Àwọn agbébọn pa ọ̀gá wọ́dà méjì, ẹlẹ́wọ̀n sá lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oṣiṣẹ Wọda meji ti di ero ọrun lẹyin ti awọn agbebọn da ọkọ kan to n gbe awọn ẹlẹwọn lọna ti wọn si ṣina ibọn bo ọkọ wọn ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Rouen nitosi ilu kan ti wọn n pe ni Normandy lorilẹede France.
Iroyin to n jade lawọn ileeṣẹ iroyin ni France ni awọn ọga wọda naa n gbe ẹlẹwọn kan lọ lasiko ti ikọlu naa waye. Ẹlẹwọn naa si sa asala ba awọn agbebọn naa lọ.
Awọn agbofinro atawọn ologun ti gunlẹ si agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lati ṣe awari ẹlẹwọn to salọ naa atawọn to wa tu u silẹ.
Ikọlu to waye laarọ yii jẹ eyi to ya gbogbo wa lẹnu – Aarẹ Emmanuel Macron

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede France, Emmanuel Macron kede loju opo X rẹ pe “gbogbo ipa ni a n sa lati ṣe awari awọn eku ẹda to ṣe ọṣẹ naa”.
Aarẹ Macron ni ni iyalẹnu nlanla ni ikọlu naa jẹ. O ni gbogbo awọn orilẹede naa lo duro ni atilẹyin fun awọn mọlẹbi awọn to farapa atawọn to jade laye.
Minisita fun eto idajọ lorilẹede France, Eric Dupond-Moretti ni awọn ọga wọda mẹta miran fi ara ṣeṣe lasiko ikọlu ọhun ti wọn si ti n gba itọju ni ile iwosan.
- Àwọn jàndùkú agbébọn lé àwọn èèyàn kúrò ní abúlé àádọ́ta ní Zamfara
- Pátákó ìpolówó ọjà wó pa èèyàn mẹ́rìnlá tó sá sábẹ́ rẹ̀ lásìkò ìjì òjò líle, ọ̀pọ̀ míì farapa, mọ́tò bàjẹ́
- Akọ̀wé ìjọba Améríkà, Blinken, balẹ̀ sí Ukraine bí Russia ṣe fẹ́ ya wọ ìlú ńlá míì
- Àbúrò mẹ́wàá ni mo pàdánù nínú ìkọlù Israel sí gúúsù Gaza

Oríṣun àwòrán, screenshot/ x
Ileeṣẹ mohunmaworan kan lorilẹede France, BFMTV ṣalaye pe wọn n gbe ẹlẹwọn naa pada lọ si ọgba ẹwọn to wa ni ilu Évreux lẹyin to lọ fun igbẹjọ ni ile ẹjọ lowurọ ọjọ Iṣẹgun ni Rouen.
Nnkan bii agogo mọkanla lorilẹede France ni ikọlu naa waye nitosi ibudo ibanisọrọ kan to wa ni opopona A154 motorway, ti awọn agbofinro ti ti pa.
‘Awọn agbebọn to ṣọṣẹ naa lo iboju lasiko ti wọn ṣe ikọlu naa’

Oríṣun àwòrán, other
Gẹgẹbi iroyin ti AFP gbe sita, ọpọ lawọn agbebọn to ṣe ikọlu naa, Ọkọ meji ni wọn si lo lati ṣe ikọlu ọhun.
Iroyin to lọ kaakiri awọn ileeṣẹ iroyin lorilẹede France n sọ pe ẹlẹwọn ti wọn n gbe pada lọ si ọgba ẹwọn naa atawọn agbebọn to ṣe ikọlu ọhun sa asala pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn fi silẹ lẹyin ti wọn ti dana sun un.
Awọn aworan kan to n yọju lori ayelujara, ti awọn ileeṣẹ iroyin kan lorilẹede France lo fi awọn agbebọn naa han pẹlu iboju lasiko ti wọn n sun mọ awọn ọkọ to n gbe ẹlẹwọn naa lọ. BBC ko tii le fi idi otitọ awọn aworan naa mulẹ.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Ọgbẹni Dupond-Moretti ni awọn afurasi naa lo “awọn ibọn to lagbara gidi” lati kọlu ọkọ ọgba ẹwọn naa.
“Ọga wọda meji lo ku. ọkan ninu wọn fi iyawo ati ọmọ meji silẹ. Ekeji fi iyawo to wa ninu oyun oṣu marun un silẹ.”












