Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì tún jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod
Agba ọjẹ osere tiata miran, ti ọpọ eeyan mọ ni Asakoko ti jade laye.
Aisan ọlọjọ pipẹ lo se gbajumọ osere tiata naa titi doju iku, to fi dagbere faye.
Gbajugbaja akẹẹgbẹ oloogbe naa lagbo tiata, Kunle Afod, lo gbe iroyin iku Asakoko sita loju opo Instagram rẹ.

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod Instagram
Gẹgẹ bi Afod ti wi, laipẹ yii ni oun kede fun araye nipa aisan ati ailera agba ọjẹ osere naa.
Bakan naa lo sọ pe ẹsẹ osere naa wu, so si se afihan ẹsẹ to wu naa loju opo ayelujara naa.
"O ti le ni ọdun meji ti aisan ti n ba Asakoko finra, to si ti n jẹ irora."
Lasiko to n saisan yii, Asakoko, ẹni to ni iyawo mẹwa sọ pe gomina ipinlẹ kan ti wa bẹ oun wo lori idubulẹ aisan nile iwosan ti oun ti n gba itọju.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ninu fidio ti Kunle Afod gbe soju opo Instagram rẹ naa, lo se afihan bo ti se abẹwo si osere tiata naa nile iwosan to ti n gba itọju.
Obinrin kan si joko sẹgbẹ rẹ.
Asakoko lasiko to n ba Kunle Afod sọrọ ni " Mo lọ si Island, ọdun meji ati osu meji ni mo lo nile iwosan.
Gbogbo ẹsẹ mi bayi delẹ, o bo ni, egbo ni gbogbo ẹ.
Gomina gan wa, amọ mo n sun, to si ni ki wọn ma ji mi.
Mi o ti gbadun daadaa, tori ẹsẹ mejeeji lo si wu, to n dun mi."















