Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Agba amofin nni, oludasilẹ ile ẹkọ giga fasiti Afe Babalola University, Afe Babalola ti loun ko ba Dele Farotimi ṣẹjọ mọ

Ah, mo ranti igba to gbe Farotimi lọ sile ẹjọ pe o ta epo si aṣọ ala oun lori iwe rẹ to kọ

Agba amofin naa ni nitori awọn oriade bii Ọọni Ile Ife, Ewi ti Ado- Ekiti atawọn agbagba Yoruba mii

Loun ṣe jọwọ silẹ lori ẹjọ naa

Lonii ni olori Naomi Silekunola, Oriyomi Hamzat ati olukọ agba ile ẹko Islamic Secondary School tun foju balẹ ẹjọ

Lori ẹsun to ni i ṣe pẹlu iku awọn ọmọde marundinlogoji to padanu ẹmi wọn nibi apejẹ ọdun n'Ibadan

Oni lo yẹ ki adajọ beere lọwọ awọn ti wọn fẹsun kan naa boya wọn jẹbi ẹsun naa amọ

Amọ kini?

Kan si oju opo bbc.com/yoruba fun ẹkunrẹrẹ

Njẹ o mọ ko fẹ ẹ si oṣu kan ki tanka agbepo ba ṣubu lulẹ ni Naijiria?

Ọrọ naa ti fẹ maa di lemọlemọ to si n mu ọpọ ẹmi lọ lẹnu ọjọ mẹta

Ṣe o mọ pe awọn nnkan mẹjọ kan to yẹ ko o ṣe nigba ti iṣẹlẹ bayii ba waye ni agbegbe to ba wa?

Ka wọn fun mi dakun

Tara ṣaṣa kan si oju bbc news yoruba lati mọ awọn ọna to le gba da aabo bo ara rẹ naa

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́