnaz Shirazi ṣi n tẹsiwaju pẹlu fifun awọn ọmọde ni abẹrẹ ajẹsara bi o tilẹ jẹ pe o ti padanu ẹbi rẹ meji lori iṣẹ naa

Ètò fífi òpin sí àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀, láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ti pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́wàá fáwọn ọmọdé tó súnmọ́ bílíọ̀nù mẹ́ta káàkiri àgbáyé.

Pakistan máa ń ṣètò abẹ́rẹ́ àjẹsára ní ojúlé sí ojúlé ní gbogbo ìgbà. Nínú oṣù Kẹsàn-án ni wọ́n parí ọ̀kan.

Lẹ́yìn ọdún márùn-ún, ètò fífún àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára láti ojúlé sí ojúlé wáyé ní Afghanistan nínú oṣù Kẹfà ọdún 2024 àmọ́ èyí tí wọ́n máa ń kán sí ẹnu tó yẹ kó wáyé nínú oṣù Kẹsàn-án ni ìjọba Taliban kò fi ààyè gbà.

Iléeṣẹ́ ètò ìlera tí ìjọba Taliban ń ṣe àkóso rẹ̀ kò fèsì sí ìbéèrè BBC láti mọ ìgbà tí ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára náà yóò tún wáyé lọ́jọ́ iwájú.

Híhu ìwà ipá sáwọn tó ń pín abẹ́rẹ́ àjẹsára

Amir Ali lori aga

Oríṣun àwòrán, Amir Ali

Àkọlé àwòrán, Amir Ali n lo iriri lati fi polongo fawọn iya lati maa gba abẹrẹ ajẹsara fawọn ọmọ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ìbẹ̀rù, ìfura àtàwọn ìròyìn òfégè mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn má fẹ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára ní orílẹ̀ èdè Pakistan àti Afghanistan.

Àjọ tó ń mójútó fífi òpin sí polio ní Pakistan sọ pé èèyàn méjìlélógún tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti pín abẹ́rẹ́ àjẹsára ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ọdún yìí nìkan.

Ní Afghanistan, ọdún 2004 ni ìkọlù sáwọn òṣìṣẹ́ polio tó lágbára jùlọ wáyé níbi tí èèyàn mẹ́jọ tí jáde láyé lọ́jọ́ kan ṣoṣo.

Ipa tí Gulnaz Shirazi àti Amir Ali kó lórí ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ló ṣì ń mú ètò náà tẹ̀síwájú di òní.

Ní ọdún 2011 ni Shirazi bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ bíi òṣìṣẹ́ fún polio ní Muzaffrabad. Àwọn ẹbí rẹ̀ mẹ́rin míì ló ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ náà àmọ́ wọ́n pa méjì nínú wọn.

Shirazi ní òun kò mọ ìdí tí wọ́n fi máa ń ṣe ìkọlù sáwọn òṣìṣẹ́ polio àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn, òun ṣì fẹ́ máa ṣiṣẹ́ láti fòpin sí polio.

Amir Ali tí àìsàn polio mú kí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan rọ láti ìgbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rin ti wà ní Karachi báyìí níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń fún àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára.

Ó ní iṣẹ́ abẹ mẹ́jọ ni òun ṣe nígbà tí òun ń dàgbà láti ṣe àtúnṣe ẹsẹ̀ òun àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.

Amir Ali ní èròńgbà òun ni láti fòpin sí polio pátápátá àti pé òun máa ń sọ fún àwọn òbí pé tí wọn kò bá jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn gba abẹ́rẹ́ àjẹsára, ó ṣeéṣe kí wọ́n dàbí òun tí òun ń fi igi rìn.

Ó sọ pé òun ti ṣetán láti kópa nínú ètò fífún àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára tó tún máa bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá.

Awọn ọlọpaa to n tẹle awọn oṣiṣẹ ilera

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àgbáyé tí kò ní polio

Àjọ WHO ń ṣiṣẹ́ lórí ìdí táwọn èèyàn kò fi fẹ́ máa gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.

Àwọn ìròyìn òfégè tó ń tàn kalẹ̀ láti orí ayélujára nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára jẹ́ ìṣòro ńlá. Àwọn onírúurú ọ̀nà ni àwọn òṣìṣẹ́ ètò polio ń gbà láti fi pèsè ojúlówó ìròyìn nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára láti paná ìròyìn òfégè.

Jafari ní tí àwọn ìjọba orílẹ̀ èdè méjèèjì bá ní ìfarajìn sí fífi òpin sí polio lọ́dún 2025 pẹ̀lú ètò fífún gbogbo ọmọdé tọ́jọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún márùn-ún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára, àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ máa di ohun ìgbàgbé.

Tí èyí bá kẹ́sẹ járí, polio máa di àìsàn kejì tí ìgbìyànjú ẹ̀dá rí òpin rẹ̀ lẹ́yìn àìsàn Sopona.