Kílódé táwọn orílẹ̀èdè kan kìí ṣe fẹ́ rí Palestine gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀èdè?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu ikede kan to jade lọjọ kejilelogun Oṣu Karun-un, orilẹede Spain, Norway, ati Ireland ṣafihan ero wọn lati kede idanimọ orilẹede fun Palestine lọjọ kejidinlọgọn Oṣu Karun 28.
Awọn oludari Palestine ṣe itẹwọgba ipinnu naa, ti wọn si sapejuwe rẹ gẹgẹ bii "itan balẹ "
Awọn orilẹ-ede ti n ṣe atilẹyin dida orilẹede Palestine gbagbọ pe yoo ṣe iranlọwọ ilọsiwaju alaafia laarin Israeli ati Palestine.
Sibẹsibẹ, Israel fariga, o sọ pe yoo pe awọn aṣoju orilẹ-ede mẹta lati wo fidio ikọlu ọjọ keje Oṣu Kẹwaa ọdun 2023.
“Itan yoo ranti pe Spain, Norway, ati Ireland pinnu lati fun awọn ọmọ ogun Hamas ti wọn jẹ apayan ni ami-ẹyẹ goolu" Minisita Israel Katz salaye.
Israeli ko ri ṣe Palestine gẹgẹ bii orilẹede ati pe ijọba Israeli lọwọlọwọ n tako dida orilẹede Palestine ni West Bank ati Gasa. O jiyan pe idasilẹ yii jẹ ewu nla fun Israel.
Awọn wo lo ri Palestine gẹgẹ bii orilẹede?

Oríṣun àwòrán, ERIK FLAARIS JOHANSEN/EPA-EFE/REX/Shutterstock
O kere ju awọn orilẹ-ede ogoje to ri Palestine gẹgẹ orilẹede pẹlu awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ, ẹgbẹ Araabu ni Ajo Agbaye, ati awọn ọmọ ẹgbẹ ti awọn orilẹede to da duro.
Sibẹsibẹ, ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede miiran, bi Amẹrika, UK, France, Germany, ati Australia, ko ri Palestine gẹgẹ bii orilẹede.
Ni Oṣu Kẹta, awọn oludari Ilu Spain, Ireland, Malta ati Slovenia fi atẹjade síta fun ajọ EU pe awọn yoo fọwọsowọpọ lati ri pe wọn Palestine gẹgẹ bii orilẹede nigba ti asiko ba ya.
Ṣaaju ki ikede naa to jade, awọn orilẹ-ede Yuroopu mẹsan an kede atilẹyin fun Palestine, ti gbogbo da lori ipinnu ti wọn se ni ọdun 1988 nigbati wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Soviet.
Igbesẹ iṣọkan tí Spain Norway, ati Ireland gbe kalẹ wa ni bii oṣu kan lẹyin ti Ajo Agbaye (UNSC) dibo lori pe ki Palestine le di ọmọ ẹgbẹ ajọ naa.
Amẹrika, alabaṣepọ ti Israeli fun ọjọ pipẹ, tako ipinnu naa, ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ 12 ti igbimọ dibo fun igbesẹ naa, pẹlu awọn alajọṣepọ Amẹrika mẹta: France, Japan, ati South Korea. UK ati Switzerland kọ yọju
Ti Igbimọ Aabo ajọ UN ba buwọlu aba, ti Algeria gbe siwaju, Apejọ Gbogbogbo yoo ni latidibo le lori, ti o nilo idamẹta to poju fun Palestine lati le di tẹwọgba wọle.
Awọn ipinnu UNSC ni wọn le buwọlu kọja nikan ti ẹnikẹni ninu ninu awọn ọmọ ẹgbẹ marun to jẹ ọmọ ẹgbẹ ayeraye - US, UK, France, Russia, tabi China - ba kọ lati buwọlu wọn.
Mahmoud Abbas, Aarẹ Palestine, sọ pe ero USjẹ “aiṣedeede,” ṣugbọn Israeli yìn igbese naa, ni apejuwe ipinnu naa bi eyi ti ko ni itiju.
Lẹyin ibo naa, Igbakeji Aṣoju US si UN Robert Wood sọ fun igbimọ naa: “Amẹrika n tẹsiwaju lati ṣe atilẹyin ni agbara ojutuu ipinlẹ meji. Idibo yii ko ṣe afihan atako si Palestine, ṣugbọn pe fun idunadura taara laarin awọn ẹgbẹ mejeeji."
Kílode tí awọn orilẹede ko ṣe rí Palestine gẹgẹ bii orilẹede?
Awọn orilẹ-ede ti ko ṣe idanimọ Palestine gẹgẹ bii orilẹede ni ko ti ṣe bẹ nitori pe ko si adehun idunadura pẹlu Israel.
