Pátákó ìpolówó ọjà wó pa èèyàn mẹ́rìnlá tó sá sábẹ́ rẹ̀ lásìkò ìjì òjò líle, ọ̀pọ̀ míì farapa, mọ́tò bàjẹ́

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan, eeyan mẹrinla ni wọn ti di oku bayii latari patako nla ipolowo ọja kan to wo lasiko iji lile to ṣẹlẹ ni Mumbai, lorilẹ-ede India.
Yatọ si eyi, ọpọlọpọ eeyan ni wọn tun farapa lọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu karun-un ọdun 2024 yii ti iṣẹlẹ naa waye.
Gẹgẹ b’awọn ọlọpaa ṣe wi, patako naa wo sori awọn ile to wa nitosi ati ile epo kan.
Wọn ni patako naa gùn ni iwọn aadọrin, o si fẹ ni iwọn aadọta mita.
Awọn ẹṣọ oṣiṣẹ pajawiri ṣalaye pe awọn eeyan kan ṣi wa labẹ rẹ, bẹẹ ni iṣẹ si n lọ lọwọ lati yọ wọn.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Maharashtra, nibi ti ijamba naa ti waye ti ni ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ló tún rún wómú s’ábẹ̀ pátákó náà

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aworan kan loju opo iroyin ilẹ India ṣafihan asiko ti patako naa n fì ninu iji lile ọhun.
O fi han bi patako ọhun ṣe n fi gbogbo agbara mì ko too wo lulẹ sori ilẹ.
Bakan naa ni awọn ọkọ̀ pupọ run womu si abẹ rẹ nigba ti agbara iji lile naa wo o lulẹ.
Fidio kan naa ṣafihan awọn oṣiṣẹ pajawiri ti wọn n yọ ẹnikan jade labẹ patako naa, bẹẹ ni wọn n fi irinṣẹ wọn ge awọn irin to de patako naa mọlẹ.
Gẹgẹ bi oṣiṣẹ pajawiri kan ṣe ṣalaye fun ẹka iroyin ANI, o ni, " eeyan to to ọgọrin lati da aabo bo lọwọ ewu yii. Ọkọ̀ ayọkẹlẹ pupa kan wa to ti run jegejege. A woye pe awọn eeyan kan ṣi wa ninu rẹ ti wọn ko le jade.’’
Ọmọbinrin kan, Akshay Vasant Patil, ẹni ogun ọdun, sọ pe,
" mo duro nibi ileepo naa pẹlu mọto mi, bi mo ṣe ṣakiyesi pe patako yẹn fẹẹ wo niyẹn.
‘’Mo gbiyanju lati sa kuro nibẹ, ṣugbọn niṣe ni mo ha si aarin ọkọ meji.
‘’Awa bii mẹjọ tabi mẹsan-an ṣaa wa ọna, a ri ọna abayọ. Ṣugbọn a tun ri ọpọ eeyan ti wọn ha sabẹ patako naa, ti wọn ko le jade’’
‘‘Ọmọ mi yà fún òjò ni pátákó fi wó pa á’’

Oríṣun àwòrán, Others
Iya kan, Naina Vinod Rathod, ṣalaye bi ọmọ rẹ, Bharat, ẹni ọdun mẹrinlelogun ṣe padanu ẹmi rẹ sinu ijamba naa.
‘’Ibi iṣẹ ni ọmọ mi n lọ ti ojo naa fi bẹrẹ pẹlu iji lile, o ya fun ojo naa lo fi sa si abẹ afara kan.
‘’Ṣugbọn lasiko naa ni patako ipolowo ọja wo lulẹ, o si pa a sibẹ ki n too de ibi iṣẹlẹ naa.’’
Mama naa sọ pe ile loun wa, baba ọmọ naa to ti jade lo pe oun lori aago to si fi iṣẹlẹ aburu naa to oun leti.
Ijọba Maharashtra kẹdun iṣẹlẹ yii

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Maharashtra ti iṣẹlẹ yii ti waye ti ba awọn to kan kẹdun.
Wọn ṣeleri iranlọwọ owo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta rupee owo India (500,000 rupees) fawọn idile to padanu eeyan wọn, ati fun awọn ti wọn farapa nibi iṣẹlẹ ọhun.
Agbegbe Mumbai yii jẹ ọkan ninu awọn agbegbe to ṣee ṣe ki ẹkun omi ti maa waye gan-an ni India, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe wi.
Wọn ni ijamba bii iji lile lasiko ojo maa n ṣẹlẹ pupọ nibẹ.
Eyi maa n waye laarin oṣu kẹfa si oṣu kẹsan-an ọdun.














