Ìdí rèé tí èmi àti Peter Obi pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú míì ṣe fẹ́ lẹ̀pọ̀ saájú ìdìbò 2027 - Atiku

Oríṣun àwòrán, ATIKU ABUBAKAR/X
Igbakeji Aarẹ tẹlẹri ati oludije Aarẹ ninu eto idibo to kọja, Atiku Abubakar ti bẹrẹ si ni gbaradi fun eto idibo to n bọ, to si ti n ba ọpọ ẹgbẹ oṣelu yooku yatọ si ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ lori bi wọn yoo gba agbara kuro lọwọ APC.
Atiku ni ipade oun pẹlu oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi n pe fun ifọwọsowọpọ ninu ẹgbẹ oṣelu.
“Fun awọn to ro pe ija wa laarin emi ati Obi, ko si nnkan to jọ bẹ.
“Ni ọjọ iwaju, ẹnikẹni to ba bori pe ko dije sipo ni a yoo gbaruku ti.”
Igbakeji Aarẹ tẹlẹ naa tẹsiwaju pe “Mo ti sọ saaju pe ti ẹgbẹ oṣelu ba parapọ, ẹ jẹ ki ẹni to wa lati guusu orilẹede Naijiria dije dupo.
“Ni bayii, a ti n sọrọ lori bi a yoo ṣe fọwọsowọpọ ninu ẹgbẹ oṣelu wa pẹlu awọn yooku lati ri pe a ṣe aṣeyọri.”
'Ǹ kò tí ṣetán láti fẹ̀yìntì nínú òṣèlú'

Oríṣun àwòrán, ATIKU ABUBAKAR/X
“Ti ẹnikẹni ba ro pe a pada sẹyin, ma wo bi awọn arabi ṣe n fiya jẹ ọmọ Naijiria, iru eeyan bẹ n la ala ni nitori ọrọ oṣelu ko ti su mi rara"
Igbakeji Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria Atiku Abubakar ti ni oun ko ti ṣetan lati fẹyin ti bayii ninu oṣelu, ti oun yoo si maa ṣe oṣelu ti oun yoo fi jade laye.
Atiku, ẹni to jẹ oludije sipo Aarẹ labẹ aisa ẹgbẹ PDP ninu eto idibo to kọja ni oun ko ni figba kankan fopin si jija fun ijọba awarawa lorilẹede Naijiria.
O ni bi ijọba asiko yii se n se awọn araalu ni ko dun mọ oun ninu, ti oun si setan lati ripe igba ọtun dide lorilẹede Naijiria.
“Ti ẹnikẹni ba ro pe a yoo pada sẹyin, ma wo bi awọn arabi ṣe n fiya jẹ awọn ọmọ Naijiria, iru eeyan bẹ n la ala ni nitori ọrọ oṣelu ko ti su mi rara.
“Ni bayii a n wo ọdun 2027 lati mọ boya ma jade dupo tabi rara
“A yoo ri pe a ja lati ri pe ijọba awarawa pada si orilẹede Naijiria, ti a si tun se idagbasoke orilẹede wa.”
Lati ọdun 1989 ni Atiku ti bẹrẹ oṣelu , to si sumọ igbakeji aarẹ ologun nigba naa, Ọgagun Shehu Musa Yar’adua.
O ti darapọ orisirisi ẹgbẹ oṣelu lati igba naa.
Atiku jẹ Gomina ipinlẹ Adamawani ọdun 1998 bo ti lẹ jẹ pe Oloye Olusegun Obasanjo pada kede rẹ gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ.
Igba kẹfa ree ti Atiku ti n dupo lati jẹ Aarẹ orilẹede Naijiria sugbọn ko ni anfani lati di aarẹ, to si n padanu eto idibo.















