"N kò rò pé àjálù bàálù le kan Bàbá mi, mo ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí bàálù tó já ní 2019"

Àkọlé fídíò, Ziporah Kuria: Ìgbà 48 ni mo pe fóònù bàbá mi, n kò gbà pé ó wà lára èèyàn 346 tó kú
"N kò rò pé àjálù bàálù le kan Bàbá mi, mo ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí bàálù tó já ní 2019"

Isẹlẹ nla kan sẹ ni ọjọ kẹwa, osu kẹta ọdun 2019, eyi to ti pe ọdun marun bayii.

Isẹlẹ naa ni baalu nla kan to ja eyi to ko ero ojilelọọdunrun ati mẹfa (346), ti ẹnikẹni ko si ye ijamba naa.

Deede aago marun ku isẹju mẹẹdogun ni ijamba naa waye, eyi to milẹ titi.

Lẹyin ọdun marun ti isẹlẹ ijamba baalu to n pani lẹkun naa waye, BBC ba Zipporah Kuria, tii se ọkan lara ọmọ awọn eeyan to ku ninu isẹlẹ naa sọrọ.

Ninu ọrọ rẹ, Zipporah ni isẹlẹ naa ba oun lojiji nigba to waye, ti oun ko si gba pe iru ijamba bayii le sẹlẹ si idile oun.

Zipporah Kuria

"Mo n pe foonu baba mi fun igba mejidinlaadọta lati gbọ ohun rẹ, ki n si ri daju pe o laye amọ ko gbe ipe mi.”

Zipporah Kuria tẹsiwaju pe “Inu sinima ni mo ti maa n gbọ nipa isẹlẹ yii, n ko lero rara pe o le ba idile mi.

Baba mi wa ninu baalu to ja naa, ti wọn si pe ẹgbọn mi lati sọ isẹlẹ naa fun amọ emi ko tiẹ fẹ gbọgbọ rara pe baba mi ti ku.

Mo n pe foonu baba mi fun igba mejidinlaadọta lati gbọ ohun rẹ, ki n si ri daju pe o laye amọ ko gbe ipe mi.”

Zipporah wa gbara ta pe ko tii si idajọ ododo lati igba ti isẹlẹ naa ti waye nipa asise ileesẹ to ni baalu to ja naa.

O wa n beere pe se wọn n fẹ ki ọpọ eeyan ku tan ninu ijamba baalu, ki wọn to fa awọn ileesẹ to n sakoso baalu leti nipa ọpọ asise wọn.

Bakan naa ni obinrin yii tun pe fun akoso to mọyan lori ni awọn ileesẹ baalu to n fo yika gbogbo agbaye.