“Bo ti lẹ jẹ pe o ti ṣe eyi to tọ lati jẹ orilẹede, Amẹrika tẹnumọ pe lori idunadura taara gbọdọ wa laarin Israeli ati Palestine, eyiti o tumọ si fifun Israeli ni agbara lori awọn ireti Palestine lati di orilẹede,” Fawaz Gerges sọ, ọjọgbọn Ile-ẹkọ Iṣowo ti Ilu London.
Ijiroro alaafin bẹrẹ ni ọdun 1990 ti wọn ṣeto ojutu-ipinlẹ meji nibiti awọn ọmọ Israeli ati awọn ara ilu Palestine le gbe ni ẹgbẹ ara wọn ni awọn orilẹ-ede lọtọ.
Sibẹsibẹ, ijororo alaafia ni o bẹrẹ si ni dinku to si n lọra lati ibẹrẹ 2000s, paapaa ṣaaju 2014, nigbati ijiroro kuna laarin awọn ọmọ Israeli ati awọn ara ilu Palestine ni Washington.
Awọn ìṣòro ni wọn kuna lati wa ojutu si paapa ọrọ nipa ibode wọn ati ọjọ ọla Palestine, ipo Jerusalemu, ati ayanmọ ti awọn asasala Palestine lati ogun 1948-49 lẹyin ikede ti ẹda Israel gẹgẹ bii orilẹede.
Israeli tako ifẹsẹmulẹ ọmọ ẹgbẹ UN fun Palestine.
Aṣoju Israel ni Ajo Agbaye, Gilad Erdan ni AFP sọ pe o sọrọ ninu Oṣu Kẹrin pe otitọ pe ijiroro naa n waye “ti jẹ iṣẹgun fun ẹru ipaeyarun”, fifi kun pe ipinnu aṣeyọri yoo ti jẹ ẹsan fun ikọlu ọjọ keje Oṣu Kẹwa tí ikọ Hamas.
Awọn orilẹ-ede ti o pinnu lati ṣetọju ajọsepọ pẹlu Israeli mọ pe riri Palestine gẹgẹ bii orilẹede kan yoo bi ọrẹ wọn ninu
Diẹ, pẹlu awọn alatilẹyin ti Israeli, jiyan pe awọn ara ilu Palestine ko ni ohun to tọ lati di orilẹede gẹgẹ apejọ Montevideo 1933 ṣe salaye
Ipo wo ni Palestine wa ni ajọ agbaye UN?

Oríṣun àwòrán, SHAHZAIB AKBER/EPA-EFE/REX/Shutterstock
Oluwoye ti ki ṣe ọmọ ẹgbẹ ni a le pe ipo Palestine ni UN.
Ni ọdun 2011, Palestine fi ohun ransẹ lati di orilẹ-ede ọmọ ẹgbẹ UN ni kikun, ṣugbọn ibere naa kuna lati wa si imusẹ nitori aini atilẹyin ni Igbimọ Aabo UN ati pe ko wa si bi ibo.
Sibẹsibẹ, ni ọdun 2012, Apejọ gbogbogo ti UN dibo lati ṣe igbesoke ipo Palestine si ti “oluwoye ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ,” eyiti o jẹ ki wọn kopa ninu awọn ijiyan apejọ, bo ti lẹ jẹ pe wọn ko le dibo lori awọn aba.
Ipinnu 2012 - eyi ti o jẹ itẹwọgba ni West Bank ati Gaza ṣugbọn ti US ati Israeli bu ẹnu atẹlu - tun gba Palestine laaye lati darapọ mọ awọn ajọ agbaye miiran, pẹlu ile-ẹjọ giga ti UN, Ile-ẹjọ Odaran, eyiti wọn ṣe ni ọdun 2015.
“Jijẹ ọmọ ẹgbẹ ni kikun ti UN yoo fun Palestine lati le gbe aba kalẹ diẹ, pẹlu agbara lati ṣe onigbọwọ awọn ipinnu taara, lati dibo ni Apejọ Gbogbogbo (eyiti, gẹgẹbi orilẹede 'ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ’, wọn ko ni lọwọlọwọ) ati lati ni ijoko/idibo ni Igbimọ Aabo,” Khaled Elgindy ni Washington ṣalaye.
“Ṣugbọn ko si ọkan ninu nkan wọnyi ti yoo mu ojutu orilẹede meji wa - eyiti o le ṣẹlẹ nikan nipa ipari iṣẹ Israeli,” o ṣafikun.
Bibẹẹkọ, Gilbert Achcar, olukọ ọjọgbọn ni Ile-iwe ni Ilu London, gbagbọ “Awọn alasẹ Palestine ko ni le ṣe aṣeyọri to pọ” pẹlu jíjẹ ọmọ ẹgbẹ UN ni kikun.















