Ọ̀rọ̀ oyún ṣíṣẹ́ ṣe wá di wàhálà t’áwọn aláboyún fi ń pe ìdájọ́ ilé ẹjọ́ níjà?

Aláboyún

Oríṣun àwòrán, Others

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Texas, orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ti ní àwọn kò gba ẹjọ́ tí àwọn obìnrin ogún kan pè tako òfin tó de oyún ṣíṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Àwọn obìnrin náà ní àwọn dókítà kọ̀ láti ṣẹ́ oyún fún àwọn nígbà tí àwọn nílò rẹ̀ fún ìlera àwọn nítorí òfin tó de oyún ṣíṣẹ́.

Àwọn obìnrin náà àti dókítà méjì ló ń pe ilé ẹjọ́ náà níjà láti ṣàlàyé ohun tí òfin tó de oyún ṣíṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà dá lé lórí gan.

Wọ́n ní àlàyé lórí ohun tó yẹ kí àwọn dókítà ṣe lásìkò tí olóyún bá nílò láti ṣẹ́yún nítorí ìlera rẹ̀ kò yé tó, àti pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ni ẹ̀mí wọn ń wà nínú nítorí àwọn dókítà kò fẹ́ lùgbàdì òfin.

Àmọ́ àwọn Adájọ́ mẹ́sàn-án ilé ẹjọ́ náà ní àwọn kò gba ìpèníjà náà wọlé.

Àwọn Adájọ́ náà ní òfin tó wà nílẹ̀ fi ààyè gba àwọn dókítà láti ṣẹ́yún fún obìnrin tí oyún náà bá fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu.

Adájọ́ Jane Bland ní òfin fàyè gba àwọn dókítà láti ṣẹ́yún fún obìnrin kí ẹ̀mí rẹ̀ má ba à bọ́ tàbí tí oyún náà yóò bá dá ọgbẹ́ ayérayé si lára.

Bland ní dókítà tí yóò bá ṣẹ́yún náà gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ìlànà òfin tó yẹ láti gbé ìgbésẹ̀ náà.

“Ṣíṣẹ́ oyún ọmọ tó bá ṣì le yè jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin àyàfi tí ẹ̀mí ìyá bá wà nínú ewu,” ilé ẹjọ́ sọ.

Dókítà tó bá lòdì sí òfin yìí ni ó ṣeéṣe kó rí ẹ̀wọ̀n tó tó ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) he, san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn-ún dọ́là, tí yóò sì tún pàdánù ìwé àṣẹ láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dókítà.

Amanda Zurawski

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amanda Zurawski tó pe ẹjọ́ náà ní ilé ẹjọ́ ti fi hàn pé àwọn kò fẹ́ rán àwọn olóyún Texas lọ́wọ́ láti gba ìtọ́jú tó péye àti pé wọn kò fẹ́ jẹ́ kí àwọn dókítà ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́.

Ọ̀sẹ̀ méjìdínlógún (18) ni oyún Zurawski wà nígbà tí bẹ̀rẹ̀ sí ní mu, tí àwọn dókítà sì sọ fún pé ọmọ inú rẹ̀ kò le yè àmọ́ wọ́n kọ̀ láti ṣẹ́ oyún náà fun nítorí ọmọ náà ṣì ń mí.

Zurawski padà ní àìsàn sepsis, tó sì lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ní ikẹ ìwòsàn láti gba ìtọ́jú nítorí wọn kò ṣẹ́yún fún lásìkò.

Àwọn mọ́kàndínlógún (19) yòókù tí wọ́n jọ ń pè ẹjọ́ náà ní àwọn ní irú ìpèníjà báyìí tí àwọn dókítà kò sì ṣẹ́yún náà fún àwọn.

Àwọn kan ní àwọn lọ sí ìpínlẹ̀ mìíràn tó fàyè gba oyún ṣíṣẹ́ láti lọ ṣé, tí àwọn mìíràn sì ní àwọn dúró kí àárẹ̀ náà fi wọ àwọn lára tó ìgbà tí wọ́n lè ṣẹ́yún náà.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Samantha Casiano tí oyún rẹ̀ kò dàgbà bó ṣe yẹ ní òun wo ọmọ òun nínú ìnira kó tó jáde láyé lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí òun bi tán.

Agbejọ́rò àgbà Texas, Ken Paxton tó lòdì sí oyún ṣíṣẹ́ sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé òun máa ti òfin Texas náà lẹ́yìn, tí òun yóò sì tún máa ṣe gbogbo ohun tó wà ní ìkáwọ́ òun láti dá ààbò bo ìyá àtàwọn ọmọ wọn.

Marjorie Dannenfelser tó jẹ́ olórí ikọ̀ tó lòdì sí oyún ṣíṣẹ́ ní ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Amanda Zurawski kò bójúmu rárá nígbà tí òfin ti là á kalẹ̀ pé wọ́n le ṣẹ́yún fún ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ bá wà nínú ewu.

Ikọ̀ Center for Reproductive Rights ló ń ṣojú àwọn olùpẹjọ́ nílé ẹjọ́. Wọ́n ní ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn aláboyún ń jà fún ara wọn láti ìgbà tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Texas tí gbé òfin náà kalẹ̀.

Ní oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ni ilé ẹjọ́ ọ̀hún mú àyípadà bá òfin oyún ṣíṣẹ́, tí wọ́n sì ní òfin kò fàyè gbà á mọ́.

Àwọn olùwòye ní ìgbẹ́jọ́ yìí yóò tan ìmọ́lẹ̀ sí ipò ìlera tí olóyún yóò wà kí wọ́n tó lè ṣẹ́yún fun tó fi mọ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ tí kò fàyè gba oyún ṣíṣẹ́ rárá.

Ní oṣù tó ń bọ̀ ni ìrètí wà pé ìgbẹ́jọ́ mìíràn yóò wáyé.