Ṣàńgbà fọ́, aráàlú kan yìnbọn ní ìgbà márùn-ún sí Olóòtù ìjọba Slovakia
Ọlootu ijọba lorilẹede Slovakia, Robert Fico ni o ti dero ile iwosan lẹyin ti ọkunrin kan yin lu ni laagbo ero.
Igba marun un ọtọtọ ni agbebọn naa yin ibọn lu Olootu ijọba, ti ibọn naa si ba bi ikun ati apa.
Lẹsẹkẹsẹ ni wọn gba Fico lọ ile iwosan, ti o si ti n gba itọju lẹyin to ti ṣe iṣẹ abẹ fun wakati marun un.
Afurasi ọhun lo ti wa ni ahamọ lẹyin to yinbọn lu Fico.
Miriam Lapunikowa, oludari ile iwosan F.D Roosevelt ni Banska Bystrica nibi ti Fico ti n gba itọju sọ fun awọn akọroyin pe lotitọ ni ipo ti Fico wa bayii buru pupọ.
Saaju ni Igbakeji olootu ijọba, Tomas Teraba sọ fun BBC pe iṣẹ abẹ ti wọn ṣe fun Fico jẹ aṣeyọri ti oun gbagbọ pe yoo wa laye.
Minisita fun ọrọ abẹlẹ lorilẹede naa, Matus Sutaj Estoka ṣapejuwe ikọlu si Olootu ijọba gẹgẹ bii eyi to ni ọwọ oṣelu ninu.
Ọpọ awọn araalu, olori orilẹede lagbaye lo ti bu ẹnu atẹlu ikọlu, ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi to tabuku ijọba awarawa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọn ti fẹsun ipaniyan kan afurasi to yinbọn lu Olootu ijọba
Ọkunrin to yinbọn lu Olootu ijọba orilẹede Slovakia, Robert Fico ni wọn ti fẹsun ipaniyan kan bayii.
Wọn ko ti darukọ afurasi naa sugbọn iwadii lorilẹede Slovakia fihan pe ọkunrin naa jẹ ẹni ọdun mọkanlelaadọrin to wa lati ilu Levice.
Bakan naa ni iwadii tun jẹ ko di mimọ pe o ṣeeṣe ki wọn ran ọkunrin naa ni ẹwọn egbere.
Fico, ẹni ọdun mọkandinlọgọta lo wa laye sugbọn ipo to wa dẹru bani pupọ
















