Èèyàn 200,000 padà sí Gaza lẹ́yìn àdéhùn jógun-ó-mí láàrín Israel àti Hamas

Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọpọ awọn eeyan to n gbe lagbebge Gaza tẹlẹ lo ti n pada sile wọn bayiii lẹyin adehun jogunomi laarin orilẹede Israel atawọn ọmọ ogun Hamas.

O le ni ẹgbẹrun lọna igba eeyan to fi ẹsẹ rin lọ si ariwa Gaza laarin wakati meji pere ti wọn ṣi ẹnu ọna abawọle ilẹ naa.

Aago mẹsan an aarọ ni wọn ṣilẹkun fun awọn ọkọ lati maa kọja, iyẹn lẹyin wakati meji ti awọn to n fi ẹsẹ rin kọkọ kọja.

Akọroyin BBC to wa nibẹ, Rushdi Abualouf ni wọn ko tete fun awọn to gbe ọkọ laaye lati kọja.

Ileeṣe iroyin AFP jabọ pe ijọba Gaza ti gba ẹgbẹrun marun un abọ eeyan siṣẹ lati ṣamọna bi awọn eeyan naa yoo ṣe pada sile wọn.

Ijọba ọhun ni awọn eeyan naa yoo nilo nnkan bii atibaba igbalode 135,000 bi wọn ṣe n pada latari pe ile pupọ ninu awọn eeyan naa lo ti dawo.

Ibanujẹ ṣubu lu ayọ

Ẹwẹ, ni ṣe ni ibanujẹ n ṣubu lu ayọ fun pupọ ninu awọn eeyan naa to n pada sile wọn.

Akoko naa jẹ akoko ti ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan ọhun ti n duro de lati nnkan bii ọdun kan sẹyin, ṣugbọn inu wọn bajẹ nigba ti wọn fi oju ri bi ilẹ wọn ṣe dahoro.

Ni iwọ oorun Gaza atawọn agbegbe mii, ni ṣe lo da bii igba ti iṣẹlẹ iri riri ba waye nibẹ nitori bi ọpọ ile ṣe dawo.

Ọkan lara awọn eeyan naa, Mohammed Imad Al-Din, to n ṣiṣẹ gẹrigẹri, ni inu oun kọkọ dun lati pada sile.

Ṣugbọn nigba ti yoo pada ri ile rẹ, ile naa ti dawo, awọn eeyan kan ti ko gbogbo ẹru inu ṣọọbu to ti n gẹ irun, bẹẹ ni ado oloro ti wo ile to wa lẹgbẹ ile rẹ.