Ohun méje tí o ní láti ṣe láti dín wàhálà kù lásìkò ìdánwò

Aworan akẹkọọ kan to gbaradi fun idanwo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba ti o ba n kawe fun igbaradi idanwo, o le maa ṣakiyesi wi pe o rẹ ọ, ki igbaradi naa si maa ko irẹwẹsi ọkan ba ọ.

O ko da wa: wahala jẹ ohun ti a ko ri ri ninu igbesi aye ẹda, ati pe asiko idanwo maa n jẹ asiko to le koko.

Ṣugbọn awọn ọna wa lati le fi din wahala ku, ki o si wa ni ilera pipe.

Ṣiṣe amulo awọn iwa lati din wahala ku yoo ni ipa rere ti yoo ko ninu igbesi aye rẹ ati iwuwasi rẹ, to si jẹ ki n wa ni alaafia lati le ṣe daadaa ninu eto ẹkọ rẹ.

Ri daju pe o n mi daadaa

Ohun akọkọ ti o nilo lati ṣe nigba ti o ba rii pe o rẹ ọ ni lati min eemi ti yoo delẹ. Fi arabalẹ min daadaa.

Nigba ti o ba ti n ni imọlara wi pe o n fẹ rẹ ọ, ọkan rẹ yoo lọ soke, oogun yoo maa jade ni atẹlẹwọ rẹ, bi ẹjẹ ṣe n lọ soke silẹ yoo tun dide sii.

Bi o ba wa fi arabalẹ min daadaa nigba ti imọlara yii ba wọle de, o le ṣatunto ọkan rẹ, ki o si din wahala agọ ara ku.

Eyi yoo jẹ ki ọkan rẹ wa loju kan si ohun ti o fẹ ṣe, yoo si tun fi aaye silẹ fun ọ lati pinnu lori ohun ti o maa ṣe si ọrọ wahala yii.

Lẹyin eemin gidi, awọn ohun miran tun wa ti o le ṣe, eyi to le ran ọ lọwọ lati ma jẹ ko maa rẹ ọ.

Ṣagbekalẹ afojusun to da ọ loju

O ṣe pataki lati ṣagbekalẹ afojusun to ṣee mu wa si imuṣẹ ti o maa tẹ ọ lọrun.

Ma fio ọpọ nnkan sinu akọsilẹ ohun ti o ba fẹẹ ṣe, eyi to ma maa mu ọ ṣaniyan nigba ti o ba n wo wọn. Ronu nipa awọn ohun ti le ṣaṣeyọri rẹ ninu asiko ti o ba ni, ki o si ni afojusun fun asiko agbeyẹwo lati le ni itẹsiwaju alaṣeyọri.

Ma ṣe gagbe lati ṣeto asiko lati tọju ara rẹ, ki o ma si ṣe gbagbe lati maa ki ara rẹ ku oriire nigba ti o ba n yege.

Fi asiko isinmi silẹ

Ko si sẹni to gbajumọ ohun kan ṣoṣo titi lai, iyẹn ni pe ki wọn maa ṣagbeyẹwo ohun ti wọn ti ka tẹlẹ. Lọpọ igba, gbigbajumọ ohun maa n fa rirẹ, o si maa n mu adinku ba ohun ti ba fẹẹ ṣe pari.

O tun le tunmọ si pe a nilo agbara lati pari ohun ti a dawọ le lọpọ igba, o si maa n fa ki a ṣe aṣiṣe lawọn igba miran.

Fifi asiko isinmi silẹ maa n mu idagbasoke ba iwe kika wa. Bi o ba wa rii pe o pọ ju, ṣe ohun miran lati ṣayipada.

Maa ṣe idaraya – ki o si maa jade nile

Ṣiṣe ere idaraya ni gbogbo igba ṣe pataki pupọ lati maa wa ni ilera pipe ati dindin wahala ku. O le gba ọna ti yoo tẹ ọ lọrun wa: Irin, sisare tabi kikopa ninu ere idaraya ti o fẹran.

Ma ṣe dawọ duro lati maa ṣe eyi nitori ti o ro pe o ni lati gbaradi fun idanwo.

Bi o ba le ṣe ere idaraya nita gbangba, iyẹn tun dara.

Iwadii ti mo ṣe pẹlu awọn akẹgbẹ mi fi han pe, lasiko ajakalẹ arun Korona, koda lai si awọn anfaani lati kopa ninu faaji awujọ, lilo awọn asiko lawọn agbegbe igbafẹ ni ipa rere lara awọn akẹkọọ.

Wa awọn ọrẹ rẹ

Nini ibaṣepọ pẹlu awọn eeyan lawujọ ni ipa rere to n ko ninu igbe aye alaafia awọn ọdọ. O le ba awọn eeyan sọrọ nipa atẹjiṣẹ lori ayelujara ni gbogbo ọjọ, ṣugbọn aṣilo ikanni ayelujara tun le ni ipa buruku ti yoo ko ninu igbe aye alaafia.

O ṣe pataki lati ni ibaṣepọ ojukoju pẹlu awọn ọrẹ ni ju ori ayelujara lọ: ṣagbekalẹ bi o ṣe le fojukoju pẹlu wọn ko to di asiko idanwo, ki o si rii daju pe o gbadun ara rẹ pẹlu wọn.

Fifi aaye silẹ lasiko ti o ba ṣe igbaradi jẹ anfaani nla lati ṣagbekalẹ awọn ero tuntun si ojuṣe. Ki lo de ti o jade lati ba awọn ọrẹ rẹ rin lati ṣe faaji?

Ṣe awọn ipinnu to dara

O le jẹ idanwo lati mu ohun mimu to n fun ni lagbara lati le kẹkọọ alẹ. Ṣugbọn mimu awọn nnkan wọnyi le fa ki eeyan ma le ṣe daadaa to ninu eto ẹkọ ẹni.

Dipo mimu ohun mimu afunilagbara wọnyi, mu omi nikan tabi ki o mu awọn ọti ẹlẹrin dodo to n ṣe ara loore bii ẹlẹrindodo ti wọn fi eso ṣe.

Dipo ki o maa kawe alẹ, ọrọ oorun sisun lọkunkundun.

Aisun daadaa le fa ki irẹwẹsi ọkan wa. Fi aaye silẹ lati sun daadaa.

Ṣamulo awọn nnkan wọnyi

Awọn ohun wọnyi wa pẹlu ẹri aridaju, o si wa fun ọna to dara lati gba fun igbaradi idanwo

Ṣugbọn sibẹ, o ni lati ronu awọn ohun to n ṣiṣẹ fun ọ daadaa. Ronu nipa awọn ohun to n mu inu ẹ dun ati awọn ohun to n mu ọ farabalẹ nigba ti iṣẹ ba pọ fun ọ.

Ṣe kikọ akọsile ni tabi gbigbọ awọn orin ti o fẹran julọ.?

Akojọpọ awọn iṣesi to n fun ara lokun ati ṣiṣe ohun ti eeyan nifẹẹ si jẹ ọna aṣeyọri, mejeeji yii lo si n ṣiṣẹ fun ṣiṣe daadaa ninu idanwo ati mimu adinku ba wahala.